Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ǸJẸ́ A NÍLÒ ỌLỌ́RUN?

Kí Nìdí Tí Ìbéèrè Yìí Fi Jẹ Yọ?

Kí Nìdí Tí Ìbéèrè Yìí Fi Jẹ Yọ?

Láìpẹ́ yìí, àwùjọ àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà lọ sanwó kí wọ́n lè lo pátákó tí wọ́n fi ń polówó ọjà, ohun tí wọ́n kọ sára pátákó náà ni pé: “Ǹjẹ́ o gbà pé o kò nílò Ọlọ́run, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà bẹ́ẹ̀.” Ó dájú pé èrò wọn ni pé àwọn kò nílò Ọlọ́run.

Kódà, ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ ń ṣe kò fi hàn pé wọ́n gbà pé Ọlọ́run wà. Ọ̀gbẹ́ni Salvatore Fisichella tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìjọ Kátólíìkì sọ nípa àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pé: “Táwọn èèyàn bá wo irú ìgbé ayé tí à ń gbé, kò sẹ́ni tó máa gbà pé Kristẹni ni wá, torí pé ìgbé ayé wa kò yàtọ̀ sí tàwọn aláìgbàgbọ́.”

Ọwọ́ àwọn míì dí débi pé wọn ò tiẹ̀ ráyè fún Ọlọ́run rárá. Wọ́n ka Ọlọ́run sí ẹni tó jìnnà sí wọn, tí kò sì ṣeé sún mọ́ débi tó lè ṣe nǹkan tó ní láárí fáwọn. Torí náà, irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kì í ronú nípa Ọlọ́run, kìkì ìgbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro nìkan ni wọ́n máa ń wá Ọlọ́run, àfi bíi pé wọ́n sọ Ọlọ́run di ọmọ ọ̀dọ̀ tí wọ́n kàn lè pè rán níṣẹ́ tí wọ́n bá nílò nǹkan.

Àwọn kan ò tiẹ̀ rí ìdí tó fi yẹ káwọn máa tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá kọ́ nílé ìjọsìn, torí wọ́n gbà pé kò sí àǹfààní kankan tó lè ṣe fáwọn. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí fi hàn pé nílẹ̀ Jámánì, nínú èèyàn mẹ́wàá tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé mẹ́jọ nínú wọn ló gbà pé kò burú kí ọkùnrin àti obìnrin máa gbé pọ̀ láì ṣe ìgbéyàwó, bẹ́ẹ̀ sì rèé, èrò yẹn tako ohun tí Bíbélì sọ àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì wọn. (1 Kọ́ríńtì 6:18; Hébérù 13:4) Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ti rí i pé ìgbé ayé tí ọ̀pọ̀ ń gbé kò bá ohun tí ẹ̀sìn ń kọ́ wọn mu. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn láti onírúurú ìjọ ni wọ́n ń ṣàròyé pé àwọn ọmọ ìjọ wọn máa ń ṣe bíi pé wọn kò gba pé Ọlọ́run wà.

Irú àwọn àpẹẹrẹ yìí ló mú kí ìbéèrè náà jẹ yọ pé: Ǹjẹ́ àwa èèyàn nílò Ọlọ́run lóòótọ́? Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe tuntun, torí pé inú ìwé àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ náà ti kọ́kọ́ wáyé. Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn tó wáyé nínú Jẹ́nẹ́sísì tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì.