Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Ni Kéènì Ti Rí Ìyàwó Rẹ̀?

Ibo Ni Kéènì Ti Rí Ìyàwó Rẹ̀?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ibo Ni Kéènì Ti Rí Ìyàwó Rẹ̀?

▪ “Bí Ádámù àti Éfà bá ní ọmọkùnrin méjì, ìyẹn Kéènì àti Ébẹ́lì, ibo wá ni Kéènì ti rí ìyàwó rẹ̀?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn tó ń ṣiyè méjì nípa Bíbélì máa ń lo ìbéèrè yìí láti fẹ̀tàn ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tó kún rẹ́rẹ́ tó sì tẹ́ni lọ́rùn.

Ìwé Jẹ́nẹ́sísì orí 3 àti 4 jẹ́ ká mọ àwọn kókó yìí: (1) Éfà ni “ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.” (2) Àkókò tó wà láàárín ìgbà tí wọ́n bí Kéènì àti ìgbà tó pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. (3) Ìgbà tí Ọlọ́run lé Kéènì dà nù tó sì di “alárìnká àti ìsáǹsá,” tó wá ń ṣàníyàn pé ‘ẹnikẹ́ni tó bá rí òun’ lè pa òun. (4) Ọlọ́run fi àmì kan sára Kéènì láti dáàbò bò ó, èyí fi hàn pé àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ tàbí àwọn ẹbí míì lè fẹ́ láti pa á. (5) “Lẹ́yìn ìgbà náà,” Kéènì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀ ní “ilẹ̀ Ìsáǹsá.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:20; 4:3, 12, 14-17.

Láti inú ohun tá a ti sọ yìí, a lè sọ pé ìyàwó Kéènì jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ ọmọ Éfà tí wọ́n bí lọ́jọ́ tí a kò mọ̀. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 5:4 sọ pé, láàárín ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n [930] tí Ádámù fi wà láàyè, ó “bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.” Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kò sọ ní pàtó pé Éfà ló bí ìyàwó Kéènì. Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀yìn tí Ọlọ́run lé Kéènì kúrò la sọ̀rọ̀ ìyàwó rẹ̀ fi hàn pé àkókò tó kọjá náà pọ̀ tó tí obìnrin náà fi lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin ọmọ Ádámù àti Éfà. Ìyẹn ló mú kí Bíbélì, The Amplified Old Testament sọ pé ìyàwó Kéènì jẹ́ “ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ Ádámù.”

Alálàyé Bíbélì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adam Clarke sọ pé ẹ̀rù tó ń ba Kéènì ló mú kí Ọlọ́run fi àmì sára rẹ̀, torí pé nígbà yẹn àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ti wà ní “àwọn abúlé mélòó kan.”

Àwọn èèyàn kan lónìí sọ pé, kò ṣeé ṣe kí Kéènì fẹ́ àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí obìnrin kan tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Ádámù. Èyí sábà máa ń rí bẹ́ẹ̀ nítorí ojú burúkú táwọn èèyàn fi ń wò ó tàbí nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí yóò ya alárùn. Síbẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni F. LaGard Smith ṣàlàyé nínú ìwé The Narrated Bible in Chronological Order pé: “Ó ṣeé ṣe pé kí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò àkọ́kọ́ yìí fẹ́ ara wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé irú ojú táwọn ìran tó ń bọ̀ máa fi wò ó kò ní dára.” Bákan náà, ohun tó gbàfiyèsí ni pé ìgbà tí Mósè gba òfin lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Ọlọ́run tó sọ pé ìbálòpọ̀ kò gbọ́dọ̀ wáyé láàárín irú ẹbí tó sún mọ́ra wọn bẹ́ẹ̀.—Léfítíkù 18:9, 17, 24.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún la ti fi jìnnà sí ìgbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ jẹ́ ẹni pípé. Ipa tí apilẹ̀ àbùdá àti ohun tá a jogún ní lórí wa lè máà ní ipa kankan lórí wọn. Síwájú sí i, àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí bí irú èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn nípa àbùdá, ìyẹn Journal of Genetic Counseling, fi hàn pé ìgbéyàwó láàárín ọmọ ẹ̀gbọ́n àti ọmọ àbúrò kò fi bẹ́ẹ̀ ní ewu bíbí ọmọ alárùn tó bí àwọn èèyàn níbi gbogbo ṣe rò. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ìṣòro nígbà ayé Ádámù tàbí ṣáájú ìgbà ayé Nóà. Nítorí náà, a lè sọ pé ọ̀kan lára àwọn obìnrin látinú ẹbí Kéènì ni ìyàwó rẹ̀.