Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tá A Kọ́ fún Mílíọ̀nù Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí

Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tá A Kọ́ fún Mílíọ̀nù Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí

Láàárín ọdún 1999 sí 2015, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ní Central America * àti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Kí mílíọ̀nù kan àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn míì tí wọ́n ń wá sí àwọn ìpàdé wa ní àgbègbè yìí tó lè rí ibi tí wọ́n á ti máa ṣèpàdé, àfi ká kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje (700) sí i.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, kò rọrùn fún àwọn ìjọ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yìí láti kọ́ ibi ìjọsìn. Bí àpẹẹrẹ, inú ilé ni ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ti máa ń ṣe ìpàdé. Kí ló fà á? Ọ̀kan lára ohun tó fà á ni pé, ọ̀pọ̀ ọdún ni òfin ò fàyè gbà á pé kí àwọn onísìn kọ́ ibi tí wọ́n á ti máa jọ́sìn. Àmọ́, lọ́dún 1990 sí 1999, òfin náà yí pa dà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Síbẹ̀, ó sábà máa ń gbà wọ́n tó oṣù mélòó kan kí wọ́n tó kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan parí.

Iṣẹ́ Náà Yára Kánkán

Nígbà tó fi máa di ọdún 1999, iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba túbọ̀ gbòòrò sí i nígbà tí Àwọn Tó Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ètò tuntun kan tó máa jẹ́ kí wọ́n lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn ilẹ̀ tí àwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, títí kan Mẹ́síkò àtàwọn orílẹ̀-èdè méje tó wà ní ilẹ̀ Central America. Láti ọdún 2010, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Mẹ́síkò ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe láwọn àgbègbè náà.

Ìṣòro ńlá ni àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń dojú kọ tí wọ́n bá lọ ṣiṣẹ́ láwọn ilẹ̀ tó wà ní àdádó. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Panama, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí mẹ́ta táwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lò nínú ọkọ̀ ojú omi kí wọ́n tó dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ ṣiṣẹ́. Bákan náà, nílùú Chiapas ní Mẹ́síkò, ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan làwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba fi kó ohun tí wọ́n máa fi kọ́lé dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ lò wọ́n.

Àǹfààní Gbọ̀ngàn Ìjọba Tuntun

Ó máa ń wu àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá pé kí wọ́n rí Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun ládùúgbò wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan láti orílẹ̀-èdè Honduras sọ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí àdúgbò wọn, àwọn kan ti fẹ́ fi ilẹ̀ náà kọ́ ibi táwọn èèyàn á ti máa gbafẹ́ alẹ́. Àmọ́ kò gbà. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bá a pé ó máa wu àwọn láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sórí ilẹ̀ náà, inú ẹ̀ dún, ó sọ pé: “Ìbùkún ńlá mà lèyí o!”

Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, báwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe máa ń ṣiṣẹ́ kára máa ń wú àwọn èèyàn lórí. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Guatemala sọ pé: “Nílẹ̀ wa, ilé ìdáná nìkan làwọn obìnrin ti máa ń ṣiṣẹ́, àṣà tiwa nìyẹn. Àmọ́ iṣẹ́ táwọn ọkùnrin ń ṣe níbí náà làwọn obìnrin ń ṣe. Ẹnu yà mí nígbà tí mo rí i táwọn obìnrin ń to irin, tí wọ́n tún ń rẹ́ ilé. Ó wú mi lórí gan-an!” Níbi tí àwọn aládùúgbò míì tiẹ̀ mọyì iṣẹ́ táwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ń ṣe dé, ṣe ni wọ́n lọ ra oúnjẹ àti ìpápánu fún wọn.

Bí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ṣe máa ń rí tún máa ń wú ọ̀pọ̀ èèyàn lórí. Ní orílẹ̀-èdè Nicaragua, oníṣẹ́ ilé kan sọ fún olórí ìlú kan pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níbẹ̀ dáa gan-an àti pé ojúlówó ohun èlò ni wọ́n fi kọ́ ọ. Ó tiẹ̀ tún sọ pé, kò sírú ilé bẹ́ẹ̀ ní ìlú náà tórí pé àwọn ohun èlò gidi ni wọ́n lò!

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà máa ń dùn gan-an láti ní ibi tó dáa tí wọ́n á ti lè máa jọ́sìn. Wọ́n ti rí i pé ó máa ń wu àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti máa wá sáwọn ìpàdé ìjọ lẹ́yìn tí Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun bá ti dúró. Àwọn ará ní ìjọ kan tó wà ní Mẹ́síkò, tí wọ́n ń ran àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́wọ́ sọ ohun tó múnú wọn dùn, wọ́n sọ pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí àǹfààní tá a ní láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba táá máa fi ìyìn àti ògo fún orúkọ rẹ̀.”

^ ìpínrọ̀ 2 Ìwé atúmọ̀ èdè Merriam-Webster’s Collegiate Dictionary, 11th Edition, sọ pé Central America jẹ́ àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Guatemala, El Salvador, Honduras, Nicaragua, Costa Rica, Panama àti Belize.