Àkọsílẹ̀ Máàkù 4:1-41

 • ÀWỌN ÀPÉJÚWE NÍPA ÌJỌBA NÁÀ (1-34)

  • Afúnrúgbìn (1-9)

  • Ìdí tí Jésù fi lo àwọn àpèjúwe (10-12)

  • Ó ṣàlàyé ìtumọ̀ àpèjúwe afúnrúgbìn (13-20)

  • A kì í gbé fìtílà sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ (21-23)

  • Òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n (24, 25)

  • Afúnrúgbìn tó sùn (26-29)

  • Hóró músítádì (30-32)

  • Ó ń lo àpèjúwe (33, 34)

 • Jésù mú kí ìjì dáwọ́ dúró (35-41)

4  Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni létí òkun, èrò rẹpẹtẹ sì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Torí náà, ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì jókòó sínú rẹ̀, ó sún kúrò ní etíkun, àmọ́ gbogbo àwọn èrò náà wà ní èbúté, létí òkun.+  Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi àpèjúwe kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan,+ bó ṣe ń kọ́ wọn, ó sọ fún wọn pé:+  “Ẹ fetí sílẹ̀. Ẹ wò ó! Afúnrúgbìn jáde lọ fún irúgbìn.+  Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, àwọn ẹyẹ wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.  Àwọn míì já bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì hù lójú ẹsẹ̀ torí pé iyẹ̀pẹ̀ náà ò jìn.+  Àmọ́ nígbà tí oòrùn ràn, ó jó wọn gbẹ, wọ́n sì rọ torí pé wọn ò ní gbòǹgbò.  Àwọn irúgbìn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà yọ, wọ́n fún wọn pa, wọn ò sì so èso kankan.+  Àmọ́ àwọn míì bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, wọ́n dàgbà, wọ́n pọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, wọ́n ń so ní ìlọ́po ọgbọ̀n (30), ọgọ́ta (60) àti ọgọ́rùn-ún (100).”+  Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+ 10  Nígbà tó wà ní òun nìkan, àwọn tó yí i ká pẹ̀lú àwọn Méjìlá náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi í nípa àwọn àpèjúwe náà.+ 11  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la jẹ́ kó mọ àṣírí mímọ́+ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ àpèjúwe ni gbogbo nǹkan jẹ́ fún àwọn tó wà ní òde,+ 12  kó lè jẹ́ pé, bí wọ́n tiẹ̀ ń wò, wọ́n lè máa wò, síbẹ̀ kí wọ́n má ṣe rí àti pé bí wọ́n tiẹ̀ ń gbọ́, wọ́n lè gbọ́, síbẹ̀ kó má sì yé wọn; wọn ò sì ní yí pa dà láé, kí wọ́n sì rí ìdáríjì.”+ 13  Bákan náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ò mọ àpèjúwe yìí, báwo wá lẹ ṣe máa lóye gbogbo àpèjúwe yòókù? 14  “Afúnrúgbìn fún irúgbìn ọ̀rọ̀ náà.+ 15  Torí náà, àwọn yìí ni àwọn tó bọ́ sí etí ọ̀nà, níbi tí a gbin ọ̀rọ̀ náà sí; àmọ́ gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ, Sátánì wá,+ ó sì mú ọ̀rọ̀ tí a gbìn sínú wọn kúrò.+ 16  Bákan náà, àwọn yìí ló bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta; gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á.+ 17  Síbẹ̀, wọn ò ta gbòǹgbò nínú ara wọn, àmọ́ wọ́n ń bá a lọ fúngbà díẹ̀; gbàrà tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n kọsẹ̀. 18  Àwọn míì wà tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún. Àwọn yìí ló ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,+ 19  àmọ́ àníyàn+ ètò àwọn nǹkan yìí,* agbára ìtannijẹ ọrọ̀+ àti ìfẹ́ + gbogbo nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn, wọ́n fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso. 20  Níkẹyìn, àwọn tó bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa ni àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n fi ọkàn rere gbà á, tí wọ́n sì ń so èso ní ìlọ́po ọgbọ̀n (30), ọgọ́ta (60) àti ọgọ́rùn-ún (100).”+ 21  Ó tún sọ fún wọn pé: “A kì í gbé fìtílà wá, ká wá gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀* tàbí sábẹ́ ibùsùn, àbí? Ṣebí tí wọ́n bá gbé e wá, orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n máa ń gbé e sí?+ 22  Torí kò sí nǹkan tí a fi pa mọ́ tí a kò ní tú síta; kò sí ohun tí a rọra tọ́jú tí kò ní hàn sí gbangba.+ 23  Kí ẹnikẹ́ni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+ 24  Ó tún sọ fún wọn pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ̀ ń gbọ́.+ Òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n la máa fi díwọ̀n fún yín, àní, a máa fi kún un fún yín. 25  Torí ẹnikẹ́ni tó bá ní, a máa fi kún ohun tó ní,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá ní, a máa gba ohun tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 26  Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Lọ́nà yìí, Ìjọba Ọlọ́run dà bí ìgbà tí ẹnì kan fún irúgbìn sórí ilẹ̀. 27  Ó sùn ní alẹ́, ó sì dìde ní àárọ̀, irúgbìn náà rú jáde, ó sì dàgbà, àmọ́ kò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀. 28  Ilẹ̀ náà mú èso jáde fúnra rẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun ọ̀gbìn náà kọ́kọ́ yọ, lẹ́yìn náà erín ọkà,* nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èso jáde lódindi nínú erín ọkà. 29  Àmọ́ gbàrà tí èso náà tó kórè, ó ti dòjé bọ̀ ọ́, torí àkókò ìkórè ti dé.” 30  Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kí la lè fi Ìjọba Ọlọ́run wé, àbí àpèjúwe wo la lè fi ṣàlàyé rẹ̀? 31  Ó dà bíi hóró músítádì, tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n gbìn ín sínú ilẹ̀, òun ló rí tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn tó wà láyé.+ 32  Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbìn ín, ó dàgbà, ó sì tóbi ju gbogbo ọ̀gbìn oko yòókù lọ, ó yọ àwọn ẹ̀ka ńláńlá, débi pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń gbé lábẹ́ òjìji rẹ̀.” 33  Ó fi ọ̀pọ̀ irú àwọn àpèjúwe+ yẹn bá wọn sọ̀rọ̀, débi tí wọ́n lè fetí sílẹ̀ dé. 34  Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìlo àpèjúwe, àmọ́ ó máa ń ṣàlàyé gbogbo nǹkan fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn nìkan.+ 35  Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká sọdá sí èbúté kejì.”+ 36  Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ní kí àwọn èrò náà máa lọ, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi náà gbé e, bó ṣe wà níbẹ̀, àwọn ọkọ̀ ojú omi míì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 37  Ìjì líle kan tó ń fẹ́ atẹ́gùn gidigidi wá bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ìgbì òkun sì ń rọ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi náà ṣáá, débi pé omi fẹ́rẹ̀ẹ́ kún inú ọkọ̀ náà.+ 38  Àmọ́ ó wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó ń sùn lórí ìrọ̀rí.* Wọ́n wá jí i, wọ́n sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, ṣé bí a ṣe fẹ́ ṣègbé yìí ò ká ọ lára ni?” 39  Ló bá dìde, ó bá ìjì náà wí, ó sì sọ fún òkun pé: “Ó tó! Dákẹ́ jẹ́ẹ́!”+ Ìjì náà bá rọlẹ̀, gbogbo ẹ̀ sì pa rọ́rọ́. 40  Ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín* tó báyìí? Ṣé ẹ ò tíì ní ìgbàgbọ́ rárá ni?” 41  Àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì sọ fúnra wọn pé: “Ta lẹni yìí gan-an? Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n.”
Ìyẹn, orí ọkà.
Tàbí “tìmùtìmù.”
Tàbí “tí ẹ̀ ń ṣojo.”