Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Nínú Ìgbéyàwó Rẹ

Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Nínú Ìgbéyàwó Rẹ

Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Nínú Ìgbéyàwó Rẹ

ÌGBÉYÀWÓ—ọ̀rọ̀ àgbọ́dunnú lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ létí àwọn kan. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ gbáà ló jẹ́ létí àwọn ẹlòmíràn. Obìnrin kan sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pé: “Ńṣe ló máa ń ṣe mí bí ẹni pé èmi àti ọkọ mi ti kọ ara wa sílẹ̀. Gbogbo ìgbà ló máa ń dà bí ẹni pé ó ti pa mí tì, tí mi ò sì ní alábàárò.”

Kí ló fà á tí ẹni méjì tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á máa nífẹ̀ẹ́ ara àwọn, pé àwọn á sì tún máa ṣìkẹ́ ara wọn wá di ẹni tí kò fẹ́ràn ara wọn mọ́? Ìdí kan ni pé àwọn kan kò mọ ohun tí ìgbéyàwó túmọ̀ sí. Ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ akọ̀ròyìn lórí ọ̀ràn ìṣègùn sọ pé: “A kàn ń ṣe ìgbéyàwó ni, a ò gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kankan.”

Yunifásítì Rutgers nílùú New Jersey, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe onígbọ̀wọ́ ìwádìí kan tí Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ètò Ìgbéyàwó ṣe. Ìwádìí náà fi hàn pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ ohun tí ìgbéyàwó túmọ̀ sí. Olùdarí ìwádìí náà sọ pé “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lákòókò ìwádìí náà ló jẹ́ àwọn tí ìgbéyàwó àwọn òbí wọn kò láyọ̀ tàbí àwọn tí òbí wọn ti kọ ara wọn sílẹ̀. Wọ́n mọ ohun tí ìgbéyàwó tí kò láyọ̀ túmọ̀ sí àmọ́ wọn kò mọ bí ìgbéyàwó tó lárinrin ṣe máa ń rí. Kìkì àlàyé táwọn kan lè ṣe nípa ìgbéyàwó alárinrin ni pé ‘ó jẹ́ òdìkejì ìgbéyàwó àwọn òbí mi.’”

Ǹjẹ́ ìṣòro tó ń yọjú láàárín àwọn lọ́kọláya yọ àwọn Kristẹni sílẹ̀ ni? Rárá o. Kódà, àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní nílò ìmọ̀ràn tó ṣe sàn-án pé kí wọ́n “dẹ́kun wíwá ìtúsílẹ̀” nínú ìgbéyàwó wọn. (1 Kọ́ríńtì 7:27) Kò sí ni kí ìgbéyàwó láàárín ẹ̀dá aláìpé méjì máà ní ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ ńbẹ. Ọkọ àti aya lè mú kí ìgbéyàwó wọn sunwọ̀n sí i nípa fífi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò.

Lóòótọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé kan tó wà fún kìkì ọ̀ràn ìgbéyàwó. Àmọ́ nígbà tó jẹ́ pé Ẹni tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀ gan-an ló mí sí kíkọ Bíbélì, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àwọn ìlànà inú rẹ̀ á ranni lọ́wọ́. Jèhófà Ọlọ́run gba ẹnu wòlíì Aísáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:17, 18.

Ṣé ìfẹ́ tó ń jo lala láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ nígbà kan rí ti bẹ̀rẹ̀ sí dín kù? Ǹjẹ́ o máa ń rò pé o ti há sínú ìgbéyàwó tí kò tí sí ìfẹ́? Obìnrin kan tó ti wà nílé ọkọ fún odindi ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n sọ pé: “Bí àárín ọkọ àti ìyàwó kò bá gún, ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń kó báni kò ṣe é fẹnu sọ. Ìṣòro ni ṣáá lójoojúmọ́, ìṣòro náà kì í sì í tán.” Àmọ́ dípò tí wàá fi gba kámú pé kò sóhun tó o lè ṣe sí ìgbéyàwó rẹ tí kò rí bó o ṣe fẹ́ kó rí, o ò ṣe kúkú wá ọgbọ́n dá sí i? Àpilẹ̀kọ tó kàn á jẹ́ káwọn tọkọtaya rí bí àwọn ìlànà inú Bíbélì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìgbéyàwó wọn ní ọ̀nà kan pàtó. Ọ̀nà náà ni àdéhùn tí wọ́n jọ ṣe.