Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá 23

Ìhìn Rere Tàn Kálẹ̀

Ìhìn Rere Tàn Kálẹ̀

Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò lórí ilẹ̀ àti lórí òkun nítorí àtiwàásù ìhìn rere

LẸ́YÌN tí Pọ́ọ̀lù ti yí pa dà, ó ń fi ìháragàgà wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run, bó ṣe di pé òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í dojú kọ irú inúnibíni rírorò tó máa ń ṣe sáwọn èèyàn tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àpọ́sítélì tó ń fi tọkàn tara wàásù yìí rin ọ̀pọ̀ ìrìn àjò lọ sáwọn ibi tó jìnnà, kó bàa lè tan ìhìn rere kálẹ̀ nípa Ìjọba tó máa mú ète tí Ọlọ́run ní fún aráyé látìbẹ̀rẹ̀ ṣẹ.

Ní Lísírà, nígbà ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ó wo ọkùnrin kan tó ti yarọ látìgbà ìbí rẹ̀ sàn. Àwọn ogunlọ́gọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tó ń bá a rìnrìn àjò. Agbára káká làwọn ọkùnrin méjèèjì yìí fi ṣèdíwọ́ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe rúbọ sáwọn. Àmọ́, nígbà táwọn ọ̀tá Pọ́ọ̀lù bá ogunlọ́gọ̀ yìí sọ̀rọ̀, àwọn náà ló sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta títí tó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Pọ́ọ̀lù bọ́ lọ́wọ́ àtakò yìí, lẹ́yìn náà ló tún pa dà sínú ìlú yẹn tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun.

Àwọn Júù kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ń jiyàn pé àwọn Òfin Mósè kan wà táwọn onígbàgbọ́ tí kì í ṣe Júù gbọ́dọ̀ máa pa mọ́. Pọ́ọ̀lù mú ọ̀rọ̀ náà tọ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin lọ ní Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fara balẹ̀ gbé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sì ti darí wọn, wọ́n kọ̀wé sáwọn ìjọ, wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú láti ta kété sí ìbọ̀rìṣà, jíjẹ ẹ̀jẹ̀ àti ẹran tí a kò dúńbú àti àgbèrè. Irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn “nǹkan pípọndandan,” àmọ́ kò dìgbà téèyàn bá ń tẹ̀ lé Òfin Mósè kó tó pa wọ́n mọ́.—Ìṣe 15:28, 29.

Nínú ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù rìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ó lọ sí Bèróà, tó wà ní ìlú Gíríìsì òde òní. Àwọn Júù tó ń gbé níbẹ̀ fi ìháragàgà gba ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì ń yẹ Ìwé Mímọ́ wò láti rí àrídájú ohun tó fi kọ́ wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àtakò tún mú kí Pọ́ọ̀lù fi ibẹ̀ sílẹ̀, ó wá kọjá lọ sí Áténì. Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ tó wọ àwọn ọ̀mọ̀wé ará Áténì lọ́kàn ṣinṣin, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà téèyàn lè gbà lo ọgbọ́n, ìfòyemọ̀ àti ìjáfáfá.

Lẹ́yìn ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù ẹlẹ́ẹ̀kẹta gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀, àwọn Júù kan báyìí dá rúkèrúdò sílẹ̀, wọ́n sì fẹ́ láti pa á. Àwọn ọmọ ogun Róòmù bá wọn dá sí i, wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu Pọ́ọ̀lù. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú Róòmù, ọ̀rọ̀ náà dé iwájú Fẹ́líìsì, Gómìnà Róòmù, níwájú ẹni tó ti lọ jẹ́jọ́. Àwọn Júù ò lè fi ẹ̀rí kankan ti ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù lẹ́yìn. Kó tó di pé gómìnà Róòmù míì, ìyẹn Fẹ́sítọ́ọ̀sì, fa Pọ́ọ̀lù lé àwọn Júù lọ́wọ́, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” Fẹ́sítọ́ọ̀sì náà bá fèsì pé: “Ọ̀dọ̀ Késárì ni ìwọ yóò lọ.”—Ìṣe 25:11, 12.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi gbé Pọ́ọ̀lù lọ sí Ítálì láti lọ jẹ́jọ́. Ọkọ̀ wọ́n rì lójú ọ̀nà, torí náà wọ́n ní láti lo ìgbà òtútù ní erékùṣù Málítà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé ìlú Róòmù, ọdún méjì lo fi gbé nínú ilé tó háyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun ń ṣọ́ ọ, àpọ́sítélì tí iná ìtara rẹ̀ ń jó náà ń bá a nìṣó láti máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo àwọn tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

—A gbé e ka Ìṣe 11:22–28:31.