Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

Nípa Àjọṣe Àwọn Èèyàn

Nípa Àjọṣe Àwọn Èèyàn

Tó o bá fẹ́ ìmọ̀ràn lórí àjọṣe ìwọ àtàwọn míì, ṣé inú Bíbélì lo máa kọ́kọ́ wò, àbí òun lo máa wò gbẹ̀yìn? Wo bí àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ti wà nínú Bíbélì tipẹ́tipẹ́ ṣe bá ohun táwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí mu.

Íńdíà

Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 2014, ìdá mẹ́ta nínú márùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún [18] sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] gbà pé kí àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó máa bá ara wọn sùn “kì í ṣe nǹkan bàbàrà mọ́ nílẹ̀ Íńdíà.” Dókítà kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Mumbai sọ nínú ìwé ìròyìn Hindustan Times pé lójú òun, “ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ń fẹ́ ara wọn sọ́nà kò ní in lọ́kàn rárá láti bá ara wọn ṣe ìgbéyàwó. Wọ́n kàn ń wá ẹni tí wọ́n á jọ máa gbé ara wọn sùn ni. Wọn ò gbà pé ó pọn dandan káwọn fẹ́ ara wọn níṣu-lọ́kà.”

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ: Àwọn wo ló sábà máa ń kó àrùn ìbálòpọ̀, tó sì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí ìbálòpọ̀, ṣé àwọn tó ti ṣègbéyàwó ni àbí àwọn tí kò ṣègbéyàwó tó kàn ń bá ara wọn sùn?—1 Kọ́ríńtì 6:18.

Denmark

Téèyàn bá ń jiyàn lóòrèkóòrè pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀, ó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀, ìyẹn sì lè fa ikú àìtọ́jọ́. Àwọn olùṣèwádìí ní yunifásítì Copenhagen fi ọdún mọ́kànlá ṣọ́ àwọn èèyàn tí o tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùndínlógójì [35] sí àádọ́ta [50] ọdún. Ìwádìí náà fi hàn pé àwọn tó sábà máa ń ṣawuyewuye pẹ̀lú àwọn tó sún mọ́ wọn ṣeé ṣe kó kú láìtọ́jọ́ ju àwọn tí kì í sábà ṣawuyewuye. Ẹni tó jẹ́ olùdarí ìwádìí náà wá sọ pé lára ohun tó lè mú kéèyàn pẹ́ láyé ni kéèyàn má ṣe gbé àníyàn sọ́kàn, kó sì máa ń ṣàkóso ara rẹ̀ tí awuyewuye bá ṣẹlẹ̀.

BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.”—Òwe 17:27.

Amẹ́ríkà

Wọ́n ṣe ìwádìí kan ní ìpínlẹ̀ Louisiana. Ìwádìí náà dá lórí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [564] tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó. Ìwádìí náà fi hàn pé tí àwọn tó ń fẹ́ ara wọn sọ́nà bá fi ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì tún fẹ́ ara wọn pa dà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n pínyà láàárín ọdún márùn-ún lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn. Wọ́n tún lè máa bá ara wọn jà lọ́pọ̀ ìgbà, kí ìgbéyàwó wọn má sì tẹ́ wọn lọ́rùn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀ [nínú ìgbéyàwó], kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:6.