ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ August 2014

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti September 29 sí October 26, 2014 ló wà nínú ẹ̀dá yìí.

Ṣé Ò Ń Rí Oúnjẹ Gbà “Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu”?

Ṣé ó dìgbà tí èèyàn bá ń rí gbogbo ìtẹ̀jáde àti ìsọfúnni tí ẹrú olóòótọ́ ń gbé jáde gbà kó tó lè ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Jèhófà?

Ipa Wo Ni Àwọn Obìnrin Ń Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ?

Kà nípa ohun tí ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì yọrí sí fún ọkùnrin àti obìnrin. Gbé àpẹẹrẹ àwọn obìnrin ìgbàanì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ yẹ̀ wò. Wàá tún mọ̀ nípa bí àwọn Kristẹni obìnrin ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run lónìí.

Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Yè!

Gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló fẹ́ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kà nípa àwọn àbá mélòó kan tó ṣeé mú lò nípa bá a ṣe lè lo Bíbélì àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn.

Àwọn Ọ̀nà Tí Jèhófà Gbà Ń Sún Mọ́ Wa

A gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Kọ́ nípa bí ìràpadà àti Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń fà wá sún mọ́ ara rẹ̀.

Máa Gbọ́ Ohùn Jèhófà Níbikíbi Tó O Bá Wà

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tẹ́tí sí ohùn Jèhófà, ká sì máa bá a sọ̀rọ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣọ́ra kí Sátánì àti àìpé tiwa fúnra wa má ṣe gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi ní gbọ́ ohùn Jèhófà mọ́.

‘Pa Dà Kí O sì Fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Lókun’

Tí arákùnrin kan bá ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nígbà kan rí, àmọ́ tí kò ní àǹfààní yẹn mọ́, ṣé ó ṣì lè pa dà “nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó”?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nígbà tí Jésù sọ pé àwọn tí ó jíǹde “kì í gbéyàwó, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi wọ́n fúnni nínú ìgbéyàwó,” ṣé àjíǹde orí ilẹ̀ ayé ló n sọ?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Eureka” Mú Kí Ọ̀pọ̀ Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́

Àwọn tó wà láwọn abúlé oko, kódà láwọn ibi tí kò sí iná mànàmáná lè wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí kò gùn tó “Photo-Drama of Creation” yìí.