Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 102

Ran Àwọn Aláìlera Lọ́wọ́

Ran Àwọn Aláìlera Lọ́wọ́

(Ìṣe 20:35)

  1. 1. Gbogbo wa pátá la ní

    Ibi tá a kù sí.

    Síbẹ̀, Jèhófà ń fìfẹ́

    Ṣèrànwọ́ fún wa.

    Bàbá aláàánú ni;

    Ó nífẹ̀ẹ́ wa púpọ̀.

    Ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jáà;

    Ká máa ṣèrànwọ́.

  2. 2. Lójú tiwa, àwọn kan

    Lè má níṣòro.

    Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn lè

    Má tó bá a ṣe rò.

    Ó yẹ ká gbé wọn ró,

    Ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

    Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà

    Yóò tún ṣèrànwọ́.

  3. 3. Àwọn tó j’áláìlera

    Nílò ìrànwọ́.

    Ká má ṣe dá wọn lẹ́bi,

    Ká mára tù wọ́n.

    Ká máa kíyè sí wọn,

    Ká lè máa gbé wọn ró.

    Tí a bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́,

    A ó rí ‘bùkún gbà.