Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Fìfẹ́ Hàn

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Fìfẹ́ Hàn

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Fìfẹ́ Hàn

NÍGBÀ tí obìnrin kan tó fi ìbejì ṣe àkọ́bí béèrè lọ́wọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kan, tó mọ̀ nípa ìtọ́jú ọpọlọ àwọn ọmọdé, pé kó sọ ọ̀nà tó dáa jù tóun lè gbà tọ́ àwọn ọmọ náà dàgbà, ó sọ fún obìnrin náà pé kó “máa gbá wọn mọ́ra dáadáa!” Ọ̀jọ̀gbọ́n náà wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Máa fi ìfẹ́ hàn ní onírúurú ọ̀nà, irú bíi gbígbá wọn mọ́ra àti fífi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, fífi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí wọn, jíjẹ́ olóye, onídùnnú, ọ̀làwọ́, olùdáríjini, kó o sì máa fún wọn ní ìbáwí nígbà tó bá yẹ. A kò sì gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé àwọn ọmọ wa mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn.”

Ó dà bíi pé Tiffany Field tó jẹ́ olùdarí Touch Research Institute ní Yunifásítì tó wà ní Miami, nílùú Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fara mọ́ àbá tí ọ̀jọ̀gbọ́n yìí dá. Obìnrin náà sọ pé: “Fífọwọ́ kan ọmọ ṣe pàtàkì fún ìdàgbà àti ìlera rẹ̀, bí oúnjẹ àti eré ìmárale ti ṣe pàtàkì.”

Ṣé àwọn tó ti dàgbà náà nílò kéèyàn tún máa fìfẹ́ hàn sí wọn? Bẹ́ẹ̀ ni. Nínú ìwádìí kan tí Claude Steiner tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ṣe, ó parí èrò sí pé fífún ẹnì kan ní ìṣírí lọ́rọ̀ àti níṣe ṣe pàtàkì fún un láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn láìka ọjọ́ orí rẹ̀ sí. Nọ́ọ̀sì kan tó ń jẹ́ Laura, tó ń tọ́jú ọ̀pọ̀ àwọn arúgbó sọ pé: “Mo ti rí i pé téèyàn bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn àgbàlagbà, ó máa ń jẹ́ kára tù wọ́n. Tó o bá ń bá wọn lò lọ́nà pẹ̀lẹ́, tó o sì máa ń fọwọ́ kàn wọ́n, wọ́n á fọkàn tán ẹ, wọ́n á sì múra tán láti ṣe ohun tó o bá ní kí wọ́n ṣe. Láfikún sí i, téèyàn bá ń ṣe wọ́n jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ lọ́nà yẹn, ńṣe lèèyàn ń fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún wọn.”

Kò tán síbẹ̀ o, téèyàn bá ń fìfẹ́ hàn síni, àtẹni tí wọ́n fìfẹ́ hàn sí àtẹni tó fìfẹ́ hàn síni ló máa jàǹfààní. Ọ̀rọ̀ náà wá rí bí Jésù Kristi ṣe sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ó tiẹ̀ máa ń ṣàǹfààní gan-an téèyàn bá fìfẹ́ hàn sí àwọn tó ní ìdààmú ọkàn, àwọn tó sorí kọ́ tàbí àwọn tọ́kàn wọn ò balẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ bí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ṣe rí ìrànwọ́ gbà.

Ronú nípa bọ́rọ̀ á ṣe rí lára “ọkùnrin kan tí ó kún fún ẹ̀tẹ̀” tí kò lè gbé láàárín àwọn èèyàn, nígbà tí Jésù Kristi fọwọ́ kàn án tàánú-tàánú. Ó dájú pé ìtùnú ló máa jẹ́ fún un.—Lúùkù 5:12, 13; Mátíù 8:1-3.

Tún ronú nípa bí ara Dáníẹ́lì tó ti darúgbó á ṣe túbọ̀ yá gágá nígbà tí áńgẹ́lì Ọlọ́run fún un lókun nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ atunilára tó sọ fún un àti bó ṣe fọwọ́ kàn án nígbà mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí ańgẹ́lì yẹn ṣe fọwọ́ kan Dáníẹ́lì tó sì sọ̀rọ̀ tó gbé e ró ló jẹ́ kó pa dà lókun lẹ́yìn tó ti rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu.—Dáníẹ́lì 10:9-11, 15, 16, 18, 19.

Ìgbà kan wà táwọn ọ̀rẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà láti Éfésù lọ sí Mílétù láti lọ pàdé rẹ̀. Ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ti sọ fún wọn pé wọ́n lè máà rí òun mọ́. Ó dájú pé ìṣírí gidi ló máa jẹ́ fún Pọ́ọ̀lù nígbà táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í, “rọ̀ mọ́ ọrùn [rẹ̀ tí] wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́”!—Ìṣe 20:36, 37.

A ti rí i báyìí pé Bíbélì àtàwọn ìwádìí táwọn èèyàn ṣe lóde òní fún wa ní ìṣírí láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ máa ń mára túni ó sì ń múni lọ́kàn yọ̀. Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe àwọn ọmọdé nìkan ló yẹ ká máa fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn sí.