Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àpárá Ṣe Lè Ran Aláìsàn Lọ́wọ́

Bí Àpárá Ṣe Lè Ran Aláìsàn Lọ́wọ́

Bí Àpárá Ṣe Lè Ran Aláìsàn Lọ́wọ́

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ

ỌLỌ́YÀYÀ èèyàn ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Conchi, ọjọ́ orí ẹ̀ á wà láàárín ogójì sí ọgọ́ta ọdún, ó sì ti tó ọdún méje tí àìsàn jẹjẹrẹ ti ń bá a fínra. Látìgbà tí wọ́n ti kọ́kọ́ sọ fún un nílé ìwòsàn pé ó lárùn jẹjẹrẹ ọmú, ẹ̀ẹ̀méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ fún un kí kókó burúkú tó ń wú yẹn má bàa tóbi jù. Ọgbọ́n wo ló ń dá tí ìbànújẹ́ ò fi dorí rẹ̀ kodò?

Ó sọ pé: “Ní gbogbo ìgbà táwọn dókítà bá sọ fún mi pé mo lárùn jẹjẹrẹ, bí ẹkún bá ń gbọ̀n mí nítorí ìròyìn burúkú náà, màá rí i pé mo sunkún náà tẹ́rùn. Lẹ́yìn náà, màá máa bá ìgbésí ayé mi lọ, màá sì máa ṣe àwọn nǹkan tó máa ń wù mí ṣe, irú bíi kíkọ́ èdè Chinese, lílọ sí àpéjọ Kristẹni, àti lílo àkókò ìsinmi lọ́dọ̀ àwọn ẹbí àtará. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń rántí ìbéèrè Jésù yẹn pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?”—Mátíù 6:27.

Conchi fi kún un pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń gbìyànjú láti máa dápàárá. Mo máa ń bá àwọn dókítà ṣàwàdà, mo máa ń wo fíìmù tá á pa mí lẹ́rìn-ín, pabanbarì ibẹ̀ ni pé mi ò jìnnà sí tẹbí tará mi. Àgbàyanu oògùn afúnnilókun ni tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ lè jọ máa rẹ́rìn-ín. Lọ́jọ́ kan, nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi, àwọn kan lára ọ̀rẹ́ àti ẹbí sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀rín kan tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn fún mi. Mo rẹ́rìn-ín débi pé nígbà tí mo fẹ́ wọnú yàrá tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ abẹ fún mi, ara mi balẹ̀ dáadáa.”

Conchi nìkan kọ́ ló mọ̀ pé kéèyàn máa dápàárá àti níní èrò tó dáa lè ranni lọ́wọ́ nígbà tára ò bá yá dáadáa. Àwọn dókítà òde òní gan-an ti bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ṣíṣàwàdà ṣe pàtàkì téèyàn bá fẹ́ dín ìrora tí àìsàn ń fà kù.

Àpárá Ń Fúnni Lókun Ó sì Ń Fọkàn Ẹni Balẹ̀

Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe tuntun rárá. Ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ọkàn tó láyọ̀ jẹ́ oògùn alágbára.” (Òwe 17:22, The Jerusalem Bible) Ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó jẹ́ òǹkọ̀wé, tó gbé ayé láàárín ọdún 1562 sí 1635, Lope de Vega, sọ bákan náà pé: “Tá a bá lè máa dápàárá dáadáa, mo rò pé ara wa ì bá máa le jù báyìí lọ.” Ṣùgbọ́n nínú ayé tí ìṣòrò kún inú ẹ̀ yìí, ó dà bíi pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ bá ẹnikẹ́ni dá àpárá mọ́, ńṣe ni wọ́n ń dì kunkun. Lóòótọ́ o, à ń gbé lákòókò tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gbòde kan, àmọ́ tí dídá àpárá ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́. Ìwé náà, El arte de la risa (Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Máa Rẹ́rìn-ín) sọ pé lóde òní, ó dà bíi pé “àrayé ti fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà rọ́pò ọmọ èèyàn.” Nígbà míì èdè tí wọ́n ń lò lórí kọ̀ǹpútà àti kọ̀ǹpútà fúnra rẹ̀ ti rọ́pò èdè tó jẹ mọ́ ẹ̀rín kèékèé, ìfaraṣàpèjúwe àti rírẹ́rìn-ín músẹ́.

Tí ẹni tó ń ṣàìsàn bá ń dápàárá, á ràn án lọ́wọ́ láti ní èrò, ìwà àti ìṣe tó túbọ̀ dára. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Jaime Sanz-Ortiz, tó jẹ́ ògbógi nínú títọ́jú àrùn jẹjẹrẹ àti dídín ìrora kù ṣe sọ, dídápàárá “máa ń jẹ́ kó rọrùn láti bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀, ó máa ń fún ara lágbára láti gbógun ti àrùn, ó máa ń dín ìrora àti àníyàn kù, ó ń jẹ́ kí ọkàn àti ara èèyàn lè balẹ̀, ó sì ń fún èèyàn ní ọgbọ́n ìdánúṣe àti ìrètí.”

Àǹfààní Ńláǹlà Tó Wà Nínú Dídápàárá

Kí ló mú kí dídápàárá máa ṣiṣẹ́ bí oògùn ajẹ́bíidán? Ìdí ni pé ó ń jẹ́ ká lè lẹ́mìí tó dáa nígbà tọ́ràn bá délẹ̀, kódà bí ìṣòro náà bá le koko bí ojú ẹja. Sanz-Ortiz sọ pé: “Tá a bá máa ń fi àpárá àti àwàdà kún ìgbésí ayé wa, agbára wa ò ní dín kù, àárẹ̀ ò ní máa mú wa tó bẹ̀ẹ́, a ò sí ní máa fàyè gba èrò pé a níṣòro.”

Kò yani lẹ́nu pé ohun tó lè pa ẹnì kan lẹ́rìn-ín tàbí kó mú un fẹyín yàtọ̀ sí tẹlòmíì, ti ẹ̀yà kan sì tún lè yàtọ̀ sí ti ẹ̀yà míì lórí èyí. Sanz-Ortiz ṣàlàyé pé: “Bó ṣe jẹ́ pé èyí wù mí ò wù ọ́ lọ̀rọ̀ ẹwà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé bí ọkàn ẹnì kan bá ṣe rí ló máa sọ ohun tó máa pa á lẹ́rìn-ín.” Ṣùgbọ́n ibi yòówù ká ti wá, ibi yòówù tá à báà kàwé dé, dídápàárá sábà máa ń jẹ́ ọ̀nà tó dáa gan-an láti rẹ́ni máa bá sọ̀rọ̀, ó sì tún jẹ́ ọ̀nà tó wúlò téèyàn lè gbà kó àníyàn, ìdààmú tàbí ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn ara ẹ̀. Tó bá wá jẹ́ pé dídápàárá lè ràn wá lọ́wọ́ tó báyìí, kí la lè ṣe tá a ó fi mọ béèyàn ṣeé dápàárá?

Ohun àkọ́kọ́ ni pé ká dẹ́kun ríronú púpọ̀ jù lórí àwọn ìṣòro wa tàbí àìsàn tó ń ṣe wá ká sì gbìyànjú láti máa wá ohun tó lè múnú wa dùn nínú gbogbo nǹkan tó bá ṣẹlẹ̀ sí wa. Bákan náà, ó yẹ ká sapá láti máa ronú lọ́nà títọ́, ká má fàyè gba ìrònú òdì tá á máa mú ká ronú pé ìṣòro wa ti pàpọ̀ jù. A tún lè fi kọ́ra láti máa dápàárá tá a bá mọ bá a ṣe lè máa wo àwọn ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Kò pọn dandan ká máa rẹ́rìn-ín tàbí ká máa fẹyín ní gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n tá a bá rí nǹkan tó dà bíi pé ó pani lẹ́rìn-ín nínú ọ̀ràn kan, ó lè mú kí ọ̀ràn náà ṣeé fewé mọ́. Sanz-Ortiz fọba lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Àpárá máa ń gbé ọkàn wa kúrò lára àníyàn wa ó sì máa ń mú ká lè fi ojú míì wo ìṣòro tá a ní . . . , á sì lè jẹ́ ká rọ́gbọ́n míì dá sí i.”

Òótọ́ ni pé dídápàárá kì í ṣe ojútùú sí gbogbo ìṣòro tá à ń dojú kọ lójoojúmọ́ o, síbẹ̀ ó sábà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ìṣòro wa tí a kò fi ní ṣìṣe tí ò sì ní kà wá láyà. Gẹ́gẹ́ bí Conchi ṣe sọ, “ẹni táìsàn bá ń ṣe á gbà pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré rárá, àmọ́ o ní láti gbìyànjú kó máa bàa di pé àìsàn tó ń ṣe ọ́ gba ẹ̀rín lẹ́nu ẹ pátápátá. Mo máa ń fi ìgbésí ayé mi wé ọgbà ewébẹ̀ níbi tí oríṣiríṣi ewébẹ̀ wà, ṣùgbọ́n ó máa ń dùn mí bí mo ti ń wò ó pé ọ̀kan nínú àwọn ewébẹ̀ tó hù síbẹ̀ ni àrùn tó ń ṣe mí. Síbẹ̀ mo máa ń gbé ti àrùn yẹn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, mi ò sì jẹ́ kó ba àwọn ewébẹ̀ yòókù nínú ọgbà yẹn, ìyẹn ìgbésí ayé mi jẹ́. Lóòótọ́, mi ò lè sọ pé mo ti ṣẹ́gun àrùn jẹjẹrẹ tó ń ṣe mí báyìí o, àmọ́ mò ń gbádùn ìgbésí ayé mi, ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Felix ọkọ Conchi àti Pili àbúrò Conchi máa ń fún un níṣìírí