Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mátíù Orí 5-7

Mátíù Orí 5-7

5 Nígbà tó rí ọ̀pọ̀ èèyàn, ó lọ sórí òkè; lẹ́yìn tó jókòó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 2 Ó wá la ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn, ó sọ pé:

3 “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, a torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn.

4 “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, torí a máa tù wọ́n nínú.

5 “Aláyọ̀ ni àwọn oníwà tútù, b torí wọ́n máa jogún ayé.

6 “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, torí wọ́n máa yó. c

7 “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, torí a máa ṣàánú wọn.

8 “Aláyọ̀ ni àwọn tí ọkàn wọn mọ́, torí wọ́n máa rí Ọlọ́run.

9 “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá àlàáfíà, d torí a máa pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run.

10 “Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn.

11 “Aláyọ̀ ni yín tí àwọn èèyàn bá pẹ̀gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́ yín nítorí mi. 12 Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì dùn gidigidi, torí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run, torí bí wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tó wà ṣáájú yín nìyẹn.

13 “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé, àmọ́ tí iyọ̀ ò bá lágbára mọ́, báwo ló ṣe máa pa dà ní adùn rẹ̀? Kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, àfi ká dà á síta, kí àwọn èèyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.

14 “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tó bá wà lórí òkè ò lè fara sin. 15 Tí àwọn èèyàn bá tan fìtílà, wọn kì í gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀, e orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e sí, á sì tàn sára gbogbo àwọn tó wà nínú ilé. 16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.

17 “Ẹ má rò pé mo wá láti pa Òfin tàbí àwọn Wòlíì run. Mi ò wá láti pa á run, àmọ́ láti mú un ṣẹ. 18 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, tí ọ̀run àti ayé bá tiẹ̀ yára kọjá lọ, lẹ́tà tó kéré jù tàbí ìlà kan lára lẹ́tà kò ní kúrò nínú Òfin títí gbogbo nǹkan fi máa ṣẹlẹ̀. 19 Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá tẹ ọ̀kan nínú àwọn àṣẹ tó kéré jù yìí lójú, tó sì ń kọ́ àwọn míì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, a máa pè é ní ẹni tó kéré jù lọ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń pa á mọ́, tó sì ń fi kọ́ni, a máa pè é ní ẹni ńlá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run. 20 Torí mò ń sọ fún yín pé tí òdodo yín ò bá ju ti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí lọ, ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run.

 21 “Ẹ gbọ́ pé a sọ fún àwọn èèyàn àtijọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pààyàn máa jíhìn fún ilé ẹjọ́.’ 22 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tí kò bá yéé bínú sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún ilé ẹjọ́; ẹnikẹ́ni tó bá sì sọ̀rọ̀ àbùkù tí kò ṣeé gbọ́ sétí sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé, ‘Ìwọ òpònú aláìníláárí!’ Gẹ̀hẹ́nà f oníná ló máa tọ́ sí i.

23 “Tí o bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, 24 fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ. Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.

25 “Tètè yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ lábẹ́ òfin, nígbà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ lójú ọ̀nà ibẹ̀, kí ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ má bàa fi ọ́ lé adájọ́ lọ́wọ́ lọ́nà kan ṣáá, kí adájọ́ sì fi ọ́ lé òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi ọ́ sẹ́wọ̀n. 26 Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ pé, ó dájú pé o ò ní kúrò níbẹ̀ títí wàá fi san ẹyọ owó kékeré tó kù g tí o jẹ.

27 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.’ 28 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá tẹjú mọ́ obìnrin kan lọ́nà tí á fi wù ú láti bá a ṣe ìṣekúṣe, ó ti bá a ṣe àgbèrè nínú ọkàn rẹ̀. 29 Tí ojú ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Torí ó sàn kí o má ní ẹ̀yà ara kan ju kí a ju gbogbo ara rẹ sínú Gẹ̀hẹ́nà. h 30 Bákan náà, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Torí ó sàn kí o má ní ẹ̀yà ara kan ju kí o bá gbogbo ara rẹ nínú Gẹ̀hẹ́nà. i

31 “A tún sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, kó fún un ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’ 32 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tí kò bá jẹ́ torí ìṣekúṣe, j lè mú kí obìnrin náà ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ obìnrin tí wọ́n ti kọ̀ sílẹ̀ ti ṣe àgbèrè.

33 “Ẹ tún gbọ́ pé a sọ fún àwọn èèyàn àtijọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ búra láìṣe é, àmọ́ o gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’ 34 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Má ṣe búra rárá, ì báà jẹ́ ọ̀run lo fi búra, torí ìtẹ́ Ọlọ́run ni; 35 tàbí ayé, torí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ni; tàbí Jerúsálẹ́mù, torí ìlú Ọba ńlá náà ni. 36 O ò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ búra, torí o ò lè sọ irun kan di funfun tàbí dúdú. 37 Ẹ ṣáà ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, torí ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà ni ohun tó bá ju èyí lọ ti wá.

38 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Ojú dípò ojú àti eyín dípò eyín.’ 39 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ má ṣe ta ko ẹni burúkú, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá gbá yín ní etí ọ̀tún, ẹ yí èkejì sí i. 40 Tí ẹnì kan bá fẹ́ mú ọ lọ sí ilé ẹjọ́, kó sì gba aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kó gba aṣọ àwọ̀lékè rẹ pẹ̀lú; 41 tí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ bá sì fipá mú ọ láti ṣiṣẹ́ dé máìlì kan, bá a dé máìlì méjì. 42 Tí ẹnì kan bá ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ, fún un, má sì yíjú kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó fẹ́ yá nǹkan k lọ́wọ́ rẹ.

43 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ 44 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín, 45 kí ẹ lè fi hàn pé ọmọ Baba yín tó wà ní ọ̀run lẹ jẹ́, torí ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo. 46 Torí tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ yín, kí ni èrè yín? Ṣebí ohun tí àwọn agbowó orí ń ṣe náà nìyẹn? 47 Tí ẹ bá sì ń kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo lẹ̀ ń ṣe? Ṣebí ohun tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń ṣe náà nìyẹn? 48 Kí ẹ jẹ́ pípé gẹ́lẹ́, l bí Baba yín ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

6 “Kí ẹ rí i pé ẹ ò ṣe òdodo yín níwájú àwọn èèyàn, torí kí wọ́n lè rí yín; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní rí èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín tó wà ní ọ̀run. 2 Torí náà, tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, a má ṣe fun kàkàkí ṣáájú ara rẹ, bí àwọn alágàbàgebè ṣe ń ṣe nínú àwọn sínágọ́gù àti láwọn ojú ọ̀nà, kí àwọn èèyàn lè kan sáárá sí wọn. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 3 Àmọ́ tí ìwọ bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, 4 kí ìtọrẹ àánú tí o ṣe lè wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.

5 “Bákan náà, tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe bíi ti àwọn alágàbàgebè, torí tí wọ́n bá ń gbàdúrà, wọ́n máa ń fẹ́ dúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní ìkóríta àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba, kí àwọn èèyàn lè rí wọn. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 6 Àmọ́ tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ, lẹ́yìn tí o bá ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san. 7 Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe máa ń ṣe, torí wọ́n rò pé àdúrà àwọn máa gbà torí bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀. 8 Torí náà, ẹ má ṣe bíi tiwọn, torí Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ nílò, kódà kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

9 “Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí:

“‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. b 10 Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run. 11 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí; 12 kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè. 13 Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá c lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’

14 “Torí tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run náà máa dárí jì yín; 15 àmọ́ tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

16 “Tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ má fajú ro mọ́ bíi ti àwọn alágàbàgebè, torí wọ́n máa ń bojú jẹ́ d kí àwọn èèyàn lè rí i pé wọ́n ń gbààwẹ̀. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 17 Àmọ́ tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, fi òróró pa orí rẹ, kí o sì bọ́jú rẹ, 18 kó má bàa hàn sí àwọn èèyàn pé ò ń gbààwẹ̀, Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀ nìkan ni kó hàn sí. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.

19 “Ẹ má to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ayé mọ́, níbi tí òólá ti ń jẹ nǹkan run, tí nǹkan ti ń dípẹtà, tí àwọn olè ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. 20 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá kò ti lè jẹ nǹkan run, tí nǹkan ò ti lè dípẹtà, tí àwọn olè kò ti lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. 21 Torí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.

22 “Ojú ni fìtílà ara. Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, e gbogbo ara rẹ máa mọ́lẹ̀ yòò. f 23 Àmọ́ tí ojú rẹ bá ń ṣe ìlara, g gbogbo ara rẹ máa ṣókùnkùn. Tó bá jẹ́ òkùnkùn ni ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ lóòótọ́, òkùnkùn yẹn mà pọ̀ o!

24 “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì; àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.

25 “Torí náà, mo sọ fún yín pé: Ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí h yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀. Ṣé ẹ̀mí i ò ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ ni, tí ara sì ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? 26 Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni? 27 Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn? 28 Bákan náà, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa ohun tí ẹ máa wọ̀? Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú; j 29 àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí. 30 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 31 Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ wá sọ pé, ‘Kí la máa jẹ?’ tàbí, ‘Kí la máa mu?’ tàbí, ‘Kí la máa wọ̀?’ 32 Torí gbogbo nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè ń wá lójú méjèèjì. Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan yìí.

33 “Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn yìí la sì máa fi kún un fún yín. 34 Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.

7 “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; 2 torí bí ẹ bá ṣe dáni lẹ́jọ́ la ṣe máa dá yín lẹ́jọ́, òṣùwọ̀n tí ẹ sì fi ń díwọ̀n fúnni la máa fi díwọ̀n fún yín. 3 Kí ló wá dé tí ò ń wo pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, àmọ́ tí o ò kíyè sí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ? 4 Àbí báwo lo ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí n bá ọ yọ pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ,’ nígbà tó jẹ́ pé, wò ó! igi ìrólé wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? 5 Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ, ìgbà yẹn lo máa wá ríran kedere láti yọ pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.

6 “Ẹ má ṣe fún àwọn ajá ní ohun tó jẹ́ mímọ́, ẹ má sì sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, kí wọ́n má bàa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kí wọ́n wá yíjú pa dà, kí wọ́n sì fà yín ya.

7 “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín; 8 torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà, gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún. 9 Ní tòótọ́, èwo nínú yín ló jẹ́ pé, tí ọmọ rẹ̀ bá béèrè búrẹ́dì, ó máa fún un ní òkúta? 10 Tó bá sì béèrè ẹja, kò ní fún un ní ejò, àbí ó máa fún un? 11 Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ohun tó dáa ló máa fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!

12 “Torí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn. Ní tòótọ́, ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí nìyí.

13 “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé, torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò, àwọn tó ń gba ibẹ̀ wọlé sì pọ̀; 14 nígbà tó jẹ́ pé, ẹnubodè tó lọ sí ìyè rí tóóró, ọ̀nà ibẹ̀ há, àwọn díẹ̀ ló sì ń rí i.

15 “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tó ń wá sọ́dọ̀ yín nínú àwọ̀ àgùntàn, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n ní inú. 16 Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀. Àwọn èèyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún, wọn kì í sì í kó ọ̀pọ̀tọ́ jọ láti ara òṣùṣú, àbí wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? 17 Bákan náà, gbogbo igi rere máa ń so èso rere, àmọ́ gbogbo igi tó ti jẹrà máa ń so èso tí kò ní láárí. 18 Igi rere ò lè so èso tí kò ní láárí, igi tó ti jẹrà ò sì lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná. 20 Torí náà, ní tòótọ́, èso àwọn èèyàn yẹn lẹ máa fi dá wọn mọ̀.

21 “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run nìkan ló máa wọ̀ ọ́. 22 Ọ̀pọ̀ máa sọ fún mi ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Olúwa, Olúwa, ṣebí a fi orúkọ rẹ sọ tẹ́lẹ̀, a fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì fi orúkọ rẹ ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára?’ 23 Àmọ́, màá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin arúfin!’

24 “Torí náà, gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tó sì ṣe é máa dà bí ọkùnrin kan tó ní òye, tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. 25 Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà, àmọ́ kò wó, torí pé orí àpáta ni ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà. 26 Bákan náà, gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò sì ṣe é máa dà bí òmùgọ̀ ọkùnrin tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. 27 Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà, àmọ́ kò lè dúró, ńṣe ló wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.”

28 Nígbà tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tán, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò náà lẹ́nu, 29 torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ, kò kọ́ wọn bí àwọn akọ̀wé òfin wọn.

a Tàbí “àwọn tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn; àwọn alágbe nípa tẹ̀mí.”

b Tàbí “oníwà pẹ̀lẹ́.”

c Tàbí “torí a máa tẹ́ wọn lọ́rùn.”

d Tàbí “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”

e Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n.”

f Ibi tí wọ́n ti ń sun pàǹtírí lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù. Orúkọ Gíríìkì tí wọ́n ń pe Àfonífojì Hínómù, ó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù àtijọ́. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n ju ẹranko tàbí èèyàn sínú Gẹ̀hẹ́nà kí wọ́n lè jóná láàyè tàbí kí wọ́n lè máa joró. Torí náà, kì í ṣe ibi téèyàn ò lè rí ló ń ṣàpẹẹrẹ, níbi tí ẹ̀mí àwọn èèyàn ti ń joró nínú iná títí láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi Gẹ̀hẹ́nà ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé tàbí ìparun yán-án yán-án.

g Ní Grk., “kúádíránì tó kù.”

h Wo àlàyé ìsàlẹ̀  5:22.

i Wo àlàyé ìsàlẹ̀ 5:22.

j Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà por·neiʹa, tí wọ́n ń lò fún onírúurú ìbálòpọ̀ tí kò bófin mu. Lára ẹ̀ ni àgbèrè, ṣíṣe aṣẹ́wó, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti bíbá ẹranko lòpọ̀.

k Ìyẹn, ẹni tó fẹ́ yá nǹkan láìsan èlé.

l Tàbí “Kí ẹ pé pérépéré.”

a Tàbí “ìtọrẹ fún àwọn aláìní.”

b Tàbí “kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ; kí a ka orúkọ rẹ sí mímọ́.”

c Tàbí “dá wa nídè.”

d Tàbí “wọn kì í túnra ṣe.”

e Tàbí “bá ríran kedere.”

f Tàbí “kún fún ìmọ́lẹ̀.”

g Ní Grk., “bá burú.”

h Tàbí “ọkàn.”

i Tàbí “ọkàn.”

j Tàbí “ṣe òwú.”