Àwọn Arákùnrin Méjì Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
NÍ OCTOBER 5, 2024, wọ́n ṣèfilọ̀ pàtàkì kan níbi ìpàdé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: Arákùnrin Jody Jedele àti Arákùnrin Jacob Rumph ti di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ti pẹ́ gan-an táwọn arákùnrin méjèèjì yìí ti ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.
Arákùnrin Jody Jedele àti Damaris ìyàwó ẹ̀ rèé
Wọ́n bí Arákùnrin Jedele sí ìpínlẹ̀ Missouri, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì làwọn òbí ẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbi tí ìdílé wọn ń gbé. Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn ará látibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè náà máa ń wá sí agbègbè wọn láti wàásù, ìyẹn jẹ́ kó mọ ọ̀pọ̀ lára wọn. Bó ṣe rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì wà níṣọ̀kan jẹ́ kó wù ú láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí náà, ó ṣèrìbọmi ní October 15, 1983 nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Inú ẹ̀ máa ń dùn láti lọ wàásù, lẹ́yìn tó sì parí ilé ẹ̀kọ́ girama, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní September 1989.
Nígbà tí Arákùnrin Jedele wà ní kékeré, àwọn òbí ẹ̀ máa ń mú òun àti àbúrò ẹ̀ obìnrin lọ wo Bẹ́tẹ́lì. Ìyẹn jẹ́ káwọn ọmọ náà pinnu pé iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì làwọn máa ṣe, wọ́n sì pe àwọn méjèèjì sí Bẹ́tẹ́lì nígbà tó yá. Arákùnrin Jedele dé sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill ní September 1990. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìmọ́tótó ló ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́, lẹ́yìn náà ó ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ìlera.
Lásìkò yẹn, àwọn ará ń pọ̀ sí i láwọn ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì nítòsí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì fẹ́ káwọn arákùnrin wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí náà, Arákùnrin Jedele bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìjọ yẹn, ó sì ń kọ́ èdè Sípáníìṣì. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ó pàdé arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Damaris, àyíká kan náà ni wọ́n sì wà. Nígbà tó yá wọ́n ṣègbéyàwó, àwọn méjèèjì sì jọ ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì.
Nígbà tó dọdún 2005, wọ́n kúrò ní Bẹ́tẹ́lì kí wọ́n lè lọ bójú tó àwọn òbí wọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́. Ní gbogbo àsìkò yẹn, iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni wọ́n ń ṣe. Arákùnrin Jedele máa ń ṣe olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà, ó sì wà lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn àti Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé lágbègbè ibi tí wọ́n wà.
Lọ́dún 2013, wọ́n ní kí Arákùnrin àti Arábìnrin Jedele pa dà sí Bẹ́tẹ́lì kí wọ́n lè wá ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ní Warwick. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n tún ṣiṣẹ́ ní Patterson àti Wallkill. Arákùnrin Jedele ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ àti Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn. Nígbà tó di March 2023, Arákùnrin Jedele di olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Nígbà tó ń sọ nípa oríṣiríṣi iṣẹ́ tó ti ṣe nínú ètò Ọlọ́run, ó ní: “Tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé iṣẹ́ kan fún wa, ẹ̀rù lè kọ́kọ́ bà wá, ká sì rò pé a ò ní lè ṣe é. Àmọ́, àsìkò yẹn gan-an ló yẹ ká gbára lé Jèhófà torí Jèhófà lè sọ wá di ohun tó fẹ́ ká lè ṣiṣẹ́ tó bá gbé fún wa.”
Arákùnrin Jacob Rumph àti Inga ìyàwó ẹ̀ rèé
Ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí Arákùnrin Rumph sí. Nígbà tó wà ní kékeré, ìyá ẹ̀ ò wàásù mọ́, kò sì lọ sípàdé mọ́. Àmọ́, ìyá ẹ̀ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọdọọdún ni Arákùnrin Rumph máa ń lọ sọ́dọ̀ ìyá bàbá ẹ̀, ó sì ti pẹ́ tí ìyá náà ti ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ìyá bàbá ẹ̀ ràn án lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, nígbà tó sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13), ó ní kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, ní September 27, 1992, ó ṣèrìbọmi kó tó pé ọmọ ogún (20) ọdún. Inú wa dùn pé lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìyá ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe déédéé nínú ìjọsìn Ọlọ́run, bàbá ẹ̀ àtàwọn àbúrò ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.
Nígbà tí Arákùnrin Rumph wà lọ́dọ̀ọ́, ó rí i pé inú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà máa ń dùn. Torí náà, nígbà tó parí ilé ẹ̀kọ́ girama, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní September 1995. Lọ́dún 2000, ó kó lọ sórílẹ̀-èdè Ecuador níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù gan-an. Ibẹ̀ ló ti pàdé Arábìnrin Inga tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà láti orílẹ̀-èdè Kánádà, nígbà tó sì yá wọ́n ṣègbéyàwó. Ìlú kan ní Ecuador ni wọ́n ń gbé lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kékeré kan. Ní báyìí, àwùjọ náà ti di ìjọ, àwọn ará sì pọ̀ níbẹ̀.
Nígbà tó yá, Arákùnrin àti Arábìnrin Rumph di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, lẹ́yìn náà wọ́n ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Lọ́dún 2011, wọ́n pè wọ́n sí kíláàsì kejìléláàádóje (132) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n láǹfààní láti sìn láwọn orílẹ̀-èdè márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì gbádùn oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn, ìyẹn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, iṣẹ́ míṣọ́nnárì àti iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Arákùnrin Rumph tún láǹfààní láti ṣe olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run.
Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, ètò Ọlọ́run sọ pé kí Arákùnrin àti Arábìnrin Rumph pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn tí wọ́n dé, wọ́n pè wọ́n sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill, wọ́n sì dá Arákùnrn Rumph lẹ́kọ̀ọ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ní kí wọ́n pa dà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Ecuador, Arákùnrin Rumph sì di ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka níbẹ̀. Lọ́dún 2023, ètò Ọlọ́run tún ní kí wọ́n lọ máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Warwick. Ní January 2024, Arákùnrin Rumph di olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Nígbà tó ń sọ nípa oríṣiríṣi iṣẹ́ tó ti ṣe nínú ètò Ọlọ́run, ó ní, “Àwọn èèyàn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ló jẹ́ kí iṣẹ́ wa ṣàrà ọ̀tọ̀, kì í ṣe ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́.”
A mọyì iṣẹ́ àṣekára táwọn arákùnrin yìí ń ṣe, ó sì yẹ ká “máa ka irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.”—Fílí. 2:29.

