Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìgbà wo ni a fòróró yan “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 9:24?

Dáníẹ́lì 9:24-27 jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó dá lé ìfarahàn “Mèsáyà Aṣáájú”—ìyẹn Kristi. Nítorí náà àsọtẹ́lẹ̀ nípa fífòróró yan “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́,” kò tọ́ka sí fífòróró yan Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbólóhùn náà “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́” ń tọ́ka sí ibùjọsìn ti Ọlọ́run ní ọ̀run—ìyẹn Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní ọ̀run—nínú tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà nípa tẹ̀mí. aHébérù 8:1-5; 9:2-10, 23.

Ìgbà wo ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́? Tóò, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wá láti ṣe batisí ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Láti àkókò yẹn lọ ni Jésù ti ń mú ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 40:6-8 ṣẹ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé lẹ́yìn náà pé Jésù ti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ṣùgbọ́n ìwọ ti pèsè ara kan fún mi.” (Hébérù 10:5) Jésù mọ̀ pé Ọlọ́run “kò fẹ́” kí fífi ẹran rúbọ máa bá a nìṣó nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Dípò ìyẹn, Jèhófà ti pèsè ara ènìyàn pípé fún Jésù láti fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ. Jésù fi hàn pé inú òun dùn sí èyí, ó sì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wò ó! Mo dé (nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.” (Hébérù 10:7) Kí sì ni Jèhófà fi dá a lóhùn? Ìhìn Rere Mátíù sọ pé: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’”—Mátíù 3:16, 17.

Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gba ara Jésù tó fi rúbọ túmọ̀ sí pé pẹpẹ kan tó tóbi ju pẹpẹ tó ṣeé fojú rí nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ti wà. Èyí ni pẹpẹ “ìfẹ́” Ọlọ́run, tàbí ìṣètò fún títẹ́wọ́ gba ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ. (Hébérù 10:10) Fífi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti gbé ìṣètò tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí látòkèdélẹ̀ kalẹ̀ nísinsìnyí. b Nítorí náà, nígbà ìbatisí Jésù, ibi tí Ọlọ́run wà ní òkè ọ̀run ni a fi òróró yàn tàbí ni a yà sọ́tọ̀, bí “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́” nínú ìṣètò tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìjíròrò lórí onírúurú apá tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí ní, wo ojú ìwé 14 sí 19 nínú Ilé Ìṣọ́ ti July 1, 1996.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

A fòróró yan “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́” náà nígbà tí Jésù ṣe batisí