Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìṣòro Aráyé Lè Dópin Láé?

Ǹjẹ́ Ìṣòro Aráyé Lè Dópin Láé?

Ǹjẹ́ Ìṣòro Aráyé Lè Dópin Láé?

“ÌDÁMẸ́RIN àwọn olùgbé ayé ló wà nínú ipò òṣì paraku, àwọn tó dín díẹ̀ ní bílíọ̀nù kan ààbọ̀ ni owó tó ń wọlé fún wọn lójúmọ́ kò tó dọ́là kan, bílíọ̀nù kan ni ò mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà, àwọn tó dín díẹ̀ ní bílíọ̀nù kan ààbọ̀ ni kì í rí omi tó dára mu, bílíọ̀nù kan ni kì í sì í rí oúnjẹ òòjọ́ jẹ.” Ohun tí ìròyìn kan láti Ireland sọ nípa báyé ṣe rí nìyẹn.

Ẹ ò rí i pé ìròyìn tí ń bani nínú jẹ́ gbáà lèyí nípa bí ẹ̀dá ènìyàn ò ṣe rí ojútùú pípẹ́ títí sáwọn ìṣòro ayé! Àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn túbọ̀ ń bani nínú jẹ́ gan-an nígbà tá a bá rí i pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn tí ìròyìn yẹn sọ̀rọ̀ nípa wọn ló jẹ́ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tí wọn ò ní aláfẹ̀yìntì. Ǹjẹ́ kò bani lọ́kàn jẹ́ gan-an pé lákòókò tá a wà yìí pàápàá, ìyẹn ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, ńṣe ni “iye àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀tọ́ wọn dù lójoojúmọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i débi pé wọn ò lóǹkà mọ́”?—The State of the World’s Children 2000.

“Ayé Tuntun Kan Láàárín Ìran Kan Ṣoṣo”

Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ti mú un dáni lójú pé “a lè mú àròdùn tí ìyà wọ̀nyí . . . ti fà fún ọ̀pọ̀ èèyàn jákèjádò ayé kúrò.” Àjọ yìí sọ pé ipò búburú tí ọ̀kẹ́ àìmọye tí nǹkan ò ṣẹnuure fún wọ̀nyí ń bá yí nísinsìnyí jẹ́ “èyí tó ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, tó sì ṣeé yí padà.” Àní, àjọ yìí ti nawọ́ ìpè sí “gbogbo èèyàn láti máa lépa àtirí ayé tuntun kan láàárín ìran kan ṣoṣo.” Ìrètí àjọ yìí ni pé yóò jẹ́ ayé kan tí gbogbo èèyàn yóò ti “bọ́ lọ́wọ́ ipò òṣì àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, tí wọn óò bọ́ lọ́wọ́ ìwà ipá àti àìsàn.”

Ohun tó ń fún àwọn tó ní irú èrò bẹ́ẹ̀ níṣìírí ni pé lákòókò tá a wà yìí pàápàá, àwọn èèyàn tó bìkítà ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti wá nǹkan ṣe sí àbájáde búburú tí “ìforígbárí àti yánpọnyánrin tó dà bí ohun tí kò lè dópin” ń mú wá. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún síbí ni Àjọ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ọmọdé Látàrí Ìjàǹbá Tó Ṣẹlẹ̀ ní Chernobyl “ti ń ṣèrànwọ́ láti dín ìyà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọdé tó ní àrùn jẹjẹrẹ nítorí èròjà olóró tó fọ́n káàkiri kù.” (The Irish Examiner, April 4, 2000) Kò sí àní-àní pé àwọn elétò ìfẹ́dàáfẹ́re, àti ńlá àti kékeré wọn, ń nípa tó lágbára gan-an lórí ìgbésí ayé àìlóǹkà àwọn tí ogun àti ìjábá ti hàn léèmọ̀.

Síbẹ̀ àwọn tó ń kópa nínú irú ètò ìfẹ́dàáfẹ́re bẹ́ẹ̀ mọ bí nǹkan ṣe rí ní ti gidi. Wọ́n mọ̀ pé àwọn ìṣòro táwọn ń dojú kọ “túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì ń gbilẹ̀ sí i ju bó ṣe rí ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá péré sí àkókò yìí.” David Begg, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Ètò àánú náà, Concern, ti ilẹ̀ Ireland, sọ pé “àwọn òṣìṣẹ́, àwọn alátìlẹyìn àtàwọn tó ń kẹ́rù wá ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà” nígbà ìkún omi tó wáyé nílẹ̀ Mòsáńbíìkì. Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́, àwa nìkan ò lè yanjú ọṣẹ́ tí irú ìjábá bẹ́ẹ̀ ń ṣe.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìsapá àwọn elétò ìfẹ́dàáfẹ́re nílẹ̀ Áfíríkà, ó gbà ní tòótọ́ pé: “Ìrètí díẹ̀díẹ̀ tó wà kò yàtọ̀ sí iná àbẹ́là tó ń kú lọ.” Ọ̀pọ̀ ló ronú pé ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn jẹ́ ká mọ bípò nǹkan ṣe rí gan-an jákèjádò ayé.

Ǹjẹ́ a lè fi tọkàntọkàn máa retí àtirí “ayé tuntun kan láàárín ìran kan ṣoṣo”? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsapá àwọn elétò ìfẹ́dàáfẹ́re dáa gan-an ni, ó dájú pé ó bọ́gbọ́n mu láti ronú nípa ìrètí mìíràn fún ayé tuntun òdodo àti alálàáfíà. Bíbélì tọ́ka sí ìrètí yẹn, bí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣe sọ ọ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ojú ìwé 3, àwọn ọmọ: UN/DPI Fọ́tò tí James Bu yà