Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá 2

A Sọ Párádísè Nù

A Sọ Párádísè Nù

Áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan mú kí ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, kọ ìṣàkóso Ọlọ́run sílẹ̀. Nítorí èyí, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wọnú ayé

TIPẸ́TIPẸ́ kí Ọlọ́run tó dá èèyàn, ló ti dá ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí, tá a mọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì. Nínú ọgbà Édẹ́nì, áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan, tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù, fi ọgbọ́n àrékérekè tan Éfà kó bàa lè jẹ lára èso igi tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.

Sátánì gba ẹnu ejò sọ̀rọ̀, ó sì mú kó dà bíi pé ńṣe ni Ọlọ́run ń fawọ́ ohun kan tó ṣàǹfààní sẹ́yìn fún obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀. Áńgẹ́lì náà sọ fún Éfà pé òun àti ọkọ rẹ̀ ò ní kú bí wọ́n bá jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà. Sátánì tipa bẹ́ẹ̀ fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó ń purọ́ fáwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Ẹlẹ̀tàn yìí mú kó dà bíi pé ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ló máa là wọ́n lójú kí òye wọn bàa lè pọ̀ sí i, tí wọ́n á sì wá dòmìnira. Àmọ́ irọ́ gbuu ló pa fún wọn, ìyẹn sì ni irọ́ àkọ́kọ́ tẹ́nikẹ́ni tíì pa rí lórí ilẹ̀ ayé. Ohun pàtàkì tó wà nínú ọ̀ràn tó délẹ̀ yìí ni pé ó kan ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ìyẹn ni pé ó mú kéèyàn máa ṣe kàyéfì pé bóyá ni Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé ṣó tiẹ̀ ń ṣàkóso lọ́nà tó máa ṣe àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí láǹfààní.

Éfà gba irọ́ tí Sátánì pa gbọ́. Ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ èso náà, nígbà tó yá, ó mú un ó sì jẹ ẹ́. Nígbà tí ọkọ ẹ̀ dé, ó fún un lára èso náà, òun náà sì jẹ ẹ́. Bí wọ́n ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀ nìyẹn o. Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn ò tó nǹkan lóòótọ́, àmọ́ ìwà ọ̀tẹ̀ gbáà ni. Níwọ̀n bí Ádámù àti Éfà ti mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n kọ ìṣàkóso Ẹlẹ́dàá, ẹni tó fi ohun gbogbo, tó fi mọ́ ìwàláàyè pípé, jíǹkí wọn.

Irú-ọmọ náà “yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15

Ọlọ́run kéde ìdájọ́ sórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn torí ohun tí wọ́n ṣe. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Irú-ọmọ, tàbí Olùdáǹdè, tó máa mú ìparun wá sórí Sátánì, tó lo ejò láti tan Éfà jẹ. Ọlọ́run ò mú ikú wá sórí Ádámù àti Éfà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kó bàa lè fi àánú hàn sáwọn ọmọ wọn tí wọn ò tíì bí. Àwọn ọmọ yẹn á sì lè máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ torí pé Ẹni tí Ọlọ́run máa rán á sọ àbájáde búburú ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì di asán. Bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ nípa Olùgbàlà tó ń bọ̀ wá yìí àti ẹni tí Olùgbàlà náà máa jẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kedere sí i bí àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣí i payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà kúrò nínú Párádísè. Ní báyìí, ó di pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ àṣelàágùn kí ilẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣọ̀gbìn lẹ́yìn òde ọgbà Édẹ́nì tó lè mú oúnjẹ jáde fún wọn. Lẹ́yìn náà, Éfà lóyún, ó sì bí Kéènì, àkọ́bí wọn. Àwọn tọkọtaya náà tún bí àwọn ọmọ míì, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lára wọn ni Ébẹ́lì àti Sẹ́ẹ̀tì, baba ńlá Nóà.

—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 3 sí 5; Ìṣípayá 12:9.