Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Ìtẹ́lọ́rùn àti Ìwà Ọ̀làwọ́

Ìtẹ́lọ́rùn àti Ìwà Ọ̀làwọ́

ṢÓ O MÁA Ń GBỌ́ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń SỌ PÉ OWÓ ÀTI OHUN ÌNÍ LÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀? Èrò yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó, torí kí wọ́n lè di olówó. Àmọ́, ṣé owó àtàwọn nǹkan ìní ló ń fúnni láyọ̀ tó tọ́jọ́? Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn kan sọ.

Ìwé Journal of Happiness Studies sọ pé ó dáa kéèyàn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun kòṣeémáàní, torí owó rẹpẹtẹ kọ́ ló ń fún èèyàn ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Àmọ́, kì í ṣe owó fúnra ẹ̀ nìṣòro. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Monitor on Psychology sọ pé: “Béèyàn bá ń forí ṣe fọrùn ṣe torí pé ó fẹ́ di ọlọ́rọ̀, onítọ̀hún ò ní láyọ̀.” Ọ̀rọ̀ yẹn bá ohun tí Bíbélì ti sọ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2000] ọdún sẹ́yìn mu pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, . . . àwọn kan . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:​9, 10) Àwọn ìrora wo ni irú àwọn eni bẹ́ẹ̀ máa ń ní?

TORÍ PÉ WỌ́N FẸ́ DÁÀBÒ BO OHUN ÌNÍ WỌN, WỌ́N MÁA Ń DÀÀMÚ, WỌN KÌ Í SÌ Í RÍ OORUN SÙN. “Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.”​—Oníwàásù 5:12.

ÌRẸ̀WẸ̀SÌ MÁA Ń BÁ WỌN TORÍ PÉ WỌN KÌ Í LÁYỌ̀ BÍ WỌ́N ṢE RÒ. Lára ohun tó sì máa ń fà á ni pé owó kì í tó olówó. “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.” (Oníwàásù 5:10) Bákan náà, torí pé ẹnì kan fẹ́ lówó, ó lè pa tẹbí-tọ̀rẹ́ tì, ó sì lè má fọwọ́ pàtàkì mú àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, àwọn nǹkan yìí gan-an ló sì máa ń fúnni láyọ̀.

ÌBÀNÚJẸ́ MÁA Ń BÁ WỌN NÍGBÀ TÍ OKÒWÒ BÁ DẸNU KỌLẸ̀. “Má ṣe làálàá láti jèrè ọrọ̀. Ṣíwọ́ kúrò nínú òye ara rẹ. Ìwọ ha ti jẹ́ kí ojú rẹ wò ó fìrí bí, nígbà tí kò jámọ́ nǹkan kan? Nítorí láìsí àní-àní, ó máa ń ṣe ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀ bí ti idì, a sì fò lọ.”​—Òwe 23:​4, 5.

ÀWỌN ÌWÀ TÓ MÁA Ń JẸ́ KÍ ÈÈYÀN LÁYỌ̀

ÌTẸ́LỌ́RÙN. “Nítorí a kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:​7, 8) Àwọn tó ní ìtẹ́lọ́rùn kì í ṣàríwísí tàbí kí wọ́n máa jowú. Bákan náà, wọn kì í ṣàníyàn tàbí kí wọ́n máa dààmú láìnídìí, torí pé wọn kì í wá nǹkan ìní tó ju agbára wọn lọ.

ÌWÀ Ọ̀LÀWỌ́. “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Àwọn tó lawọ́ máa ń láyọ̀ torí pé wọ́n ń mú inú àwọn míì dùn, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ pé àkókò díẹ̀ ni wọ́n lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń jèrè àwọn nǹkan tí kò ṣeé fowó rà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ràn wọn, wọ́n máa ń níyì lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi tó máa ń lawọ́ sáwọn náà.​—Lúùkù 6:38.

GBÀ PÉ ÈÈYÀN BONI LÁRA JU AṢỌ LỌ. “Oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.” (Òwe 15:17) Kókó tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ni pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan tara lọ. Bákan náà, ìfẹ́ ṣe pàtàkì téèyàn bá máa láyọ̀. A ṣì máa rí kókó yìí níwájú.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sabina, ní apá Gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà kọ́ nípa àwọn ìlànà Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́. Nígbà tí ọkọ rẹ̀ já a jù sílẹ̀, ẹrù ẹni méjì wá di tòun nìkan, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ àti tàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì. Iṣẹ́ méjì ló ń ṣe pọ̀, èyí sì gba pé kó máa jí ní aago mẹ́rin àárọ̀. Láìka bí ọwọ́ rẹ̀ ṣe máa ń dí tó, Sabina pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe pé owó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wọlé fún un gan-an, àmọ́ ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dára! Bí àpẹẹrẹ, ó túbọ̀ láyọ̀ torí pé ó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Mátíù 5:3) Ó rí àwọn ọ̀rẹ́ gidi láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run. Ohun míì tó tún fún un láyọ̀ gan-an ni pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń kẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ẹlòmíì.

Bíbélì sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Èyí fi hàn pé a máa láyọ̀ tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn, tá a jẹ́ ọ̀làwọ́, tá a sì ka àwọn èèyàn sí pàtàkì ju àwọn ohun ìní lọ.