Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni Jésù ń sọ nígbà tó ní: “Ẹ má rò pé mo wá láti mú àlàáfíà wá”?

Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n jẹ́ ẹni àlàáfíà. Àmọ́ nígbà kan, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ má rò pé mo wá láti mú àlàáfíà wá sí ayé; ṣe ni mo wá láti mú idà wá, kì í ṣe àlàáfíà. Torí mo wá láti fa ìpínyà, ọkùnrin sí bàbá rẹ̀, ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.” (Mát. 10:34, 35) Àmọ́ kí ni Jésù ń sọ?

Kì í ṣe pé Jésù fẹ́ dá ìyapa sáàárín àwọn tó wà nínú ìdílé, àmọ́ ó mọ̀ pé ẹ̀kọ́ tóun ń kọ́ àwọn èèyàn máa dá ìyapa sáàárín àwọn ìdílé kan. Torí náà, ó yẹ káwọn tó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, tí wọ́n sì fẹ́ ṣèrìbọmi mọ̀ pé àwọn ará ilé wọn lè má fara mọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe. Nígbà míì, ó lè jẹ́ ọkọ, aya tàbí ará ilé wọn míì ló máa ta kò wọ́n, ìyẹn sì lè jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti gba ẹ̀kọ́ Kristi.

Bíbélì rọ àwa Kristẹni pé ká “wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.” (Róòmù 12:18) Àmọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù lè dà bí “idà” láwọn ìdílé kan. Ìyẹn máa ń ṣẹlẹ̀ tí ẹnì kan nínú ìdílé kan bá gba ẹ̀kọ́ Jésù, àmọ́ táwọn yòókù ò gba ẹ̀kọ́ náà. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ẹni tó gba ẹ̀kọ́ Jésù máa di “ọ̀tá” àwọn ará ilé rẹ̀.​—Mát. 10:36.

Nígbà míì, ohun kan lè ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí àwọn ará ilé wọn ń ṣe ẹ̀sìn míì tí ìyẹn sì máa dán ìgbàgbọ́ wọn wò bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará ilé wọn lè rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe àwọn ayẹyẹ ìsìn tó ta ko Bíbélì. Tí wọ́n bá dojú kọ irú àdánwò bẹ́ẹ̀, ta ni wọ́n máa gbọ́rọ̀ sí lẹ́nu? Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ bàbá tàbí ìyá jù mí lọ kò yẹ fún mi.” (Mát. 10:37) Àmọ́ ṣá o, Jésù ò sọ pé káwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn òun má nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jésù ń sọ ni pé kí wọ́n fi ohun tó ṣe pàtàkì jù sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. Tí àwọn ará ilé wa bá ń ta kò wá pé ká má jọ́sìn Jèhófà mọ́, a ò ní torí ẹ̀ kórìíra wọn, àmọ́ ó yẹ ká mọ̀ pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ló yẹ kó gba ipò àkọ́kọ́.

Kò sí àní-àní pé ó máa ń dùn wá gan-an táwọn ará ilé wa bá ń ta kò wá. Síbẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa ń rántí ohun tó sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé òpó igi oró rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi, kò yẹ fún mi.’ (Mát. 10:38) Lédè míì, àwọn tó di ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ pé àtakò látọ̀dọ̀ ará ilé wọn wà lára ohun táwọn máa fara dà. Àmọ́ wọ́n tún mọ̀ pé tí ìwà àwọn bá dáa, ó lè yí àwọn ará ilé wọn pa dà, kí wọ́n sì wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.​—1 Pét. 3:1, 2.