Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 1 2018 | Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀

IBO LA TI LÈ RÍ ÌMỌ̀RÀN GIDI NÍPA BÁ A ṢE LÈ MÁA GBÉ ÌGBÉ AYÉ ALÁYỌ̀?

Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláìní-àléébù ní ọ̀nà wọn.”​—Sáàmù 119:1.

Àwọn àpilẹ̀kọ méje yìí sọ àwọn ìlànà tó ṣeé gbára lé nípa bí èèyàn ṣe lè máa gbé ìgbé ayé aláyọ̀.

 

Bó O Ṣe Lè Máa Gbé Ìgbé Ayé Aláyọ̀

Sé o máa ń láyọ̀? Kí ló máa ń mú kéèyàn láyọ̀

Ìtẹ́lọ́rùn àti Ìwà Ọ̀làwọ́

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé bí àwọ́n bá ṣe lówó tó ni àwọn ṣe máa láyọ̀ tó. Àmọ́ ṣé owó àti ohun ìní rẹpẹtẹ ló ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀? Kí ni ẹ̀rí fi hàn?

Ara Líle àti Ìfaradà

Ṣé téèyàn bá ní àìlera, ó túmọ̀ sí pé èèyàn lè láyọ̀ mọ́ láé?

Ìfẹ́

Èèyàn máa láyọ̀ tí wọ́n bá ń fi ìfẹ́ hàn síni téèyàn sì ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmí ì.

Ìdáríjì

Tí ìgbésí ayé ẹni bá kún fún ìbínú ní gbogbo ọjọ́, téèyàn sì ń gbé ọ̀rọ̀ sọ́kàn, èèyàn ò ní láyọ̀, ìlera rẹ̀ ò sì ní dára.

Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀

Tá a bá fẹ́ láyọ̀, ó ṣe pàtàkì ká mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé.

Ìrètí

Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í láyọ̀ tí wọn ò bá mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wọn àti àwọn èèyàn wọn lọ́jọ́ ọ̀la.

Kẹ́kọ̀ọ́ Sí I

Oríṣirísi nǹkan ló lè mú kéèyàn láyọ̀ tàbí kéèyàn má láyọ̀. Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ohun tó o lè ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro tó ò ń kojú nígbèésí ayé rẹ.