Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń wàásù fún obìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ West Bengal lórílẹ̀-èdè Íńdíà

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI September 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọni àti bá a ṣe lè fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa. Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”

Kí ló túmọ̀ sí láti máa rìn nínú òfin Jèhófà? Àpẹẹrẹ àtàtà ni ẹni tó kọ Sáàmù 119 jẹ́ fún wa lónìí.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Tí Ọmọdé Kan Bá Sọ Pé Ká Wọlé

Ohun tó yẹ ká béèrè lọ́wọ́ ọmọdé kan tó bá sọ pé ká wọlé, èyí tó máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí rẹ̀.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”

Onísáàmù náá lo ọ̀rọ̀ àpèjúwe nínú Sáàmù 121 láti sọ bí ààbò Jèhófa ṣe rí.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọlọ́run Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-Tìyanu

Ní Sáàmù 139, Dáfídì yin Jèhófà fún ọ̀nà àgbàyanu tó gbà ṣẹ̀dá wa.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Nǹkan Tó Yẹ Kó O Yẹra fún Tó O Bá Ń Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kí ló yẹ ká yẹra fún tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́kàn?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Jèhófà Tóbi, Ó sì Yẹ fún Ìyìn Gidigidi”

Ní Sáàmù 145, Dáfídì fi hàn pé òun mọyì bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fún Àwọn Tó Bá Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Wa Níṣìírí Láti Wá sí Ìpàdé

Àwọn olùfìfẹ́hàn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń tẹ̀ síwájú gan-an tí wọ́n bá ti ń wá sáwọn ìpàdé.