Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 112

Jèhófà, Ọlọ́run Àlàáfíà

Jèhófà, Ọlọ́run Àlàáfíà

(Fílípì 4:9)

  1. 1. Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́,

    Jọ̀ọ́, fún wa ní àlàáfíà

    Tó o ṣèlérí pó o máa fún wa

    Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.

    Ìgbàgbọ́ tí a ní

    Nínú Jésù Ọmọ rẹ

    Ló mú ká sún mọ́ ọ, ká sì

    Wà lálàáfíà pẹ̀lú rẹ.

  2. 2. Ẹ̀mí rẹ ń ṣèrànwọ́

    Láyé tó ṣókùnkùn yìí.

    Ọ̀rọ̀ rẹ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀,

    Ó ń tọ́ wa, ó ń pa wá mọ́.

    Láìpẹ́, Ìjọba rẹ

    Yóò fòpin sí ‘ṣòro wa.

    Ṣùgbọ́n báyìí, ràn wá lọ́wọ́

    Ká lè máa wà lálàáfíà.

  3. 3. Àwa ìránṣẹ́ rẹ

    Ní ọ̀run àti láyé,

    O fìfẹ́ kó gbogbo wa jọ;

    À ń kọ́wọ́ ti ’Jọba rẹ.

    Láìpẹ́, yóò dé sáyé,

    Yóò sì fòpin sí ogun.

    Àwọn olódodo máa yọ̀,

    Wọn yóò máa gbé lálàáfíà.