Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà 1:1-10

  • Ìkíni (1)

  • Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ àwọn ará Tẹsalóníkà (2-10)

1  Pọ́ọ̀lù, Sílífánù*+ àti Tímótì,+ sí ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Jésù Kristi Olúwa: Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà wà pẹ̀lú yín.  Ìgbà gbogbo là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí a bá ń rántí gbogbo yín nínú àdúrà wa,+  torí a ò lè ṣe ká má rántí iṣẹ́ tí ìgbàgbọ́ mú kí ẹ ṣe àti ìsapá onífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfaradà yín nítorí ìrètí tí ẹ ní+ nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa.  Ẹ̀yin ará tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, a mọ̀ pé òun ló yàn yín,  nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ nìkan ni ìhìn rere tí à ń wàásù fi dé ọ̀dọ̀ yín, ó tún wá nípasẹ̀ agbára, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ àti nípasẹ̀ ìdánilójú tó lágbára, bí ẹ ṣe mọ irú ẹni tí a dà láàárín yín àti nítorí yín.  Ẹ sì ń fara wé àwa+ àti Olúwa,+ bí ẹ ṣe tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú+ pẹ̀lú ayọ̀ ẹ̀mí mímọ́,  débi pé ẹ di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ní Makedóníà àti ní Ákáyà.  Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Jèhófà* ti dún jáde látọ̀dọ̀ yín ní Makedóníà àti Ákáyà nìkan ni, àmọ́ ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run ti tàn káàkiri níbi gbogbo,+ débi pé a kò nílò láti sọ ohunkóhun.  Nítorí àwọn fúnra wọn ń ròyìn nípa bí a ṣe kọ́kọ́ dé ọ̀dọ̀ yín àti bí ẹ ṣe fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀,+ tí ẹ sì yíjú sọ́dọ̀ Ọlọ́run kí ẹ lè jẹ́ ẹrú Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè, 10  kí ẹ sì lè dúró de Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run,+ ẹni tó gbé dìde kúrò nínú ikú, ìyẹn Jésù tó gbà wá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìrunú tó ń bọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.