Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àìṣòótọ́ Gbòde Kan!

Àìṣòótọ́ Gbòde Kan!

Àìṣòótọ́ Gbòde Kan!

Ilé ìṣòwò ńlá kan ni Danny a ti ń ṣiṣẹ́ nílùú Hong Kong. Nígbà tó lọ ṣèbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ kan tí yóò máa kó ọjà wá fún wọn, ó kọminú pé bóyá ni iléeṣẹ́ ọ̀hún á fi lè máa rí ojúlówó ọjà kó fún àwọn. Kó tó kúrò níbẹ̀, máníjà iléeṣẹ́ náà fún Danny ní àpò ìwé kan níbi tí wọ́n ti ń jẹun. Ìgbà tí Danny máa ṣí àpò ìwé náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó dọ́là tí ó tó iye owó oṣù rẹ̀ fún odindi ọdún kan ni Danny bá nínú rẹ̀. Owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ló jẹ́.

● Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Danny yìí kì í ṣe nǹkan tuntun. Kò sí ibi tí àìṣòótọ́ kò sí, tọmọdé tàgbà ló ń hùwà àìṣòótọ́, ó sì máa ń ṣeni ní kàyéfì gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àkọsílẹ̀ kan tó wà ní ilé ẹjọ́ kan fi hàn pé láàárín ọdún 2001 sí 2007, iléeṣẹ́ ńlá kan nílẹ̀ Jámánì san owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún àwọn kan nítorí àtirí iṣẹ́ gbà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtìjú tí ìwà àìṣòótọ́ kó bá àwọn kan tí wọ́n jẹ́ abẹnugan láwùjọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti mú kí àwọn àyípadà díẹ̀ wà, síbẹ̀ ńṣe ni ọ̀rọ̀ náà ń burú sí i kárí ayé. Lọ́dún 2010, nínú ìwádìí kan tí Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ, ìyẹn àjọ tí wọ́n ń pè ní Transparency International, ṣe, wọ́n sọ pé kárí ayé “ńṣe ni ìwà ìbàjẹ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i láti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn.”

Kí nìdí tí ìwà àìṣòótọ́ fi gbalé gbòde bẹ́ẹ̀? Ṣé ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lèèyàn ṣe máa ṣe é? Ṣé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí.