Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Là Ń Pè Ní Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kí Là Ń Pè Ní Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

 Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni àwùjọ àwọn Kristẹni kan tó dàgbà dénú tó ń darí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Ọ̀nà méjì ni iṣẹ́ wọn pín sí:

 •   Wọ́n ń bójú tó báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń rí ìtọ́ni tó dá lórí Bíbélì gbà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, àwọn ìpàdé wa àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a máa ń lọ.​—Lúùkù 12:42.

 •   Wọ́n ń darí iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé, ní ti pé wọ́n ń darí iṣẹ́ ìwàásù wa àti bá a ṣe ń lo ọrẹ.

 Àpẹẹrẹ “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù” ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń tẹ̀ lé. Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin yìí ló máa ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó kan gbogbo ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 15:2) Bíi tàwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí kì í ṣe olórí wa. Inú Bíbélì ni wọ́n ti máa ń wá ìtọ́sọ́nà, wọ́n sì gbà pé Jèhófà Ọlọ́run ti yan Jésù Kristi ṣe Orí ìjọ.​—1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:​23.

Àwọn wo ló wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí?

 Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní January ọdún 2018 ni Kenneth Cook, Jr., Samuel Herd, Geoffrey Jackson, Stephen Lett, Gerrit Lösch, Anthony Morris III, Mark Sanderson àti David Splane. Oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, ìpínlẹ̀ New York, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́.

Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń ṣe iṣẹ́ wọn?

 Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní ìgbìmọ̀ kéékèèké mẹ́fà tó ń bójú tó onírúurú iṣẹ́ tá à ń ṣe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń wà nínú ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ìgbìmọ̀ kéékèèké yìí.

 •   Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ àti òfin, àwọn ló ń gbé ìgbésẹ̀ tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí àwọn ará wa torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, tàbí táwọn ọ̀rọ̀ pàjáwìrì míì bá ṣẹlẹ̀ tó kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 •   Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó ìṣètò tó wà fáwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì.

 •   Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó bá a ṣe ń tẹ̀wé tó dá lórí Bíbélì jáde, tá a sì ń kó o ránṣẹ́. Àwọn ló ń bójú tó bá a ṣe ń kọ́ àwọn ibi tá a ti ń ṣèpàdé, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì.

 •   Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń darí bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere ìjọba” náà.​—Mátíù 24:14.

 •   Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń darí bá a ṣe ń rí ìtọ́ni tó dá lórí Bíbélì gbà láwọn ìpàdé, ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì, lórí fídíò àtàwọn ètò tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀.

 •   Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé: Ìgbìmọ̀ yìí ló ń darí bá a ṣe ń rí ìtọ́ni tó dá lórí Bíbélì gbà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa àti lórí ìkànnì wa, àwọn ló sì ń bójú tó iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè.

 Yàtọ̀ sí pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń bá àwọn ìgbìmọ̀ kéékèèké yìí ṣiṣẹ́, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fúnra wọn máa ń pàdé láti bójú tó ohun tí ètò wa nílò. Láwọn ìpàdé yìí, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń jíròrò ohun tí Bíbélì sọ, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run darí wọn kí wọ́n lè fẹnu kò lórí àwọn ìpinnu tí wọ́n fẹ́ ṣe.​—Ìṣe 15:25.

Àwọn wo ni olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí?

 Kristẹni tó ṣeé fọkàn tán làwọn olùrànlọ́wọ́ yìí, àwọn ló ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbìmọ̀ kéékèèké tí wọ́n pín iṣẹ́ wọn sí. (1 Kọ́ríńtì 4:2) Wọ́n tóótun, wọ́n ní ìrírí lẹ́nu iṣẹ́ tí ìgbìmọ̀ tí wọ́n yàn wọ́n sí ń bójú tó, wọ́n sì máa ń lọ sípàdé tí ìgbìmọ̀ náà máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í bá Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣèpinnu, ìmọ̀ràn wọn máa ń wúlò gan-an, wọ́n sì máa ń ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni lọ́wọ́. Àwọn ni wọ́n máa ń gbé ìgbésẹ̀ lórí ìpinnu tí ìgbìmọ̀ náà bá ṣe, wọ́n sì máa ń wo ibi tí àwọn ìpinnu náà bá já sí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún lè yan àwọn olùrànlọ́wọ́ yìí pé kí wọ́n lọ bẹ àwọn ará wa wò káàkiri ayé tàbí kí wọ́n lọ sọ àsọyé láwọn àpéjọ kan, bíi ìpàdé ọdọọdún tàbí ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ní Gílíádì.

ÀWỌN OLÙRÀNLỌ́WỌ́

Ìgbìmọ̀

Orúkọ

Olùṣekòkáárí

 • Ekrann, John

Ọ̀rọ̀ Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni

 • Grizzle, Gerald

 • LaFranca, Patrick

 • Molchan, Daniel

 • Walls, Ralph

Ìṣèwéjáde

 • Adams, Don

 • Butler, Robert

 • Corkern, Harold

 • Glockentin, Gajus

 • Gordon, Donald

 • Luccioni, Robert

 • Reinmueller, Alex

 • Sinclair, David

Iṣẹ́ Ìsìn

 • Breaux, Gary

 • Dellinger, Joel

 • Hyatt, Seth

 • Mavor, Christopher

 • Perla, Baltasar, Jr.

 • Turner, William, Jr.

 • Weaver, Leon, Jr.

Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́

 • Curzan, Ronald

 • Flodin, Kenneth

 • Malenfant, William

 • Noumair, Mark

 • Schafer, David

Ìkọ̀wé

 • Ciranko, Robert

 • Mantz, James

 • Marais, Izak

 • Smalley, Gene

 • van Selm, Hermanus