Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Iná Ọ̀run Àpáàdì Ni Jésù Ní Lọ́kàn?

Ṣé Iná Ọ̀run Àpáàdì Ni Jésù Ní Lọ́kàn?

Ṣé Iná Ọ̀run Àpáàdì Ni Jésù Ní Lọ́kàn?

ÀWỌN kan tó gba ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì gbọ́ sábà máa ń fi ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Máàkù 9:48 (tàbí ẹsẹ 44 àti 46) ti ẹ̀kọ́ yìí lẹ́yìn. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Jésù sọ̀rọ̀ nípa kòkòrò mùkúlú (tàbí ìdin) tí kì í kú àti iná tí wọn kì í pa. Tẹ́nì kan bá bi ọ́ ní ohun kan nípa àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, kí lo máa sọ?

Irú ìtumọ̀ Bíbélì tí ẹni náà bá lò ló máa pinnu bóyá ó máa ka ẹsẹ 44 àti 46, tàbí ẹsẹ 48, torí pé ohun kan náà ló wà nínú àwọn ẹsẹ yẹn nínú àwọn Bíbélì kan. a Àmọ́ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun rèé: “Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, sọ ọ́ nù; ó sàn fún ọ láti wọ ìjọba Ọlọ́run ní olójú kan ju kí a gbé ọ pẹ̀lú ojú méjì sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà, níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí a kì í sì í pa iná náà.”—Máàkù 9:47, 48.

Síbẹ̀síbẹ̀, ohun táwọn kan máa ń sọ ni pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé, tí ẹni burúkú bá kú ọkàn rẹ̀ yóò máa joró títí láé. Bí àpẹẹrẹ, àlàyé kan nínú Bíbélì èdè Sípáníìṣì tí wọ́n pè ní Sagrada Biblia tí Yunifásítì tó wà ní Navarre nílẹ̀ Sípéènì ṣe, sọ pé: “Olúwa wa lo [ọ̀rọ̀ yìí] láti fi tọ́ka sí ìdálóró nínú ọ̀run àpáàdì. Wọ́n sábà máa ń sọ pé ‘ìdin wọn tí kì í kú’ túmọ̀ sí ìbànújẹ́ ayérayé táwọn tó wà ní ọ̀run àpáàdì máa ní; àti pé ‘iná tí a kì í pa’ náà túmọ̀ sí ìdálóró wọn.”

Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ Jésù wé ohun tó wà nínú ẹsẹ tó gbẹ̀yìn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà. b Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú orí kẹrìndínláàádọ́rin ìwé Aísáyà ni Jésù ń dọ́gbọ́n tọ́ka sí? Ẹ̀rí fi hàn pé, nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, ńṣe ni wòlíì Aísáyà ń sọ̀rọ̀ nípa jíjáde kúrò ní “Jerúsálẹ́mù lọ sí Àfonífojì (Gẹ̀hẹ́nà) Hínómù tó yí wọn ká, níbi tí wọ́n ti máa ń fi èèyàn rúbọ nígbà kan, (Jer 7:31) àmọ́ tó wá padà dibi táwọn ará ìlú ń dalẹ̀ sí.” (The Jerome Biblical Commentary) Ó ṣe kedere pé, ọ̀rọ̀ nípa òkú àwọn ènìyàn ni àpèjúwe tó wà nínú ìwé Aísáyà 66:24 dá lé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ bí wọn yóò ṣe máa dá àwọn èèyàn lóró nínú iná. Ohun tí Aísáyà sọ pé kì í kú ni ìdin, kì í ṣe èèyàn tó ṣì wà láàyè tàbí ọkàn kan tí kì í kú. Nígbà náà, kí ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ túmọ̀ sí?

Wo ohun tí ìwé ẹ̀sìn Kátólíìkì kan sọ nípa Máàkù 9:48, ó ní: “Inú ìwé Aísáyà (66,24) ni wọ́n ti mú gbólóhùn náà. Nínú ẹsẹ yẹn, wòlíì náà sọ ọ̀nà méjì tí wọ́n ń gbà palẹ̀ òkú mọ́ kúrò nílẹ̀, ìyẹn ni kí òkú jẹrà tàbí kí wọ́n dáná sun ún . . . Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà ìdin àti iná tẹ̀ lé ara wọn nínú àkọsílẹ̀ yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìparun ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. . . . Àwọn nǹkan méjèèjì tó máa ń jẹ nǹkan run yìí, ni wọn sọ pé kì í pa run, (‘wọn kì í kú, wọn kì í sì í pa iná rẹ̀’): ìyẹn ni pé, kò sí bí ohun tó bá wà níbẹ̀ ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ wọn. Nínú àpèjúwe yìí, ohun tí kì í pa run ni ìdin àti iná, kì í ṣe èèyàn, torí pé ńṣe ni nǹkan méjèèjì yìí máa ń jẹ ohun tó bá kó sí wọn lọ́wọ́ run pátápátá. Nítorí náà, èyí kì í ṣe àpèjúwe ìdálóró ayérayé, àpèjúwe ìparun ráúráú ni, nítorí ó túmọ̀ sí pé kò ní sí àjíǹde fún ẹni tó bá pa run lọ́nà yìí, ńṣe ni wọ́n kú ikú ayérayé. Torí náà, ohun tí [iná] ń ṣàpẹẹrẹ níhìn-ín ni ìparun ráúráú.”—El evangelio de Marcos. Análisis lingüístico y comentario exegético, Ìdìpọ̀ Kejì.

Ó yẹ kí ẹni tó bá gbà pé Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti onídàájọ́ òdodo lè rí i pé ó mọ́gbọ́n dání láti lóye ọ̀rọ̀ Jésù lọ́nà tí ìwé yìí gbà ṣàlàyé rẹ̀. Jésù kò sọ pé Ọlọ́run máa dá àwọn ẹni burúkú lóró títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jésù ń sọ ni pé ọ̀rọ̀ wọn lè yọrí sí ìparun títí láé tí wọn kò sì ní ní àjíǹde.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kò sí ẹsẹ 44 àti 46 nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì tó péye jù lọ. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fi àwọn ẹsẹ méjì yìí kún un nígbà tó yá. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Archibald T. Robertson sọ pé: “Kò sí ẹsẹ méjèèjì yìí nínú ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì tó lọ́jọ́ lórí jù, tó sì péye jù lọ. Inú ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì ti Ìwọ̀-Oòrùn àti ti Síríà (Bìsáńṣíọ̀mù) ló ti wá. Ohun tó wà ní ẹsẹ 48 ni wọ́n kàn tún sọ ní ẹsẹ 44 àti 46. Ìdí nìyí tá a fi [fo] ẹsẹ 44 àti 46 torí wọn kì í ṣe ojúlówó.”

b “Wọn yóò sì jáde lọ ní tòótọ́, wọn yóò sì wo òkú àwọn ènìyàn tí ń rélànà mi kọjá; nítorí pé kòkòrò mùkúlú tí ó wà lára wọn kì yóò kú, iná wọn ni a kì yóò sì fẹ́ pa, wọn yóò sì di ohun tí ń kóni nírìíra fún gbogbo ẹran ara.”—Aísá. 66:24.