Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tí Ẹnì Kan Tó O Fẹ́ràn Bá Kú

Tí Ẹnì Kan Tó O Fẹ́ràn Bá Kú

“Nígbà tí ẹ̀gbọ́n mi kú lójijì, ńṣe ni ìbànújẹ́ dorí mi kodò. Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn ìgbà yẹn, màá kàn ṣàdédé rántí wọn, àárẹ̀ á sì mú mi, á sì dà bíi pé wọ́n fi ọ̀bẹ gún ọkàn mi. Nígbà míì sì rèé, inú á bí mi gan-an. Màá wá máa bi ara mi pé kí ló dé tí ẹ̀gbọ́n mi fi kú? Ó sì máa ń dùn mí pé mi ò lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú wọn kí wọ́n tó kú.”​—Vanessa, Australia.

TÍ ẸNÌ kan tá a fẹ́ràn bá kú, ìbànújẹ́ àti ìdánìkanwà tó máa ń fà kì í ṣe kékeré, ó sì lè mú kí nǹkan tojú súni. Ó tún lè mú kí èèyàn máa bínú, kí ẹ̀rí ọkàn máa dáni lẹ́bi tàbí kéèyàn máa bẹ̀rù. Kódà, èèyàn tiẹ̀ lè ro ara rẹ̀ pin pé ó ti tán fún òun pátápátá.

Àmọ́, fi sọ́kàn pé kì í ṣe ohun tó burú láti ṣọ̀fọ̀ ikú èèyàn rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi hàn pé o fẹ́ràn ẹni tó kú náà gan-an. Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan mélòó kan tó lè mú kí ara tù ẹ́ tó o bá ń ṣọ̀fọ̀.

OHUN TÓ RAN ÀWỌN KAN LỌ́WỌ́

Tó bá dà bíi pé ẹ̀dùn ọkàn rẹ kò fẹ́ lọ bọ̀rọ̀, o lè fi àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí tu ara rẹ nínú:

MÁ ṢE PA ẸKÚN MỌ́RA

Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀dùn ọkàn kálukú yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ náà ni àkókò tá a máa ń lò kí ara wa tó balẹ̀ ṣe máa ń yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, téèyàn bá sunkún, ó máa ń jẹ́ kí ara tuni. Vanessa, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo rí i pé tí mo bá sunkún, ara máa ń tù mí.” Sofía, tí àbúrò rẹ̀ obìnrin kú lójijì sọ pé: “Inú mi máa ń bà jẹ́ gan-an tí mo bá ń ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá ń wẹ ojú egbò tó ti kẹ̀, ìrora náà lè pọ̀, àmọ́ ìyẹn ló máa jẹ́ kí egbò náà jiná.”

SỌ BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÁRA RẸ

Ká sòótọ́, nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o má ṣe dá sí ẹnikẹ́ni. Àmọ́ máa rántí pé ńṣe ni ìbànújẹ́ dà  bí ẹ̀rù kan tó wúwo tí kò yẹ kó o dá gbé. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó ń jẹ́ Jared, pàdánù Bàbá rẹ̀, ó sọ pé: “Mo sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún àwọn míì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mi lè má fi bẹ́ẹ̀ yé wọn, síbẹ̀ ara tù mí nígbà tí mo sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi.” Janice tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ náà sọ pé: “Bí mo ṣe sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún àwọn ẹlòmíì tù mí nínú gan-an. Mo rí i pé ọ̀rọ̀ mi yé wọn, wọn ò sì dá mi dá ìṣòro mi.”

JẸ́ KÍ WỌ́N RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

Dókítà kan sọ pé: “Tí ẹni tó bá ń ṣọ̀fọ̀ bá gbà kí àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ran òun lọ́wọ́ ní gbàrà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ó máa rọrùn fún un láti fara da ẹ̀dùn ọkàn náà, ara rẹ̀ á sì tètè balẹ̀.” Jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mọ bí wọ́n ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n máa ń fẹ́ ṣèrànwọ́ àmọ́ wọn kì í mọ ohun tí wọ́n lè ṣe.​—Òwe 17:17.

TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Tina sọ pé: “Nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ pa ọkọ mi, mi ò ní alábàárò mọ́. Torí náà, Ọlọ́run ni mo máa ń sọ gbogbo ìṣòro mi fún! Tí mo bá ti jí láràárọ̀, màá bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n lè ru ọjọ́ yẹn là. Ọlọ́run sì ràn mí lọ́wọ́ ju bí mo ṣe rò lọ.” Tarsha, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún nígbà tí ìyá rẹ̀ kú sọ pé: “Mo máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, ìyẹn sì ti tù mí nínú gan-an. Ó jẹ́ kí n lè máa ronú lórí àwọn nǹkan tó ń gbéni ró.”

MÁA RONÚ NÍPA ÀJÍǸDE

Tina ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, mi ò kọ́kọ́ rí ìtùnú kankan nínú ìrètí àjíǹde torí pé nígbà yẹn àárò ọkọ mi ń sọ mí gan-an, àwọn ọmọkùnrin mi náà sì ń ṣàárò bàbá wọn. Àmọ́, ọdún mẹ́rin ti kọjá báyìí, mo lè sọ pé ìrètí àjíǹde yẹn ló ń gbé mi ró. Òun ni kò jẹ́ kí n sọ ìrètí nù. Mo máa ń ronú nípa ìgbà tí màá tún rí ọkọ mi, ìyẹn máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀, ó sì máa ń fún mi láyọ̀!”

Lóòótọ́, kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀dùn ọkàn rẹ máa kúrò. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí Vanessa sọ fini lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ẹ̀dùn ọkàn rẹ kò ní lọ, àmọ́ tó bá yá, ara á máa tù ẹ́ díẹ̀díẹ̀.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárò ẹni yẹn á ṣì máa sọ ẹ́, ayé rẹ ṣì máa dùn. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run aláàánú, o ṣì lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ kó o sì gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Má sì gbàgbé pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde láìpẹ́. Ó fẹ́ kó o tún pa dà rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú. Nígbà yẹn, ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ rẹ á kúrò pátápátá!