Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ BÍBÉLÌ WÚLÒ FÚN WA LÓNÌÍ?

Jije Oloooto

Jije Oloooto

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ [Ọlọ́run]? . . . Ẹni tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Sáàmù 15:1, 2.

ÈRÈ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Kò sẹ́ni tí kò fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òun sí olóòótọ́ àti adúróṣinṣin. Àmọ́, tí wọ́n bá rí ọ̀nà tí wọ́n fi lè ṣe èrú kí wọn sì rí èrè gọbọi nídìí ẹ̀, tẹ́ni kẹ́ni ò sì ní mọ̀ ńkọ́? Ẹ ò rí i pé ó gbèrò, ibi tí ọ̀rọ̀ ti kan ẹ̀rí ọkàn wa nìyẹn.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Raquel tó máa ń ra ọjà fún iléeṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Níbi tí mo ti máa ń rajà fún ilé iṣẹ́ wa, àwọn ọlọ́jà máa ń fi owó lọ̀ mí, pé tí mo bá rajà lọ́wọ́ àwọn, èmi ni àwọn á fún ní ‘ẹ̀dínwó’ orí rẹ̀ dípò kí àwọn fún iléeṣẹ́ wa. Mo rántí ohun tí Bíbélì sọ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀, mo sì sọ fún wọn pé rárá. Nígbà tí ọ̀gá mi gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ dùn, ó sì túbọ̀ kà mí sí ẹni tó ṣeé fọkàn tán.”

Ká ní Raquel ṣe ohun tí àwọn oníbàárà yẹn sọ ni, ó lè rí owó gidi, àmọ́ bí ọ̀gá rẹ̀ bá pa dà wá mọ̀, ṣé ọ̀rọ̀ ò ní lẹ́yìn? Ǹjẹ́ ẹ rò pé ọ̀gá yẹn kò ní lé e kúrò lẹ́nu iṣẹ́? Ṣé á rọrùn fún un láti ríṣẹ́ síbòmíì? Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì sí Raquel jù ni pé kóun ní ẹ̀rí ọkàn tó dára, kí àwọn èèyàn sì fọ̀wọ̀ wọ òun. Ó ṣe tán, Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Orúkọ ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀; ojú rere sàn ju fàdákà àti wúrà pàápàá.”—Òwe 22:1.

Jessie lórúkọ rere lọ́dọ̀ọ́ ọ̀gá rẹ̀ torí pé ó jẹ́ olóòótọ́

Àpẹẹrẹ míì ni ti Jessie. Òun náà fi ara rẹ̀ hàn ní olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ìdí nìyí tó fi lórúkọ rere lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Èrè wo ló rí nínú ìṣòtítọ́ rẹ̀? Wọ́n gbé e sípò ńlá, wọ́n sì tún máa ń fún un láyè dáadáa níbi iṣẹ́. Torí náà, ó túbọ̀ máa ń wà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, ó sì tún ráyè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run dáadáa.

Àwọn iléeṣẹ́ kan tó ń wá òṣìṣẹ́ máa ń lọ síbi tí wọ́n ti lè rí àwọn olóòótọ́ tí wọ́n á gbà sẹ́nu iṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá iléeṣẹ́ kan ní orílẹ̀-èdè Philippines kọ̀wé sí ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè yẹn pé òun ń wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tóun máa gbà sí iṣẹ́. Ó sọ pé, “wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì tún máa ń jára mọ́ṣẹ́.” Jèhófà Ọlọ́run ni ọpẹ́ yẹ torí pé òun ló kọ́ wa pé ká “kórìíra ohun búburú,” ká sì “nífẹ̀ẹ́ ohun rere.”—Ámósì 5:15.