ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ August 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti September 30 sí October 27, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

“A Kò Juwọ́ Sílẹ̀”!

Báwo ni ìrètí ọjọ́ iwájú ṣe lè mú káwa náà túbọ̀ pinnu pé a ò ní juwọ́ sílẹ̀?

Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Máa Pọ̀ Sí I

Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Fílípì máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè túbọ̀ fìfẹ́ hàn sáwọn ará kódà nígbà tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀.

“Àwọn Tó Ń Fetí Sí Ọ” Máa Rí Ìgbàlà

Kí la lè ṣe táá mú kí àwọn mọ̀lẹ́bí wa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?

Bó O Ṣe Lè Láyọ̀ Tí Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Bá Yí Pa Dà

Kò rọrùn rárá fún ọ̀pọ̀ láti fi iṣẹ́ tí wọ́n gbádùn gan-an sílẹ̀. Kí lá jẹ́ kó rọrùn fún wọn nínú ipò tuntun tí wọ́n bára wọn?

Ìgbàgbọ́—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára

Ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ ká lágbára gan-an. Tá a bá ní ìgbàgbọ́, àá lè borí àwọn ìṣòro tó dà bí òkè.

Jòhánù Arinibọmi—Àpẹẹrẹ Ẹnì Kan Tó Láyọ̀ Láìka Ìyípadà Tó Dé Bá A

Báwo làwa náà ṣe lè máa láyọ̀ tí nǹkan bá tiẹ̀ yí pa dà bìrí fún wa?