ÀPILẸ̀KỌ 40
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
Jèhófà Ni Ayọ̀ Wa
“ Màá wá . . . sọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó jẹ́ ayọ̀ ńlá mi.”—SM. 43:4.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tó lè mú ká má láyọ̀ mọ́ àtohun tó máa jẹ́ ká pa dà láyọ̀.
1-2. (a) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí? (b) Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
LÓNÌÍ oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn ń ṣe kí wọ́n lè láyọ̀. Síbẹ̀, ayọ̀ wọn kì í tọ́jọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni inú wọn kì í dùn, wọ́n sì gbà pé nǹkan ò lè dáa fáwọn mọ́. Kódà nígbà míì, ó lè máa ṣe àwa èèyàn Jèhófà náà bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa sì lè jẹ́ kí nǹkan “nira” gan-an.—2 Tím. 3:1.
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tó lè má jẹ́ ká láyọ̀ mọ́ àtohun tó máa jẹ́ ká pa dà láyọ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Ẹni tó lè jẹ́ ká láyọ̀ tòótọ́.
ẸNI TÓ LÈ FÚN WA LÁYỌ̀ TÒÓTỌ́
3. Kí làwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà kọ́ wa nípa ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
3 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń láyọ̀. Ó sì fẹ́ káwa náà máa láyọ̀. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwọn ohun tí Jèhófà dá jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run aláyọ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dá ayé wa yìí lọ́nà tó rẹwà gan-an, à ń rí oríṣiríṣi àwọ̀ mèremère, à ń rí báwọn ẹranko ṣe ń bára wọn ṣeré, a sì ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ aládùn. Àbí ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́, ó sì fẹ́ ká gbádùn ayé wa!
Baby elephant: Image © Romi Gamit/Shutterstock; penguin chicks: Vladimir Seliverstov/500px via Getty Images; baby goats: Rita Kochmarjova/stock.adobe.com; two dolphins: georgeclerk/E+ via Getty Images
Tá a bá rí àwọn ẹranko tó ń bára wọn ṣeré, àá rántí pé aláyọ̀ ni Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 3)
4. (a) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń rí gbogbo ìṣòro tó wà láyé, kí nìdí tó fi ń láyọ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? (Sáàmù 16:11)
4 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń rí gbogbo ìṣòro tó wà láyé àti ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn, síbẹ̀ ó ṣì ń láyọ̀ torí Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni. (1 Tím. 1:11) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń láyọ̀? Ìdí ni pé ó mọ̀ pé gbogbo ìyà máa tó dópin torí òun fúnra ẹ̀ ti pinnu ìgbà tó máa fòpin sí i. Torí náà, ó ń mú sùúrù dìgbà tó máa mú ìyà àti omijé kúrò pátápátá. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, Jèhófà mọ ohun tá à ń bá yí, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Báwo ló ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? Ọ̀kan lára ohun tó ń ṣe ni pé ó ń jẹ́ ká láyọ̀. (Ka Sáàmù 16:11.) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí Jésù láyọ̀.
5-6. Kí nìdí tí Jésù fi ń láyọ̀?
5 Nínú gbogbo àwọn tí Jèhófà dá, Jésù ló láyọ̀ jù. Kí nìdí? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé “òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí,” ó sì fìwà jọ Bàbá ẹ̀ láì kù síbì kan. (Kól. 1:15; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “happy” tá a ṣe lórí 1 Tímótì 6:15 nínú nwtsty-E.) Ìdí kejì ni pé àìmọye ọdún ni Jésù ti lò pẹ̀lú Bàbá ẹ̀ tó jẹ́ orísun ayọ̀.
6 Jésù tún ń láyọ̀ torí ìgbà gbogbo ló máa ń ṣe ohun tí Bàbá ẹ̀ ní kó ṣe. (Òwe 8:30, 31; Jòh. 8:29) Torí pé ó jẹ́ olóòótọ́, inú Jèhófà dùn sí i, ó sì tẹ́wọ́ gbà á.—Mát. 3:17.
7. Kí ló máa jẹ́ ká láyọ̀ tòótọ́?
7 Àwa náà lè ní ayọ̀ tòótọ́ tá a bá sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Orísun ayọ̀. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà tá a sì ń fara wé e, àá túbọ̀ máa láyọ̀. A tún máa láyọ̀ tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, tá a sì mọ̀ pé inú ẹ̀ ń dùn sí wa. a (Sm. 33:12) Àmọ́ tá a bá kíyè sí pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan inú wa kì í dùn àbí kó jẹ́ ọ̀pọ̀ ìgbà la kì í láyọ̀ ńkọ́? Ṣéyẹn túmọ̀ sí pé inú Jèhófà ò dùn sí wa ni? Rárá o! Ìdí ni pé Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, ó sì mọ̀ pé àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa dùn wá tó sì lè mú ká banú jẹ́. (Sm. 103:14) Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó lè má jẹ́ ká láyọ̀ mọ́ àtohun tó máa jẹ́ ká pa dà láyọ̀.
MÁ JẸ́ KÍ OHUNKÓHUN BA AYỌ̀ Ẹ JẸ́
8. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá níṣòro?
8 Nǹkan àkọ́kọ́ tó lè mú ká má láyọ̀ mọ́: Ìṣòro. Oríṣiríṣi ìṣòro ló ṣeé ṣe ká ní. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa ṣenúnibíni sí wa, àjálù lè ṣẹlẹ̀, a lè má lówó lọ́wọ́, a lè ṣàìsàn, ó sì lè jẹ́ pé ọjọ́ ogbó ló ti dé. Irú àwọn nǹkan yìí lè jẹ́ káyé sú wa ká má sì láyọ̀, pàápàá tí ò bá sí nǹkan tá a lè ṣe sí i. Kódà, Bíbélì sọ pé “ẹ̀dùn ọkàn máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.” (Òwe 15:13) Alàgbà kan tó ń jẹ́ Babis pàdánù ẹ̀gbọ́n kan ṣoṣo tó ní, bàbá àti màmá ẹ̀ láàárín ọdún mẹ́rin péré. Ó sọ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé mo dá wà, kò sì sẹ́ni tó lè ràn mí lọ́wọ́. Nígbà míì, mo máa ń ní ìdààmú ọkàn tó le gan-an, torí ó wù mí kí n lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú àwọn òbí mi àti ẹ̀gbọ́n mi kí wọ́n tó kú, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún mi.” Bíi Babis, àwa náà lè níṣòro tó le gan-an, tó sì lè jẹ́ kí nǹkan sú wa.
9. Kí ló lè jẹ́ ká pa dà láyọ̀? (Jeremáyà 29:4-7, 10)
9 Kí ló máa jẹ́ ká pa dà láyọ̀? A máa láyọ̀ tá ò bá dara wa láàmú nípa àwọn nǹkan tá ò lè ṣe, tá a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí àwọn nǹkan tó ṣe fún wa. Àwọn èèyàn inú ayé gbà pé nǹkan gbọ́dọ̀ máa lọ geerege ká tó lè láyọ̀. Àmọ́ irọ́ gbuu nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fáwọn Júù tó lọ sígbèkùn ní Bábílónì pé kí wọ́n gbádùn ara wọn, kí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe nílùú tuntun tí wọ́n wà. (Ka Jeremáyà 29:4-7, 10.) Kí la kọ́? Máa ronú nípa àwọn nǹkan tó dáa tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ, kó o sì máa dúpẹ́ fún àwọn nǹkan yìí. Rántí pé Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm. 63:7; 146:5) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Effie, kò lè rìn mọ́, ó wá sọ pé: “Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an, àwọn ará ilé mi àtàwọn ará inú ìjọ náà sì ràn mí lọ́wọ́. Torí náà, tí mi ò bá láyọ̀ tí mo sì ń kárísọ, ṣe ló máa dà bíi pé mi ò moore. Mo fẹ́ kí Jèhófà àtàwọn ọ̀rẹ́ mi mọ̀ pé mo mọrírì gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe fún mi.”
10. Kí nìdí tá a fi lè máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ níṣòro?
10 Tí nǹkan ò bá lọ bá a ṣe fẹ́ tàbí tí nǹkan tí kò dáa bá ṣẹlẹ̀ sí àwa tàbí àwọn ará ilé wa, a ṣì lè láyọ̀. b (Sm. 126:5) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa kọ́ ló ń pinnu bóyá a máa láyọ̀ àbí a ò ní láyọ̀. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Maria sọ pé: “Tó o bá níṣòro tó o sì ń láyọ̀, ìyẹn ò sọ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn ò dùn ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé o ò gbàgbé àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Baba wa ọ̀run á jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ níṣòro.” Máa rántí pé kò sí bí ìṣòro kan ṣe lè le tó, fúngbà díẹ̀ ni. Ó máa tó pòórá bí èéfín ṣe ń pòórá sínú afẹ́fẹ́. Láìpẹ́, Jèhófà máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìbànújẹ́ kúrò, a ò sì ní rántí wọn mọ́.
11. Kí la rí kọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?
11 Tó bá ń ṣe wá bíi pé inú Jèhófà ò dùn sí wa la ṣe ń níṣòro ńkọ́? Ọkàn wa máa balẹ̀ tá a bá ronú nípa àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó níṣòro tó le gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Jésù fúnra ẹ̀ ló yàn án láti wàásù òtítọ́ fún “àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣe 9:15) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn! Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù láwọn ìṣòro tó ń bá a fínra. (2 Kọ́r. 11:23-27) Ṣé àwọn ìṣòro tó dà bí òkè tí Pọ́ọ̀lù ní yìí wá túmọ̀ sí pé inú Jèhófà ò dùn sí i mọ́? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe ń fara dà á fi hàn pé inú Jèhófà ń dùn sí i. (Róòmù 5:3-5) Wá ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ síwọ náà báyìí. Ò ń fara dà á bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ní ọ̀pọ̀ ìṣòro. Torí náà, ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ.
12. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tọ́wọ́ wa ò bá tẹ ohun tá a fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run?
12 Nǹkan kejì tó lè mú ká má láyọ̀ mọ́: Tọ́wọ́ wa ò bá tẹ ohun tá a fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Òwe 13:12) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọrírì ohun tó ń ṣe fún wa, a máa ń fẹ́ ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìjọsìn ẹ̀. Àmọ́ tọ́wọ́ wa ò bá tẹ ohun tó wù wá láti ṣe nínú iṣẹ́ Ọlọ́run nítorí ipò tá a wà, a lè má láyọ̀ mọ́. (Òwe 17:22) Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Holly sọ pé: “Ohun tó wù mí ni pé kí n lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere, kí n lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè tàbí kí n lọ ṣiṣẹ́ ní Ramapo. Àmọ́ ipò mi yí pa dà, mi ò sì lè ṣe àwọn nǹkan yẹn mọ́. Ó dùn mí gan-an. Nǹkan máa ń tojú súni téèyàn bá fẹ́ ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan àmọ́ tí ò lè ṣe é.” Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí.
13. Tí ipò wa ò bá jẹ́ ká lè ṣe àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe, kí làwọn nǹkan míì tá a lè ṣe?
13 Kí ló máa jẹ́ ká pa dà láyọ̀? Máa rántí pé Jèhófà kì í fipá mú wa pé ká ṣe nǹkan. Kò fẹ́ ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ, kì í sì í ṣe nǹkan tá a bá gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ ló fi ń díwọ̀n bá a ṣe ṣeyebíye tó. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká ṣe ìwọ̀n tá a lè ṣe, ká sì jẹ́ olóòótọ́. (Míkà 6:8; 1 Kọ́r. 4:2) Ohun tó wà lọ́kàn wa ló máa ń wò, kì í ṣe ohun tá à ń ṣe táwọn èèyàn lè rí. Ṣé ó wá yẹ ká máa ṣe ohun tó ju agbára wa lọ tó sì jẹ́ pé Jèhófà ò retí pé ká ṣe bẹ́ẹ̀? c Rárá o! Torí náà, tí ipò tó o wà ò bá jẹ́ kó o ṣe àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, á dáa kó o gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó o lè ṣe. Ṣé o lè gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú àbí ṣé o lè ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ kára lè tù wọ́n? Ṣé o lè pinnu pé wàá máa fún àwọn ará níṣìírí lójúkojú, lórí fóònù tàbí kó o fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí wọn? Jèhófà máa jẹ́ kó o láyọ̀ bó o ṣe ń ṣe àwọn nǹkan tó o lè ṣe yẹn. Máa rántí pé láìpẹ́, a máa láǹfààní tó pọ̀ nínú ayé tuntun láti sin Jèhófà bó ṣe wù wá. Nígbà tí Holly tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní: “Tí mo bá ń ronú nípa ẹ̀, mo máa ń sọ fún ara mi pé lágbára Jèhófà, a máa wà láàyè títí láé. Torí náà, mo mọ̀ pé Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́ kọ́wọ́ mi lè tẹ gbogbo ohun tí mo bá fẹ́ nínú ayé tuntun.”
14. Nǹkan míì wo ló lè má jẹ́ ká láyọ̀ mọ́?
14 Nǹkan kẹta tó lè mú ká má láyọ̀ mọ́: Kéèyàn máa gbádùn ara ẹ̀ ṣáá. A máa ń rí àwọn kan lórí ìkànnì àjọlò tí wọ́n máa ń sọ pé èèyàn máa ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ tòótọ́ tó bá ń gbádùn ara ẹ̀ dọ́ba. Wọ́n máa ń sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n máa ṣeré ìnàjú, kí wọ́n máa ra nǹkan tó bá ṣáà ti wù wọ́n, kí wọ́n sì máa rìnrìn àjò afẹ́ káàkiri. Kò burú téèyàn bá ń gbádùn ara ẹ̀ torí Jèhófà fẹ́ ká gbádùn àwọn nǹkan tó dá. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ti rí i pé ohun tí wọ́n rò pé ó máa fáwọn láyọ̀ ló ń kó wàhálà bá wọn. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Eva sọ pé: “Tó bá jẹ́ bó o ṣe máa gbádùn ara ẹ lò ń wá ní gbogbo ìgbà, ohun tó o ní kò ní tó ẹ.” Torí náà, àwọn tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa gbádùn ara wọn ṣáá ni wọ́n ń wá ò lè láyọ̀.
15. Kí la kọ́ lára Ọba Sólómọ́nì?
15 A lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Sólómọ́nì nígbà tó ń fi gbogbo àkókò ẹ̀ jẹ̀gbádùn. Ó rò pé òun máa láyọ̀ tóun bá ń gbádùn ṣáá, bíi kó máa jẹ oúnjẹ tó dáa, kó máa gbọ́ orin amóríyá tàbí kó ra àwọn nǹkan olówó ńlá tó wà nígbà àtijọ́. Àmọ́ gbogbo nǹkan yẹn ò fún un láyọ̀. Ó sọ pé: “Ìran kì í sú ojú; bẹ́ẹ̀ ni etí kì í kọ gbígbọ́.” (Oníw. 1:8; 2:1-11) Ọ̀pọ̀ rò pé táwọn bá lówó, àwọn á lè ṣe ohun tó wu àwọn, àwọn á sì láyọ̀. Àmọ́ irọ́ gbuu nìyẹn, àwọn nǹkan tara kò lè fúnni láyọ̀.
16. Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, báwo ló ṣe máa jẹ́ ká pa dà láyọ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Kí ló máa jẹ́ ká pa dà láyọ̀? Jésù kọ́ wa pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Alàgbà kan tó ń jẹ́ Alekos sọ pé: “Mo máa ń ṣe àwọn nǹkan kéékèèké fáwọn èèyàn. Bí mo ṣe ń ṣe nǹkan fáwọn èèyàn ni ò jẹ́ kí n máa ronú nípa ìṣòro mi mọ́, mo sì ń láyọ̀.” Kí lo lè ṣe fáwọn èèyàn? Tó o bá rẹ́ni tó níṣòro, gbìyànjú kó o ràn án lọ́wọ́. O lè má lágbára láti yanjú ìṣòro ẹ̀, àmọ́ o lè tù ú nínú tó o bá ń gba tiẹ̀ rò, tó ò ń bá a kẹ́dùn, tó o sì ń rán an létí pé kó sọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ fún Jèhófà. (Sm. 55:22; 68:19) O tún lè jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú ẹ̀ gbágbáágbá. (Sm. 37:28; Àìsá. 59:1) O tiẹ̀ lè bá a ṣe àwọn nǹkan kan, bíi kó o bá a se oúnjẹ tàbí kẹ́ ẹ jọ rìn jáde lọ. Ẹ lè jọ lọ wàásù, ìyẹn á sì jẹ́ kára ẹ̀ yá gágá. Jẹ́ kí Jèhófà lò ẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, a máa láyọ̀!—Òwe 11:25.
Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ dípò kó o máa ro tara ẹ nìkan (Wo ìpínrọ̀ 16) d
17. Kí la máa ṣe tá a bá fẹ́ láyọ̀? (Sáàmù 43:4)
17 A máa láyọ̀ gan-an tá a bá túbọ̀ sún mọ́ Bàbá wa Jèhófà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni “ayọ̀” wa. (Sáàmù 43:4.) Tá a bá tiẹ̀ níṣòro, ẹ jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tó ń fún wa láyọ̀!—Sm. 144:15.
ORIN 155 Orísun Ayọ̀ Wa
a Wo àpótí náà, “ Jẹ́ Kí Jèhófà Fún Ẹ Láyọ̀.”
b Bí àpẹẹrẹ, wo fídíò Dennis àti Irina Christensen nínú Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2023 #5 lórí jw.org.
c Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Láti Lè Máa Láyọ̀, Ohun Tọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀ Ni Kó O Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2008.
d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan lọ ra ọ̀pọ̀ nǹkan fún ara ẹ̀, àmọ́ ohun tó fún un láyọ̀ jù ni bó ṣe ra òdòdó fún arábìnrin àgbàlagbà kan tó nílò ìtùnú.

