Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 15

Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀

Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀

1 Tẹsalóníkà 1:5

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé o gbà pé òótọ́ ni ohun tí ò ń sọ àti pé ọ̀rọ̀ náà ṣe pàtàkì.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Múra sílẹ̀ dáadáa. Ṣàyẹ̀wò ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí dáadáa títí wàá fi rí ọ̀nà tí Bíbélì gbà fi hàn pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni. Fi ọ̀rọ̀ ṣókí tó sì rọrùn ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ. Pọkàn pọ̀ sórí àǹfààní tó máa ṣe fún àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.

  • Lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà dá ẹ lójú. Dípò ti wàá fi máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìtẹ̀jáde kan bó ṣe wà níbẹ̀ gẹ́lẹ́, ńṣe ni kó o sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ. Lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa fi hàn pé ohun tó ò ń sọ dá ẹ lójú.

  • Fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, kó o sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Gbóhùn sóke bó ṣe yẹ. Máa wo ojú àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, tí kò bá burú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní àgbègbè yín.