“Ní Báyìí, Wàá Rí Ohun Tí Màá Ṣe sí Fáráò”
Kó tó di pé Jèhófà mú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí àwọn ará Íjíbítì, tó sì gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, ó jẹ́ káwọn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tí òun máa ṣe. Wọ́n máa rí ọwọ́ agbára Jèhófà lọ́nà tí wọn ò rírú ẹ̀ rí, àwọn ará Íjíbítì sì máa mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Nígbà táwọn ìlérí Jèhófà ṣẹ, ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì túbọ̀ lágbára sí i, ìyẹn sì mú kí wọ́n jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà tí wọ́n tí ń lọ́wọ́ sí tẹ́lẹ̀ ní Íjíbítì.
Báwo ni ìtàn Bíbélì yìí ṣe jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ?