Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ILÉ ÌṢỌ́ No. 1 2022 | Bá A Ṣe Lè Borí Ìkórìíra

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kórìíra àwọn ẹlòmíì. Èyí máa ń mú kí wọ́n ka àwọn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ, kí wọ́n máa fìyà jẹ àwọn míì, kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn tàbí kí wọ́n máa ṣe oríṣiríṣi nǹkan míì tó burú gan-an sí wọn. Báwo la ṣe lè borí ìkórìíra? Àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé yìí máa jẹ́ ká rí bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe lè mú ká borí ìkórìíra. Wàá tún rí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn ò ní máa kórìíra ara wọn mọ́.

 

A Lè Borí Ìkórìíra!

Kí ni ìkórìíra? Àwọn ọ̀nà wo làwọn èèyàn máa ń gbà fi hàn pé wọ́n kórìíra àwọn míì?

Kí Nìdí Tí Ìkórìíra Fi Pọ̀ Láyé?

Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó ń fa ìkórìíra, ìdí táwọn èèyàn fi lẹ́mìí ìkórìíra àti ìdí tí ìkórìíra fi ń tàn kálẹ̀.

Ohun Tó Lè Fòpin Sí Ìkórìíra

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n dẹni tí kò lẹ́mìí ìkórìíra mọ́.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

1 | Yẹra fún Ojúsàájú

Ó lè borí èrò tí ò dáa tó o ní sáwọn èèyàn tó o bá fara wé Ọlọ́run tí kì í ṣe ojúsàájú.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

2 | Má Ṣe Gbẹ̀san

O lè borí ìkórìíra kó o má sì máa gbẹ̀san tó o bá gbà pé Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìrẹ́jẹ láìpẹ́.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

3 | Mú Ìkórìíra Kúrò Lọ́kàn Rẹ

Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú ìkórìíra kúrò lọ́kàn rẹ.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

4 | Ọlọ́run Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìkórìíra

Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní àwọn ìwà tó jẹ́ òdìkejì ìkórìíra.

Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ò Ní Sí Ìkórìíra Mọ́!

Báwo ni ìkórìíra ṣe máa dópin títí láé?

Ibi Gbogbo Ni Ìkórìíra Wà

Báwo lo ṣe lè borí ìkórìíra? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń borí ìkórìíra kárí ayé.