Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Èṣù Wà Lóòótọ́?

Ǹjẹ́ Èṣù Wà Lóòótọ́?

Ǹjẹ́ Èṣù Wà Lóòótọ́?

NÍGBÀKIGBÀ tó o bá gbọ́ orúkọ náà ‘Èṣù,’ kí ló máa ń wá sí ọ lọ́kàn? Ṣé ẹnì kan tó ń tanni láti hùwà ibi ni àbí ohunkóhun tó bá ṣáà ti jẹ́ ibi ni Èṣù? Ǹjẹ́ ó yẹ ká bẹ̀rù Èṣù, tàbí ńṣe ni ká kàn gbà pé ẹ̀tàn tàbí ìtàn àlọ́ lásán-làsàn làwọn èèyàn gbà gbọ́ tí wọ́n fi ń sọ pé Èṣù wà? Ṣé kinní kan tí kì í ṣe ohun ẹlẹ́mìí àmọ́ tó lè pa nǹkan run ni Èṣù? Àbí ìwà ibi tí ń bẹ ní inú èèyàn tiẹ̀ ni Èṣù bí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn òde òní ṣe wí?

Èrò àwọn èèyàn ò ṣọ̀kan nípa ẹni tí Èṣù jẹ́, ìyẹn ò sì yani lẹ́nu. Ó máa ń ṣòro láti mọ ẹni tó mọ bá a ṣe ń díbọ́n láti fi tanni jẹ, àgàgà tónítọ̀hún bá tún ń fi agọ̀ bojú! Irú ẹni yẹn ni Bíbélì sọ pé Èṣù jẹ́. Bíbélì pè é ní Sátánì, ó sì sọ pé: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14) Ẹni ibi ni Èṣù o, àmọ́ ó sábà máa ń ṣe bí ẹni rere kó lè tanni jẹ. Tí Èṣù bá sì lè rọ́gbọ́n dá káwọn èèyàn lè gbà pé òun ò sí rárá, ìyẹn gan-an ló máa jẹ́ kó tètè rí wọn tàn jẹ.

Ta wá ni Èṣù yìí nígbà náà? Ìgbà wo ló di pé ó wà, ibo ló sì ti wá? Ipa wo ló ń sà lórí àwọn èèyàn lóde òní? Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe tí ò fi ní lágbára lórí wa? A lè rí ìtàn Èṣù látòkèdélẹ̀ nínú Bíbélì, Bíbélì sì dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí lọ́nà tó tọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ó máa ń ṣòro gan-an láti dá ẹni tó ń fi agọ̀ bojú mọ̀!