Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Tó Ń gbé Ìgbàgbọ́ Ró Tó Sì Ń Fúnni Ní Ìgboyà—Ìtàn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine

Ìtàn Tó Ń gbé Ìgbàgbọ́ Ró Tó Sì Ń Fúnni Ní Ìgboyà—Ìtàn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine

Ìtàn Tó Ń gbé Ìgbàgbọ́ Ró Tó Sì Ń Fúnni Ní Ìgboyà—Ìtàn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine

BÍ ÀWỌN èèyàn ṣe ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe é sí àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní. (Mátíù 10:22; Jòhánù 15:20) Kì í ṣe ibi púpọ̀ ni inúnibíni ti wà fún ìgbà pípẹ́ tó sì lágbára gan-an bíi ti Ukraine, níbi tí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ti wà lábẹ́ ìfòfindè fún ọdún méjìléláàádọ́ta gbáko.

Ìwé 2002 Yearbook of Jehovah’s Witnesses sọ ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè yẹn. Ó jẹ́ ìtàn tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró, tí ń fúnni ní ìgboyà àti okun lójú ìpọ́njú líle koko. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì táwọn èèyàn kọ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wa ní Ukraine nìwọ̀nyí:

“Mo ti ka ìwé 2002 Yearbook tán. Mo sọkún nígbà tí mò ń kà ìtàn nípa ìgbòkègbodò yín ní Ukraine. Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ bí mo ṣe rí ìṣírí gbà tó látinú àpẹẹrẹ ìtara yín àti ìgbàgbọ́ lílágbára tẹ́ ẹ ní. Ó jẹ́ ohun àmúyangàn fún mi pé mo wà nínú ìdílé tẹ̀mí kan náà tẹ́ ẹ wà. Gbogbo ọkàn ni mo fi sọ pe ẹ ṣe gan-an ni o!”—Andrée, ilẹ̀ Faransé.

“Ọ̀nà ọpẹ́ mi pọ̀, mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ ẹ̀yin àti Jèhófà, nítorí ìwé 2002 Yearbook náà. Ńṣe ni omi ń ṣàn lójú mi bi mo ṣe ń ka ọ̀pọ̀ ìrírí àwọn arákùnrin tí wọ́n lo àwọn ọdún tó wúlò jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àti láwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ìgboyà wọn wú mi lórí gan-an ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n rèé tí mo ti di Ẹlẹ́rìí, síbẹ̀ mo ṣì rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyẹn. Wọ́n fún ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà, Baba wa ọ̀run lókun gan-an.”—Vera, Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí.

“Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi ń kọ ìwé yìí nítorí àpẹẹrẹ rere tẹ́ ẹ fi lélẹ̀ nínú jíjẹ́ onífaradà àti olóòótọ́ láàárín gbogbo àwọn ọdún táwọn èèyàn fi ṣàtakò sí yín yẹn. Ìgbọ́kànlé kíkún tẹ́ ẹ ní nínú Jèhófà àti bẹ́ ẹ ṣe pinnu láti dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ mú káwọn èèyàn bọlá fún yín gan-an ni. Láfikún sí i, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́ ẹ ní nígbà àdánwò túbọ̀ jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà kì í fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí àpẹẹrẹ rere tẹ́ ẹ fi lélẹ̀ nínú jíjẹ́ onígboyà, adúróṣinṣin, tẹ́ ẹ sì ní ìfaradà, àwa náà lè túbọ̀ fara da àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá a ní.”— Tuteirihia, ilẹ̀ French Polynesia.

“Lẹ́yìn tí mo ka ìwé Yearbook náà tán, mo ní láti kọ̀wé sí yín. Gbogbo ìrírí tí ń fúnni níṣìírí tí mo kà níbẹ̀ ló wọ̀ mi lákínyẹmí ara. Mo lè fi yangàn pé mo wà nínú irú ètò àjọ tó dúró ṣinṣin tó sì wà níṣọ̀kan bẹ́ẹ̀, èyí tí Baba onífẹ̀ẹ́ tó jẹ adúrótini, tó máa ń fúnni lókun lákòókò tó yẹ, ń darí. Ó bà mí nínú jẹ́ gan-an pé ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ onígboyà àti onítara ló fojú winá ohun tó burú tó yẹn tí wọ́n tiẹ̀ tún pàdánù ẹ̀mí wọn pàápàá. Àmọ́, ó tún múnú mi dùn, nítorí pé ìgboyà àti ìtara wọn ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mọ Baba wa onífẹ̀ẹ́.”—Colette, Netherlands.

“Ó di dandan kí èmi àti ìyàwó mi kọ̀wé sí yín láti sọ fún yín pé orí wa wú gan-an nígbà tá a ka ìtàn nípa Ukraine nínú Yearbook. Ẹ̀yin arákùnrin tòótọ́ wọ̀nyí ti fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ nípa ìfaradà tẹ́ ẹ ní lábẹ́ inúnibíni tó le koko tí kò sì tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀ yẹn. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ inú Òwe 27:11, ẹ ò rí i pé inú Jèhófà ti ní láti dùn gan-an láti rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin olóòótọ́ láti Ukraine ló pa ìwà títọ́ wọn mọ́ láìfi gbogbo iṣẹ́ ibi Èṣù pè.”—Alan, Ọsirélíà.

“Omi bọ́ lójú mi nígbà tí mo ka ìtàn nípa àwọn arákùnrin tó wà ní Ukraine. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n fara dà, irú bí ọ̀pọ̀ ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ìdálóró, ìnilára, àti yíya ìdílé nípa. Mo fẹ́ sọ fún gbogbo àwọn arákùnrin tó ṣì ń sìn nínú ìjọ yín pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn mo sì bọ̀wọ̀ fún wọn gan-an. Ìgboyà àti ìdúróṣinṣin wọn múnú mi dùn gan-an. Mo mọ orísun agbára wọn, ẹ̀mí Jèhófà ni. Jèhófà sún mọ́ wa, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́.”— Sergei, Rọ́ṣíà.

“Mo ka ìwé 2002 Yearbook, mo sì bú sẹ́kún. Ọ̀pọ̀ arábìnrin àtàwọn arákùnrin nínú ìjọ wa ló ń sọ̀rọ̀ nípa yín. Ẹ ṣeyebíye gan-an lójú wọn. Inú mi mà dùn o, pé mo wa lára irú ìdílé ńlá tẹ̀mí bẹ́ẹ̀.”—Yeunhee, South Korea.

“Àkọsílẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ yín, ìfaradà yín, àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tẹ́ ẹ ní fún Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ wú mi lórí gan-an. Nígbà mìíràn, a kì í rántí pé ó yẹ ká mọrírì òmìnira tá a ní àti ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tiyín ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ yín ti ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run wa, òun yóò fún wa ní okun láti kojú gbogbo onírúurú àdánwò tó bá dìde.”—Paulo, Brazil.

“Mo láǹfààní láti ka ìrírí yín nínú ìwé 2002 Yearbook. Wọ́n wọ̀ mi lára gan-an, àgàgà ìrírí amúnikáàánú ti Arábìnrin Lydia Kurdas. Ọkàn mi fà mọ́ arábìnrin yìí gan-an ni.”—Nidia, Costa Rica.

“Òní gan-an ni mo ka ìwé 2002 Yearbook tan. Bí mo ṣe ń kà á ni ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà túbọ̀ ń lágbára sí i. Ohun kan tí mi ò ní gbàgbé ni ìròyìn nípa ìgbà tí wọ́n ǹ tán iyèméjì kálẹ̀ nípa àwọn tó ń mú ipò iwájú. Ó kọ́ mi láti má ṣe ṣiyè méjì láé nípa àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú. Ẹ ṣe gan-an ni o! Oúnjẹ tẹ̀mí yìí ń fún ìgbàgbọ́ lókun gan-an, ó sì múra wa sílẹ̀ de ìgbà tá a bá máa dán ìgbàgbọ́ wa wò.”—Leticia, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“A dúpẹ́ gan-an fún ìwé Yearbook títayọ lọ́lá yìí. Ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀pọ̀ akéde máa kà nípa ìgbòkègbodò àwọn arákùnrin wa ní Ukraine nìyí. Ó fún àwọn ará níbi lókun gan-an ni. Ọ̀pọ̀ ará ló ti mú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn wọn pọ̀ sí i, àgàgà àwọn ọ̀dọ́. Ọ̀pọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Gbogbo wa pátá ní ìtàn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó sìn Jèhófà lákòókò ìfòfindè náà fún níṣìírí.”—Ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ìjọ kan, Ukraine.

Láìsí àní-àní, ìṣòtítọ́ àwọn arákùnrin wa nílẹ̀ Ukraine ti jẹ́ orísun ìṣírí fáwọn èèyàn Jèhófà kárí ayé. Ká sòótọ́, kíka àwọn ìtàn amọ́kànyọ̀ tó máa ń wà nínú ìwé Yearbook lọ́dọọdún jẹ́ ọ̀nà tó dára láti fún ìgbàgbọ́ àti ìfaradà wa lókun láwọn àkókò mánigbàgbé tá a wà yìí.—Hébérù 12:1.