Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lórí Òkun Gálílì

Lórí Òkun Gálílì

Lórí Òkun Gálílì

MÁÀKÙ orí kẹrin ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ìkọkànlélógójì sọ pé Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi kan nígbà tí wọ́n fẹ́ kọjá Òkun Gálílì. Bíbélì sọ pé: “Wàyí o, ìjì ẹlẹ́fùúùfù ńlá lílenípá kan bẹ́ sílẹ̀, ìgbì sì ń rọ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi ṣáá, tó bẹ́ẹ̀ tí omi fi fẹ́rẹ̀ẹ́ bo ọkọ̀ ojú omi náà mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n [Jésù] wà ní ìdí ọkọ̀, ó ń sùn lórí ìrọ̀rí kan.”

Ibí yìí nìkan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìrọ̀rí” wà nínú Bíbélì. Èyí ló fà á táwọn ọ̀mọ̀wé ò fi mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Ọ̀pọ̀ Bíbélì ló túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “ìrọ̀rí” tàbí “tìmùtìmù.” Àmọ́, irú ìrọ̀rí wo ni Jésù lò? Nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, Máàkù tọ́ka sí ìrọ̀rí náà lọ́nà tó fi hàn pé ó wà lára ohun tí wọ́n ń lò nínú ọkọ̀. Àmọ́, ọkọ̀ kan tí wọ́n ṣàwárí nínú Òkun Gálílì lọ́dún 1986 jẹ́ ká mọ ohun tó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Máàkù lò yìí túmọ̀ sí.

Nígbà táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ṣe àyẹ̀wò, wọ́n rí i pé ìgbòkun àti àjẹ̀ ni wọ́n fi máa ń wa ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n rí náà, èyí tí gígùn rẹ̀ jẹ́ mítà mẹ́jọ. Ẹja ni wọ́n ń fi ọkọ̀ náà pa, ibì kan sì wà lẹ́yìn ọkọ̀ tí wọ́n lè kó àwọ̀n ńlá tó wúwo gan-an lé. Wọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan bí ọdún 100 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 70 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n lo ọkọ̀ náà, ó sì jọ irú ọkọ̀ tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò. Shelley Wachsmann jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ṣàwárí ọkọ̀ náà, òun ló sì kọ ìwé The Sea of Galilee Boat—An Extraordinary 2000 Year Old Discovery (Ọkọ̀ Òkun Gálílì—Ohun Àrà Ọ̀tọ̀ Tí A Rí Lẹ́yìn Ẹgbàá Ọdún). Ó ní ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpò kan tí wọ́n kó yanrìn sí tí wọ́n ń gbé sínú ọkọ̀ kó má bàa máa fì síhìn-ín sọ́hùn-ún ni Jésù fi ṣe “ìrọ̀rí.” Ọkùnrin kan tó ń gbé nílùú Jaffa, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ẹja pípa tó sì mọ bí wọ́n ṣe ń fi àwọ̀n ńlá pẹja sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, a sábà máa ń gbé àpò kan tàbí méjì tá a kó yanrìn sí sínú àwọn ọkọ̀ tí mò ń bá ṣiṣẹ́ lórí Òkun Mẹditaréníà. . . . A máa ń gbé àwọn àpò náà sínú ọkọ̀ kí ọkọ̀ má bàa máa fì síhìn-ín sọ́hùn-ún. Àmọ́, tá ò bá lò wọ́n, ẹ̀yìn ọkọ̀ la máa ń gbé wọn sí. Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ó ti rẹ ẹnì kan, á rọra lọ sẹ́yìn ọkọ̀, á sì fi àpò náà ṣe ìrọ̀rí tó bá fẹ́ sùn.”

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ohun tí Máàkù ní lọ́kàn ni pé orí àpò tí wọ́n kó yanrìn sí kí ọkọ̀ má bàa máa fì síhìn-ín sọ́hùn-ún ni Jésù sùn lé lẹ́yìn ọkọ̀, ibẹ̀ ló sì láàbò jù lọ nínú ọkọ̀ bí ìjì bá ń jà. Bá ò tiẹ̀ mọ irú ìrọ̀rí tó jẹ́ gan-an, ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ló ṣe pàtàkì jù. Ìjì líle tó ń jà bẹ̀rẹ̀ sí mú kí òkun ru gùdù, àmọ́ Jésù lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi mú kí òkun náà pa rọ́rọ́. Kódà àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé: “Ta nìyí ní ti gidi, nítorí ẹ̀fúùfù àti òkun pàápàá ń ṣègbọràn sí i?”