Àwọn tó wá sí àpéjọ agbègbè kan ní Màláwì kóra jọ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ láti wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI November 2019

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Àwọn ìjíròrò tó dá lórí ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé àtàwọn nǹkan tó ṣèlérí fún wa nípa ọjọ́ iwájú.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ayé Tàbí Àwọn Nǹkan Tó Wà Nínú Ayé

Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ káyé yìí àtàwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ má bàa mú ká jìnnà sí Jèhófà?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Yẹra fún Ẹ̀mí Ayé Tó O Bá Ń Ṣètò Ìgbéyàwó

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ran àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó náà lọ́wọ́, kí wọ́n lè ṣètò ọjọ́ ayọ̀ wọn lọ́nà táá múnú wọn dùn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò sí ní máa dá wọn lẹ́bi?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

A Gbọ́dọ̀ Jà Fitafita Ká Lè Dúró Nínú Òtítọ́

Báwo la ṣe lè “jà fitafita torí ìgbàgbọ́”?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Mo Mọ Àwọn Iṣẹ́ Rẹ”

Jésù mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ, òun ló sì ń darí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Mọ Ohun Tá A Nílò

Kí nìdí táwọn ohun tá a máa ń gbádùn ní àpéjọ agbègbè fi máa ń bọ́ sákòókò gan-an? Kí nìdí tí ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ fi máa ń gbádùn mọ́ni, tó sì máa ń kún fún ẹ̀kọ́ tó ṣeé múlò?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tó Ń Gẹṣin Lọ

Lónìí, à ń rí ohun táwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tí ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ wọn ń fà fún aráyé. Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣàpẹẹrẹ?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹni Tó Ń Fúnni Pẹ̀lú Ìdùnnú

Báwo la ṣe lè fi ọrẹ ti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn lágbègbè wa tàbí kárí ayé?