Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 1-5

Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́ Nígbà Àdánwò

Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́ Nígbà Àdánwò

Ilẹ̀ Úsì ni Jóòbù ń gbé lásìkò tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lóko ẹrú ní Íjíbítì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tọkàntọkàn ló fi sin Jèhófà. Ó ní ìdílé ńlá, ọlọ́rọ̀ ni, ẹnu rẹ̀ sì tólẹ̀ nílùú. Àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí àgbà agbani-nímọ̀ràn àti onídàájọ́ tí kì í ṣe ojúsàájú. Ó lawọ́ sí àwọn aláìní àti àwọn tí kò rí jájẹ. Ọkùnrin oníwà títọ́ ni Jóòbù.

Jóòbù fi hàn kedere pé Jèhófà lẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé òun

1:8-11, 22; 2:2-5

  • Sátánì kíyè sí ìwà títọ́ Jóòbù. Kò jiyàn pé Jóòbù ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń mú kí Jóòbù ṣègbọràn ni ẹ̀sùn tó fi kàn án dá lé

  • Sátánì sọ pé torí ohun tí Jóòbù ń rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà ló ṣe ń sìn ín

  • Jèhófà gba Sátánì láyè láti gbógun ti ọkùnrin olóòótọ́ yẹn kó lè mọ̀ pé ẹ̀sùn èké ló fi kàn án. Gbogbo ohun tí Jóòbù ní pátá ni Sátánì pa run

  • Jóòbù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, àmọ́ Sátánì sọ pé gbogbo èèyàn ò lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Jèhófà

  • Jóòbù ò dẹ́ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni kò dá Ọlọ́run lẹ́bi fún gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i