Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ṣèbẹ̀wò sí Àgbègbè Tí Yìnyín Ti Lọ Salalu

A Ṣèbẹ̀wò sí Àgbègbè Tí Yìnyín Ti Lọ Salalu

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-Èdè Norway

A Ṣèbẹ̀wò sí Àgbègbè Tí Yìnyín Ti Lọ Salalu

NÍ ÀÁRỌ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kan nígbà òtútù, a yọjú lójú fèrèsé láti wo bí ojú ọjọ́ ṣe rí. Inú wa dùn gan-an nígbà tá a rí ojú ọ̀run tó mọ́ roro! A fẹ́ lọ fi ọjọ́ mẹ́ta wàásù ní àgbègbè Finnmarksvidda, ìyẹn lórí òkè pẹrẹsẹ kan ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Norway.

Òtútù máa ń mú gan-an nígbà òtútù lórílẹ̀-èdè Norway, nítorí náà, ọkàn wa kò fí bẹ́ẹ̀ balẹ̀ láti lọ sí apá àríwá tí yìnyín ti lọ salalu. Inú wa dùn pé mẹ́ta lára àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé àgbègbè yẹn la jọ fẹ́ lọ. Wọ́n mọ ohun tá a máa bá níbẹ̀, wọ́n sì ti fún wa ní àmọ̀ràn tó dáa.

Ọ̀nà kò pọ̀ níbẹ̀. Ọkọ̀ orí yìnyín ni èèyàn lè gbé lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé lágbègbè tó jìnnà yìí. A mú aṣọ, oúnjẹ àti epo ọkọ̀ tí a máa lò dání, a sì dì wọ́n sínú ọkọ̀ orí yìnyín náà àti ọpọ́n onírin tí a so mọ́ ọkọ̀ náà. Òkè yìnyín olórí pẹrẹsẹ lọ salalu. Yìnyín máa ń tàn yanran bí dáyámọ́ǹdì nínú oòrùn. Ìrísí ibẹ̀ sì lẹ́wà gan-an ni!

Àgbègbè Finnmarksvidda jẹ́ ibi tí àwọn ẹranko lóríṣiríṣi wà, irú bí ìgalà ilẹ̀ yìnyín, ẹran moose tó rí bí ẹfọ̀n, ológbò igbó, ehoro, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, ẹran wolverine tó jọ gara orí àpáta àti àwọn béárì díẹ̀. Àmọ́ ohun tó múnú wa dùn jù lọ ni pé á máa dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé ní ibi tó jìnnà gan-an yìí. Ó wù wá gan-an láti rí àwọn kan lára àwọn Sami tí wọ́n ń sin ìgalà ilẹ̀ yìnyín tàbí tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nínú àwọn ilé ìgbafẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè.

Ní ìta ilé ìgbafẹ́ àkọ́kọ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè, a rí àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ń ṣeré orí yìnyín pẹ̀lú àwọn ọmọ kíláàsì wọn lágbègbè yẹn. Wọ́n dáwọ́ eré tí wọ́n ń ṣe dúró, wọ́n sì béèrè ohun tí a wá ṣe lágbègbè náà. Inú wa dùn láti ṣàlàyé fún wọn. Bí a ṣe ń fibẹ̀ sílẹ̀, ọ̀kan lára wọn sọ fún wa pé: “Ọlọ́run á wà pẹ̀lú yín o bí ẹ ti ń wàásù!” Bí a ṣe pa dà sórí ọkọ̀ wa, a ré kọjá lórí adágún ńlá kan to ti di yìnyín àti ibi gbalasa kan. Ǹjẹ́ a máa rí ọ̀wọ́ ìgalà ilẹ̀ yìnyín?

Bí a ṣe wakọ̀ dé ilé kékeré kan, ọkùnrin kan fi ọ̀yàyà kí wa. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wá gbé ibẹ̀. Nígbà tó rí i pé ọpọ́n onírin tí a sọ mọ́ ọkọ̀ wa ti bà jẹ́, ó lóun á bá wa tún un ṣe. Ó fara balẹ̀ ṣe é, àwọn èèyàn ibẹ̀ yẹn kì í kánjú rárá. Ìwà ọkùnrin náà mú kí ara tù wá gan-an. Lẹ́yìn tó ti tún ọpọ́n náà ṣe tán, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ a sì fi ohun díẹ̀ hàn án látinú Bíbélì nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Ó fetí sílẹ̀ dáadáa. Ká tó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? pẹ̀lú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó ní, “Ẹ ṣeun gan-an tí ẹ wá sọ́dọ̀ mi.”

Lẹ́yìn tá a ti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn díẹ̀ sí i, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú, a lọ sí ilé kékeré níbi tá a máa sùn sí. Lójijì, a rí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kan. Irun rẹ̀ tó pupa ń tàn yẹ́ẹ́ nínú yìnyín, ìyẹn sì gbé ẹwà rẹ̀ yọ. Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà dúró díẹ̀, ó wò wá tìfura-tìfura, lẹ́yìn náà, ó sì bá tiẹ̀ lọ. Ní báyìí yìnyín ti bẹ̀rẹ̀ sí í já bọ́, èyí sì mú kó ṣòro fún wa láti rí ibi tí à ń lọ. Ẹ wo bi inú wa ti dùn tó nígbà tí a jàjà rí ilé wa! A dá iná sínú ààrò tó ń múlé gbóná, inú ilé náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í móoru. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti rẹ̀ wá lọ́jọ́ yẹn, nítorí pé kòtò àti gegele pọ̀ lójú ọ̀nà tí a gbé ọkọ̀ wa gbà, àmọ́ inú wa dùn gan-an.

Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ ilẹ̀ tún ti mọ́. Ni a bá tún kó ẹrù sínú ọkọ̀ orí yìnyín wa, a gùn ún láti òkè wá sí ìsàlẹ̀, a gba ibi odò já sí ilé ìgbafẹ́ míì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè. A rí ọ̀dọ́kùnrin kan níbẹ̀, a sì fi àwọn ohun tó ṣàǹfààní hàn án látinú Bíbélì. Ó fi inú rere hàn sí wa, ó sì tọ́ka wa sí ibi tó rọrùn tá a lè gbà bọ́ sí ojú ọ̀nà.

Ọjọ́ tí a máa lò kẹ́yìn níbẹ̀ pé. Bí a ṣe wọ ọgbà ìtura tó ń jẹ́ Stabbursdalen National Park, àrímáleèlọ ni ẹwà àyíká ibẹ̀, yìnyín tó bo àwọn òkè tó wà láyìíká náà ń tàn yanran nínu oòrùn. A rí ọ̀wọ́ ìgalà ilẹ̀ yìnyín lọ́ọ̀ọ́kán! Wọ́n rọra ń jẹun, wọ́n ń fi pátákò wọn gbẹ́ yìnyín kúrò lórí ewéko wẹ́ẹ́wẹ̀ẹ̀wẹ́ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń jẹ wọ́n. A rí Sami kan lọ́ọ̀ọ́kán, ó jókòó lórí ọkọ̀ orí yìnyín rẹ̀. Ó rọra ń wo ọ̀wọ́ ìgalà ilẹ̀ yìnyín tó ń bójú tó. Ajá rẹ̀ rọra ń ṣọ́ àwọn ìgalà náà, ó sì mú kí wọ́n wà lójú kan. Ajá náà dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbóòórùn apá ibi tí a wà. Àmọ́ kíákíá ló pa dà sọ́dọ̀ ọ̀wọ́ ìgalà tó ń ṣọ́. A wàásù ìhìn rere fún ẹni tó ń da ọ̀wọ́ ìgalà yìí. Ó hùwà ọmọlúwàbí sí wa, ó sì tẹ́tí gbọ́ wa.

Lójú ọ̀nà, bá a ti ń pa dà bọ̀ wálé, a ń ronú nípa àwọn èèyàn tá a rí nígbà ìrìn àjò wa tí ó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] kìlómítà. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé a kópa nínú dídé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé ní àgbègbè tí yìnyín ti lọ salalu yìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]

© Norway Post