ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ April 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti June 3 sí 30, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?

Báwo la ṣe lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kí ayọ̀ wa sì túbọ̀ pọ̀ sí i?

Fara Wé Jésù Kó O Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Ohun mẹ́ta kan wà tí Jésù ṣe táá jẹ́ káwa náà ní ìbàlẹ̀ ọkàn bá a tiẹ̀ ń kojú ìṣòro.

Rọ̀ Mọ́ Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ipò Táwọn Òkú Wà

Kí la lè ṣe tá ò fi ní lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá Bíbélì mu?

Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Kó O Lè Borí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù

Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tá ò fi ní kó sọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Rí “Péálì Kan Tó Níye Lórí Gan-An”

Kà nípa ohun tó mú kí Winston àti Pamela Payne láti Ọsirélíà gbádùn ìgbésí ayé wọn.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo làwọn èèyàn nígbà àtijọ́ ṣe máa ń ṣètò láti bá ọkọ̀ ojú omi rìn?