ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ May 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti July 1 sí August 4, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ìfẹ́ àti Ìdájọ́ Òdodo Nínú Ìjọ Kristẹni

Kí ni òfin Kristi, báwo ló sì ṣe gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ?

Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí, Kó O sì Máa Ṣèdájọ́ Òdodo

Báwo làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, báwo sì làwọn alàgbà ṣe lè dáàbò bo àwọn ará nínú ìjọ?

Bá A Ṣe Lè Pèsè Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n Bá Lò Pọ̀ Nígbà Tí Wọ́n Wà Lọ́mọdé

Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn alàgbà àtàwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe lè pèsè ìtùnú fún àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé?

Má Ṣe Jẹ́ Kí “Ọgbọ́n Ayé Yìí” Nípa Lórí Rẹ

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kò sí ẹlòmí ì tá a lè gbára lé fún ìtọ́sọ́nà bí kò ṣe Jèhófà? Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa ro ara wa ju bó ti yẹ lọ?

Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I!

Báwo la ṣe lè jàǹfààní ní kíkún tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?