Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òtítọ́ Ló Pé

Òtítọ́ Ló Pé

Òtítọ́ Ló Pé

“Oúnjẹ tí a fi èké jèrè gbádùn mọ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà náà, ẹnu rẹ̀ yóò kún fún taàrá.”—Òwe 20:17.

ṢÉ Ó di dandan kéèyàn lọ́wọ́ nínú ìwà àìṣòótọ́ kó tó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ajé? Rárá o. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ńṣe ni ìwà àìṣòótọ́ máa ń kó báni. Kí nìdí? Ìdí ni pé “òtítọ́ ló máa lékè” bí àwọn èèyàn ṣe máa n sọ.” Àwọn èèyàn máa ń fọkàn tán àwọn olóòótọ́, ìyẹn sì ṣe pàtàkì gan-an bí èèyàn bá fẹ́ ṣe àṣeyọrí tó máa tọ́jọ́.

Èrè Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Fọkàn Tán

Bóyá o mọ̀ tàbí o kò mọ̀, tí àwọn èèyàn bá mọ̀ ẹ́ sí olóòótọ́, èyí máa jẹ́ kó o ṣe àṣeyọrí. Ìrírí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Franz, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. “Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n fi dán mi wò láti mọ̀ bóyá olóòótọ́ èèyàn ni mí, tí èmi ò sì mọ̀ rárá. Nígbà tó yá, wọ́n sọ fún mi pé mo yege ìdánwò àwọn. Èyí ti wá mú kí wọ́n túbọ̀ fa ọ̀pọ̀ nǹkan lé mi lọ́wọ́, wọn kì í sì í yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò, àwọn tí mò ń ṣiṣẹ́ fún sì ti san mí lẹ́san nítorí pé mo jẹ́ olóòótọ́. Mo mọ̀ pé àwọn míì wà tí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí mò ń ṣe lọ́nà tó dára ju bí mo ṣe ń ṣe é lọ, tí wọ́n sì já fáfá jù mí lọ, ṣùgbọ́n, mo wá rí i pé ohun tí kò jẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ mi ni pé àwọn tó gbà mí síṣẹ́ fọkàn tán mi.”

Sá fún Àwọn Ohun Tó Lè Kó Bá Ẹ

Ọkùnrin oníṣòwò tó ń jẹ́ David tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ pé: “Bí mo ṣe ń rí i tí àwọn èèyàn ń gba ọ̀nà ẹ̀bùrú kí ọwọ́ wọn lè tètè tẹ ohun tí wọ́n ń wá, mó máa ń sọ lọ́kàn mi pé, ‘Bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ́ kan ni òtítọ́ máa lé e bá.’ Lédè míì, àtúbọ̀tán àwọn aláìṣòótọ́ kì í dáa rárá. À kì í gba àwọn iṣẹ́ tó ń kọni lóminú tí wọ́n bá fi lọ̀ wá. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé iṣẹ́ tó máa ń lọ́wọ́ sí irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ ló máa ń kógbá wọlé nígbà tó bá yá, ọwọ́ òfin sì máa ń tẹ àwọn ẹlòmíì tí wọ́n á sì gbé wọn lọ sílé ẹjọ́. Àwọn nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ sí ilé iṣẹ́ tiwa.”

Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Ken fẹ́ dá oko kan tí yóò ti máa sin màlúù sílẹ̀ ní apá ìlà oòrùn gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà, ká sọ pé ó fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ì bá fún àwọn aláṣẹ ìjọba ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí ó lè ṣeé ṣe fún un láti máa kó àwọn ohun tó fẹ́ wọlé láti ilẹ̀ míì láìsan owó orí. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń ṣe irú iṣẹ́ yìí ló máa ń lọ́wọ́ sí àṣà tó wọ́pọ̀ gan-an yìí. Nítorí pé àwa kò bá wọn lọ́wọ́ sí ìwà àìṣòótọ́ yìí, ó gbà wá ní ọdún mẹ́wàá kó tó di pé oko màlúù tá a dá sílẹ̀ lójú. Àmọ́, ǹjẹ́ èrè wà nínú ohun tá a ṣe yìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìgbà gbogbo ni àwọn ọ̀gá tó jẹ́ jẹgúdújẹrá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba máa ń yọ àwọn tó ń san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lẹ́nu pé kí wọ́n tún wá san owó mìíràn.”

Bí Èèyàn Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Àtijẹ Àtimu

Tó bá dà bíi pé òwò tí èèyàn ń ṣe fẹ́ dojú dé, ó lè máa ṣe èèyàn bíi pé kó lọ́wọ́ nínú ìwà àìṣòótọ́. Àmọ́, irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ tún máa ń jẹ́ kéèyàn rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí èèyàn jẹ́ ẹni tí àwọn èèyàn mọ̀ sí olóòótọ́.

Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kọ́lékọ́lé kan tó ń jẹ́ Bill. Nígbà kan ti iṣẹ́ ilé kíkọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ tà mọ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọkùnrin yìí kò ríṣẹ́ gbà mọ́. Ó sọ pé: “Àwọn kan lára àwọn oníbàárà wa tó ṣe pàtàkì kógbá sílé, wọ́n sì jẹ wá ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó dọ́là. Nígbà tó di pé àtijẹ àtimu fẹ́ di ìṣòro, mo lọ sí ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ kọ́lékọ́lé tó wà ní àgbègbè wa bóyá wọ́n lè gba àwọn kan lára wa síṣẹ́. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí mo ṣe ìpàdé pẹ̀lú wọn, wọ́n gbà kí èmi àti èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ wá máa bá àwọn ṣiṣẹ́. Wọ́n sọ pé àwọn mọ̀ dáadáa pé mo máa ń ṣiṣẹ́ tó jọjú àti pé olóòótọ́ èèyàn ni mí.”

Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí. Ìlànà Bíbélì ni wọ́n ń tẹ̀ lé lẹ́nu iṣẹ́ ajé wọn àti nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wọn tó kù. Bí ìwọ náà ṣe rí i, bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ wọn mú èrè wá gan-an ni, dípò kí ó mú kí wọ́n kógbá sílé.

Síbẹ̀, àwọn ìgbà míì máa ń wà tí àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ tó máa dà bíi pé àǹfààní wà nínú àìṣòótọ́. Ṣé owó téèyàn ń rí nídìí iṣẹ́ nìkan ni ohun téèyàn fi ń pinnu bóyá ẹnì kan ṣe àṣeyọrí?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Bóyá o mọ̀ tàbí o kò mọ̀, tí àwọn èèyàn bá mọ̀ ẹ́ sí olóòótọ́, èyí máa jẹ́ kó o ṣe àṣeyọrí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Wọ́n sọ pé àwọn mọ̀ dáadáa pé mo máa ń ṣiṣẹ́ tó jọjú àti pé olóòótọ́ èèyàn ni mi.” —Bill, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà