ILÉ ÌṢỌ́ November 2012 | Ìbéèrè Wo Lo Máa Fẹ́ Bi Ọlọ́run?

Wo bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá èèyàn sáyé? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tá a bá kú? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìyà máa jẹ èèyàn?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Ká Máa Bi Ọlọ́run Ní Ìbéèrè?

Ibo la ti lè rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè nípa ìgbésí ayé. Ṣé a lè bi Ọlọ́run?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ìbéèrè Kìíní: Ìwọ Ọlọ́run, Kí Nìdí Tó O Fi Dá Mi Sáyé?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé kéèyàn lówó tàbí kó di gbajúmọ̀ ló ṣe pàtàkì jù láyé, àmọ́ àwọn nǹkan míì ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ìbéèrè Kejì: Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Mi Nígbà Tí Mo Bá Kú?

Ẹ̀rù máa ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ́ sí wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n bá kú? Wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?

Bíbélì sọ ní tààràtà pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìjìyà. Kí ló wá dé tí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ń jìyà?

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Báwo ni obìnrin kan tó ti rọ́wọ́ mú nínú ayé àti onítẹ́tẹ́ kan pẹ̀lú ọkùnrin kan táyé ti sú, ṣe rí ayọ̀ àtọkànwá?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Irú gègé àti yíǹkì wo ni wọ́n ń lò nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? Irú àwọn àgọ́ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń pa?

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Yóò Fún Wa Ní Ìjọba Kan Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé?

Kárí ayé láwọn èèyàn ti ń níṣòro. Ṣé ẹnì kan lè ṣàkóso gbogbo ayé kó sì yanjú àwọn ìṣòro náà?

OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Nípa Gbèsè

Kí ni ìdílé le ṣe tí wọ́n bá ti wọko gbèsè?

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

‘Kí Ni Ohun Tí Jèhófà Ń Béèrè Láti Ọ̀dọ̀ Rẹ?’

Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tó ń jọ́sìn òun ṣe? Ṣé èèyàn aláìpé lè tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn?

ÀWỌN ÒǸKÀWÉ WA BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ẹni Tó Bá Lóun Ní Ìgbàgbọ́ Kàn Ń Tan Ara Rẹ̀ Jẹ Ni?

Bíbélì kò sọ pé ká kàn máa gba gbogbo nǹkan gbọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó rọ̀ wá pé ká lo agbára ìmọnúurò wa, ká sì gbé àwọn ẹ̀rí tó wà yẹ̀ wò.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì

Ta ló dá òjò? Kí nìdí tá a fi nílò rẹ̀? Lo ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí láti kọ àwọn ọmọ nípa Ọlọ́run àti àwọn ohun tó dá.

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Olùṣọ́ Àgùntàn

Irú àwọn ẹran wo ní olụ̀ṣọ́ àgùntàn máa ń dà? Kí ni iṣẹ́ rẹ̀ ní nínú?

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù Gbèjà Ẹ̀tọ́ Ẹni Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ̀ Kò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun

Ká nípa ẹjọ́ mánigbàgbé tí Ilẹ̀ Yúróòpù máa máa tẹ̀ lé báyìí.