Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àjálù Ṣẹlẹ̀ ní Erékùṣù Solomon Islands

Àjálù Ṣẹlẹ̀ ní Erékùṣù Solomon Islands

Àjálù Ṣẹlẹ̀ ní Erékùṣù Solomon Islands

Ní ọjọ́ Monday, ọjọ́ kejì oṣù kẹrin ọdún 2007, ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé lápá ibi tó pọ̀ ní erékùṣù Solomon Islands. Àwọn erékùṣù tó wà ní ìhà ìlà oòrùn àríwá Ọsirélíà ló para pọ̀ di erékùṣù yìí. Ìmìtìtì ilẹ̀ yìí wọ̀n tó 8.1 lórí ìwọn tí wọ́n fi ń wọn ìmìtìtì ilẹ̀. Láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan, àwọn ìgbì omi bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ lu àwọn erékùṣù tó wà ní Ẹkùn Ìwọ Oòrùn. Wọ́n tiẹ̀ ní àwọn kan nínú wọn ga tó bí ọgbọ̀n ẹsẹ̀ bàtà [tó ga tó òpó iná], ó pa èèyàn méjìléláàádọ́ta, ó sì sọ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà èèyàn di aláìnílélórí.

Ara ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti lágbára jù ni Gizo, ìlú kan tó wà létí omi ní erékùṣù Ghizo táwọn èèyàn tó ń gbébẹ̀ pọ̀ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje. Máìlì méjìndínlọ́gbọ̀n [ìyẹn kìlómítà márùndínláàádọ́ta] péré ni ilú náà wà sí ibi tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀. Ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà níbẹ̀, àwọn ará ìjọ kékeré yìí ń retí pé kó dìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn káwọn lọ ṣe Ìrántí Ikú Jésù tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún ni. (1 Kọ́ríńtì 11:23–26) Bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rẹwà nígbà tí ilẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́ náà ló ṣe rí lọ́jọ́ yìí, tí òkun sì dákẹ́ rọ́rọ́. Àfìgbà tó di ọwọ́ aago mẹ́jọ ku ìṣẹ́jú mọ́kànlélógún àárọ̀ tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mì tìtì.

Ìmìtìtì Ilẹ̀!

Arákùnrin Ron Parkinson, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ àti Arábìnrin Dorothy, ìyàwó rẹ̀ ń gbọ́ oúnjẹ àárọ̀ wọn lọ́wọ́ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dédé ṣẹlẹ̀. Arákùnrin Ron sọ pe: “Ilé wa bẹ̀rẹ̀ sí í mì síwá fì sẹ́yìn bíi igi àgbọn, àmọ́ kò wó. Ariwo yẹn pọ̀ jù. Kọ́ńbọ́ọ̀dù ni o, tigbá-tàwo tìkòkò ọ̀bẹ̀ ni o, tó fi mọ́ dùrù àtàwọn nǹkan míì tó wà nínú ilé, gbogbo rẹ̀ ló dà wó sílẹ̀ẹ́lẹ̀. Ká ní kì í ṣe pé àwa gan-an tiraka ni, a ò bá má ráyè jáde síta. Ìyàwó mi fẹsẹ̀ gún èkúfọ́ ìgò torí kò rójú wọ bàtà.”

Míṣọ́nnárì ni Arákùnrin Tony Shaw àti Arábìnrin Christine ìyàwó rẹ̀, tòsí ibẹ̀ làwọn náà ń gbé, ṣe làwọn náà bẹ́ jáde nígbà tí ìṣẹ́lẹ̀ yẹn ń wáyé. Arábìnrin Christine sọ pé: “Ilẹ̀ mì jìgìjìgì débi pé mo ṣubú yakata tí mi ò sì lè dá dìde. Mò ń wo àwọn ilé tómi ń gbé lọ bí wọ́n ṣe léfòó sórí òkun. Ìgbì ti gbé wọn tìdítìdí. Àwọn èèyàn kan gbé ọkọ̀ sójú omi, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti wá àwọn èèyàn tí kò tíì kú tí wọ́n lè rí yọ nínú omi. Bí ìmìtìtì ilẹ̀ tún ṣe wáyé lẹ́ẹ̀kan sí i nìyẹn. Ọjọ́ márùn-ún gbáko ni ìmìtìtì yẹn fi ń wáyé tẹ̀ léra wọn. Ìpayà rẹ̀ ò jẹ́ kọ́kàn èèyàn balẹ̀!”

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Abẹ́ Òkun Tó Ń Jẹ́ Sùnámì Ló Tẹ̀ Lé E

Erékùṣù Sepo Hite tí Arákùnrin Patson Baea ń gbé ni wọ́n wà tí ìmìtìtì ilẹ̀ fi wáyé, ibi tí wọ́n wà yẹn ò sì ju bíi máìlì mẹ́rin [bíi kìlómítà mẹ́fà] sí ìlú Gizo tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Patson àti ìdílé rẹ̀ nígbà tí àjálù yìí wáyé?

Arákùnrin Patson sọ ohun tójú ẹ̀ rí, ó ní: “Mo sáré lọ bá Naomi ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa mẹ́rin létí odò. Ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn ti gbé wọn ṣubú, àmọ́ wọn ò fara pa. Àwọn ọmọ ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, àwọn kan nínú wọn ń sunkún. Èmi àtìyàwó mi sì ń rẹ̀ wọ́n lẹ́kún pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀.”

“Mo kíyè sí i pé bí òkun ṣe ń bì yìí ò dáa. Ó dájú pé àjálù sùnámì ló ń bọ̀ yìí. Ó ṣeé ṣe kí omi ya wọ erékùṣù wa tí kò tó nǹkan yìí kó sì gbá a lọ. Ìyá mi, Evalyn tó ń gbé ní erékùṣù tó wà nítòsì wa náà wà nínú ewu. Kíá mo ní kí ìyàwó àtàwọn ọmọ mi kó sínú ọkọ ojú omi wa tó ń lo ẹ́ńjìnnì, ká tètè lọ wá bá a ṣe máa yọ màmá mi.

“Kò pẹ́ tá a bọ́ sójú agbami tí ìgbì ńlá kan kọjá lábẹ́ ọkọ ojú omi wa. Bẹ́ẹ̀ ni òkun ń ru gùdù. Nígbà tá a fi máa dé ọ̀dọ̀ màmá mi, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n jìnnìjìnnì, ìbẹ̀rù ò sì jẹ́ kí wọ́n lè wọnú omi. Ìyàwó mi àti Jeremy ọmọkùnrin wa ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógun ló kán ludò tó ń ru gùdù yẹn láti lè gbé màmá mi wá sínú ọkọ ojú omi. Bí wọ́n ṣe wọnú ọkọ̀ ojú omi báyìí, tí mo ṣáná sí ẹ́ńjìnnì rẹ̀, iná piti la bá wọ orí agbami òkun.

“Ní gbogbo àkókò yìí, omi òkun ti lọ sílẹ̀ dé ibi tí kò lọ sílẹ̀ dé rí, kódà à ń rí àwọn òkìtì iyùn abẹ́ omi tó wà káàkiri gbogbo erékùṣù wa. Òjijì ni ìgbì òkun tó lágbára ya wọ erékùṣù méjèèjì. Omi ba ilé tá a kọ́ sétí omi tá à ń gbàlejò sí jẹ́ kọjá àtúnṣe, ṣe ló gbé e tìdítìdí. Kódà, omi ya wọ ilé táwa fúnra wa ń gbé, ó sì ba ọ̀pọ̀ dúkìá wa jẹ́. Nígbà tí òkun padà sáyè rẹ̀, a ṣa àwọn Bíbélì àti ìwé orin nínú ilé wa tómi ti bà jẹ́ a sì forí lé ìlú Gizo.”

Òkú sùn lọ bíi rẹ́rẹ sétí omi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá ló sì ṣòfò dà nù. Apá ìwọ̀ oòrùn erékùṣù Ghizo Island ló fara gbá jù nínú àjálù yìí. Kò dín ní abúlé mẹ́tàlá tí ibú omi tó kún tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gbá lọ!

Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, èèyàn méjìlélógún ló kóra jọ pọ̀ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ṣe Ìrántí Ikú Jésù tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. A dúpẹ́ pé kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kóra jọ yìí tí àjálù ṣèpalára tó pọ̀ fún. Arákùnrin Ron tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Kò sí iná mànámàná, ẹyin láńtà wa sì ti fọ́.” Iná tọ́ọ̀ṣì ni Arákùnrin Shaw fi sọ àsọyé lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Nínú òkùnkùn yẹn náà, a kọrìn ìdúpẹ́ sí Jèhófà, pẹ̀lú ohùn wa tó ń rókè lala.”

Ìrànlọ́wọ́ Dé

Nígbà tí ìròyìn àjálù yìí dé ìlú Honiara, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ò jáfara, kíá ni wọ́n dìde ìránwọ́ fún àwọn tó fara gbá àjálù náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹlifóònù àwọn tó wà níbi tí àjàlú náà ti ṣẹlẹ̀ láti fi béèrè àlàáfíà àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Wọ́n rán àwọn tó ṣeé fọkàn tán pé kí wọ́n lọ wá arábìnrin wa kan tó wà níbi tó jẹ́ àdádó ní erékùṣù Choiseul Island. Wọ́n rí i nígbẹ̀yìngbẹ́yín lálàáfíà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì fowó ránṣẹ́ sí ìlú Gizo pé kí wọ́n lọ ra àwọn ohun kòṣeémáàní ojú ẹsẹ̀ táwọn ará ibẹ̀ nílò.

Àwọn aṣojú tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá dé ìlú Gizo lọ́jọ́ Thursday, ọkọ òfuurufú tó kọ́kọ́ dé síbẹ̀ ni wọ́n bá rìn. Arákùnrin Craig Tucker tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé: “A di ọ̀pọ̀ ẹrù dáni, àwọn ohun kòṣeémáàní tó wúlò fáwọn tí àjálù dé bá la kó sínú àwọn ẹrù ọ̀hún.” Ọkọ̀ òfuururú já ẹrù àwọn kan sílẹ̀ torí pé kò lè gbé gbogbo rẹ̀ tán, a dúpẹ́ pé gbogbo ẹrù tiwa ló débẹ̀ láìdín. Wọ́n wà lára àwọn ẹrù tó kọ́kọ́ wọ ibi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀. Ọkọ̀ ojú omi tún gbé àwọn ohun èlò míì dé ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà.”

Ní gbogbo àkókò yẹn, ṣe ni Arákùnrin Tony Shaw àti Patson Baea àtàwọn ará míì tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti ìlú Gizo, rin ìrìn àjò wákàtí méjì lórí omi láti lè ṣèrànwọ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ní àdádó ní erékùṣù Ranongga. Erékùṣù yìí gùn tó ogún máìlì [ìyẹn kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n] ó sì fẹ̀ tó máìlì márùn-ún [ìyẹn kìlómítà mẹ́jọ]. Agbára ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn ti mú kí erékùṣù yìí fi bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ga ju òkun lọ! Bí omi ṣe dédé ya wọ àwọn ìlú tó wà ní erékùṣù náà ló fa ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun tó ń jẹ́ sùnámì tó wáyé ní erékùṣù náà.

Arákùnrin Tony sọ pé: “Inú àwọn ará ìjọ yẹn dùn púpọ̀ nígbà tí wọ́n rí wa. Wọ́n wà lálàáfíà, koko lara wọn sì le, gbangba ìta ni wọ́n ń gbé torí tí ìmìtìtì míì bá tún máa wáyé. Ọkọ̀ ojú omi wa ni àkọ́kọ́ tó gbé àwọn ohun èlò wá fáwọn èèyàn. Ká tó kúrò níbẹ̀ àwa àtàwọn ará tó wà níbẹ̀ gbàdúrà àtọkànwá láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.”

Arákùnrin Patson sọ pé: “Lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, a padà wá sí erékùṣù Ranongga láti wá kó ẹrù fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀, a sì tún lọ wá ìdílé kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń gbé ní àdádó ní òpin erékùṣù yẹn. Níkẹyìn, a rí Arákùnrin Matthew Itu àtàwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n pàgọ́ sínú igbó. Omijé ayọ̀ ló ń bọ́ lójú wọn nígbà tí wọ́n rí i pé a ò gbàgbé wọn! Ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn ti ba ilé wọn àti ọ̀pọ̀ ilé yòókù lábúlé wọn jẹ́. Àmọ́ ohun tó jẹ wọ́n lógún jù lọ ni bá a ṣe máa rí Bíbélì míì fún ìdílé wọn torí pé Bíbélì wọn ti bá àjálù náà lọ.”

Àwọn Tó Rí Akitiyan Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbóríyìn fún Wa

Àwọn èèyàn ò ṣàì máa kíyè sí ìfẹ́ ará tá a lò lákòókò àjálù yẹn. Arákùnrin Craig Tucker sọ pé: “Oniròyìn kan wà tó ti ń bẹnu àtẹ́ lu ètò ìránwọ́ táwọn èèyàn ń ṣe fáwọn tí àjálù bá. Àmọ́, ó jọ ọ́ lójú nígbà tó rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fún àwọn ará wọn ní oúnjẹ, tapólì àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò láàárín ọjọ́ mélòó kan tí àjálù náà ṣẹlẹ̀.” Arákùnrin Patson fi kún un pé: “Àwọn ará abúlé tó wà ní erékùṣù Ranongga sọ pé inú àwọn dùn sí ètò ìrànwọ́ tiwa àmọ́ wọ́n ń ráhùn pé àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì wọn kò ran àwọn lọ́wọ́.” Ó ká obìnrin kan lára débi tó fi sọ pé, “Ìjọ yín yára láti wá ṣèrànwọ́ gan-an ni!”

Àwọn Ẹlẹ́rìí tún nawọ́ ìrànwọ́ sáwọn aládùúgbò wọn. Arábìnrin Christine Shaw sọ pé: “Nígbà tá a lọ sí ilé ìwòsàn alábọ́dé kan tí wọ́n sáré gbé kalẹ̀ sí ìlú Gizo, a rí tọkọtaya kan tá a pàdé lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àwọn méjèèjì ló fara pa yánnayànna tí jìnnìjìnnì sì bò wọ́n. Jàǹbá yẹn ti gba ọmọ-ọmọ obìnrin yẹn lọ́wọ́ rẹ̀, ọmọ náà sì ti kú sómi. A tètè padà sílé ká lè lọ kó oúnjẹ àti aṣọ wá fún wọn. Wọ́n dúpẹ́ dúpẹ́ fóhun tá a ṣe.”

Ó dájú pé àwọn tí àjálù dé bá nílò ju àwọn ẹrù bí oúnjẹ, aṣọ àtàwọn ohun èlò míì. Ohun tí wọ́n nílò jù ni ìtùnú tí wọ́n lè rí nínú Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan. Arákùnrin Ron sọ pé: “Àwọn olórí ìsìn kan ń sọ pé Ọlọ́run ló ń fìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn yẹn jẹ wọ́n.” Àmọ́ a jẹ́ kí wọ́n rí i látinú Bíbélì pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa láabì tó ń ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ wọn ló dúpẹ́ lọ́wọ́ wa pé a sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Jákọ́bù 1:13. a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà “‘Why?’—Answering the Hardest of Questions,” [tó jíròrò ìdí tí àjálù fi ń ṣẹlẹ̀ gẹ́gé bí ìdáhùn sí ìbéèrè tó le jù fáwọn èèyàn], èyí tó jáde nínú Jí! November 2006 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 3 sí 9. Wọ́n pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dá Jí! yìí ní ìlú Gizo lẹ́yìn àjálù yẹn.

[Àwòrán/Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Choiseul

Ghizo

Gizo

Ranongga

HONIARA

ỌSIRÉLÍÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Arákùnrin Baea àti ìdílé rẹ̀ rèé nínú ọkọ̀ ojú omi wọn tó ń lo ẹ́ńjìnnì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí nìkan ni ilé tí kò wó ní abúlé Lale ní erékùṣù Ranongga Island

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bí ọṣẹ́ tí sùnámì ṣe nílùú Gizo ṣe burú tó rèé