Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 92

Ibi Tá À Ń Fi Orúkọ Rẹ Pè

Ibi Tá À Ń Fi Orúkọ Rẹ Pè

(1 Kíróníkà 29:16)

  1. 1. Àǹfààní ńlá lèyí jẹ́ fún wa

    Láti kọ́ ilé yìí fún ọ!

    Gbogbo ohun tá a ní, tìrẹ ni.

    A fi ń buyì fórúkọ rẹ.

    Tọkàntọkàn la ń fi iṣẹ́ wa,

    Okun wa, ohun ìní wa,

    Bọlá fún orúkọ mímọ́ rẹ.

    Ọlọ́run wa, jọ̀ọ́ tẹ́wọ́ gbà á.

    (ÈGBÈ)

    Ilé náà rè é níwájú rẹ,

    Tá ó máa forúkọ rẹ pè.

    A ti yà á sí mímọ́ fún ọ;

    Tìrẹ ni títí láéláé.

  2. 2. Ní báyìí, a gbórúkọ rẹ ga,

    Kógo àtìyìn jẹ́ tìrẹ.

    Kí àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ

    Máa pọ̀ sí i nínú ilé yìí.

    A ó máa jọ́sìn rẹ nínú ‘lé yìí,

    A ó sì máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa.

    Kó lè máa jẹ́rìí fáwọn èèyàn,

    Kó tiṣẹ́ ‘wàásù wa lẹ́yìn.

    (ÈGBÈ)

    Ilé náà rè é níwájú rẹ,

    Tá ó máa forúkọ rẹ pè.

    A ti yà á sí mímọ́ fún ọ;

    Tìrẹ ni títí láéláé.