Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Tó Ń Gbógun Ti Ìwé Mìíràn

Ìwé Tó Ń Gbógun Ti Ìwé Mìíràn

Ìwé Tó Ń Gbógun Ti Ìwé Mìíràn

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ

KÍ NÌDÍ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ní èrò tó lòdì nípa Bíbélì? Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìdáhùn sí ìbéèrè yìí lè jẹ́ nítorí ohun táwọn èèyàn kan lò láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn “àdámọ̀,” ìyẹn ni ìwé Index of Forbidden Books. Báwo ni ìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

Nígbà tí ìwé títẹ̀ bẹ̀rẹ̀, àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ìtara ọkàn gbà á. Àwọn póòpù bíi mélòó kan tiẹ̀ gbóṣùbà fún iṣẹ́ ìwé títẹ̀ yìí, tí àwọn àlùfáà kan pè ní “iṣẹ́ àtọ̀runwá.” Àmọ́ o, kò pẹ́ kò jìnnà làwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì wá rí i pé àwọn èèyàn ń lo ìwé títẹ̀ láti fi tan àwọn èròǹgbà tó lòdì sí ìlànà ẹ̀sìn Kátólíìkì kálẹ̀. Nítorí náà, ní ìparí ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún, wọ́n gbé àwọn òfin kalẹ̀ ní ọ̀pọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó wà nílẹ̀ Yúróòpù. Wọ́n pàṣẹ pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa gba àṣẹ kí wọ́n tó tẹ̀wé, nígbà tó sì di ọdún 1515 Àpérò Lateran Ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún gbé àwọn ìlànà kan jáde láti máa darí ìwé títẹ̀. Àwọn tó bá tàpá sí òfin yìí lè di ẹni tí wọ́n lé kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì. Àmọ́ o, òfin náà kò dá ìpínkiri àwọn ìwé tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbà pé ó lè ṣàkóbá fún ẹ̀kọ́ ìsìn àti ìlànà ìwà rere dúró, pàápàá lẹ́yìn táwọn Atẹ́sìnṣe dé. Nítorí náà, nígbà tó máa di ìparí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ohun tí àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń fẹ́ ni pé “kó má ṣe sí ìwé títẹ̀ mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún.”

Láti ṣèkáwọ́ “omilẹgbẹ àwọn ìwékíwèé” yìí, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Jesuit kan tó jẹ́ ará Ítálì ṣe pè é lọ́dún 1951, àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì fẹ́ láti ní ìwé àkọsílẹ̀ kan tó máa ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìwé tí wọ́n kà léèwọ̀ fún gbogbo ọmọ ìjọ Kátólíìkì. Lọ́dún 1542, wọ́n dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbógun Ti Àdámọ̀ sílẹ̀ ní ìlú Róòmù. Ohun tí ìgbìmọ̀ yìí kọ́kọ́ ṣe ni pé wọ́n gbé òfin kan jáde tó fòfin de títẹ ìwé tó bá jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn. Nígbà tí aṣáájú tẹ́lẹ̀rí fún ìgbìmọ̀ tó ń gbógun ti àdámọ̀, ìyẹn Gian Pietro Carafa, di Póòpù Paul Kẹrin lọ́dún 1555, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pàṣẹ pé kí ìgbìmọ̀ kan ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ìwé tí wọ́n fòfin dè sínú ìwé kan. Bí wọ́n ṣe tẹ ìwé Index of Forbidden Books àkọ́kọ́ tó wà fún àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì ní tilé-toko jáde nìyẹn lọ́dún 1559.

Irú Àwọn Ìwé Wo Ni Wọ́n Fòfin Dè?

“Apá” mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n pín ìwé Index náà sí. Nínú apá àkọ́kọ́, wọ́n to orúkọ gbogbo àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n fòfin de ìwé wọn, láìka ohun yòówù kí ìwé náà dá lé lórí sí. Nínú apá kejì, wọ́n to àkọlé gbogbo ìwé tí wọ́n fòfin dè lára ìwé àwọn òǹkọ̀wé kan. Nínú apá kẹta, wọ́n to ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìwé tí kò ní orúkọ òǹkọ̀wé, èyí tí wọ́n fòfin de. Ìwé Index náà ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́tàdínláàádọ́fà [1,107] òfin tí wọ́n ṣe láti tẹ iṣẹ́ àwọn òǹkọ̀wé rì, kì í ṣe àwọn ìwé tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn nìkan, àmọ́ ó tún kan irú àwọn ìwé mìíràn pẹ̀lú. Àsomọ́ kan tó wà lẹ́yìn ìwé náà ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n kà léèwọ̀, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó wà lédè táwọn èèyàn lè kà ni òfin dè.

Gigliola Fragnito, olùkọ́ nípa ìtàn òde òní ní Yunifásítì Parma tó wà lórílẹ̀-èdè Ítálì, sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òfin kan ti wà fún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò tẹ́lẹ̀, “àwọn òfin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tó kan gbogbo ẹlẹ́sìn Kátólíìkì yìí ni ṣọ́ọ̀ṣì fi sọ ní gbangba-gbàǹgbà pé àwọn ka títẹ Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀, kíkà á àti níní in lọ́wọ́ léèwọ̀.” Àtakò kékeré kọ́ làwọn òǹtàwé àtàwọn òǹṣèwé gbé dìde sí ìwé Index yìí, kódà ìjọba pàápàá kò gbẹ́yìn, nítorí pé wọ́n ń jàǹfààní látinú iṣẹ́ ìwé títẹ̀. Nítorí èyí àtàwọn ìdí mìíràn, wọ́n ṣètò fún ṣíṣe ìwé Index mìíràn, èyí tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1564 lẹ́yìn Àpérò Ìlú Trent.

Wọ́n dá ìgbìmọ̀ kan sílẹ̀ lákànṣe lọ́dún 1571 láti ṣiṣẹ́ lórí àtúnṣe ìwé náà, ìyẹn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìwé Index. Nígbà kan, ó tó ọ̀nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń gbà pinnu irú àwọn ìwé tí wọ́n máa fòfin dè, ìyẹn ni Ìgbìmọ̀ Ọ́fíìsì Mímọ́, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìwé Index àti alábòójútó ààfin ọlọ́wọ̀, tó jẹ́ ògbóǹkangí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tí póòpù yàn sípò. Ẹrù iṣẹ́ tó bára dọ́gba àti àìsí ìfohùnṣọ̀kan ní ti bóyá àwọn bíṣọ́ọ̀bù ni kí wọ́n fún lágbára sí i ni o tàbí àwọn tó ń gbógun ti àdámọ̀ wà lára àwọn ohun tó mú kó pẹ́ kí wọ́n tó tẹ ìwé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè ẹlẹ́ẹ̀kẹta jáde. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìwé Index ló ṣàkójọ ìwé náà, Póòpù Clement Kẹjọ ló sì fọwọ́ sí i ní March 1596. Àmọ́ o, Ìgbìmọ̀ Ọ́fíìsì Mímọ́ bẹ́gi dínà ìmújáde ìwé náà títí dìgbà tó wá di dandan pé kí wọ́n lò ó láti fòfin de kíka Bíbélì èyíkéyìí tí a túmọ̀ sí àwọn èdè ìbílẹ̀.

Ìwé Index of Forbidden Books tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde yìí fìdí múlẹ̀ gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé látìgbàdégbà ni wọ́n ń ṣe àtúnṣe sí i jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, tí wọ́n rí i pé ìwé àwọn wà lára àwọn ìwé tí a fòfin dè yìí, pe ìwé Index náà ní “ọ̀nà tó dára jù lọ láti fi mọ àwọn ìwé tó pójú owó.” Àmọ́ o, nígbà yẹn náà, ọ̀pọ̀ lára èròǹgbà àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ló fara jọ ti àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó bá di ọ̀ràn ṣíṣàyẹ̀wò ìwé àti kíkà á léèwọ̀.

Ìwé Index yìí ṣàkóbá gidigidi fún àṣà ìbílẹ̀, nítorí pé láwọn orílẹ̀-èdè bí Ítálì, “ó ṣèdíwọ́ fún ìdàgbàsókè” gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Antonio Rotondò ṣe sọ. Òpìtàn mìíràn tó ń jẹ́ Guido Dall’Olio sọ pé ìwé Index náà jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì tó mú ìfàsẹ́yìn bá orílẹ̀-èdè Ítálì, ní ìfiwéra pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nílẹ̀ Yúróòpù.” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwọn ìwé kan là á já nítorí pé ibi àkànṣe kan ni wọ́n lọ kó wọn sí, ìyẹn ni ibì kan tó wà ní ọ̀pọ̀ àwọn ibi ìkówèésí ṣọ́ọ̀ṣì, níbi tí wọ́n ń kó àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè pa mọ́ sí, tí wọ́n sì tì wọ́n pa mọ́bẹ̀ gbọin-gbọin.

Àmọ́ o, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ táwọn èèyàn ní ní àkókò ọ̀làjú wá di ọ̀kan lára àwọn ohun tó mú kí “ọ̀nà bíburú jáì jù lọ láti fi gbógun ti òmìnira ìwé títẹ̀” di ohun ìgbàgbé. Lọ́dún 1766, òǹṣèwé ará ilẹ̀ Ítálì kan kọ̀wé pé: “Kíkà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń ka ìwé léèwọ̀ kọ́ ló ń pinnu bóyá ìwé kan dára tàbí kò dára. Ọwọ́ àwọn aráàlú nìyẹn wà.” Bí ìwé Index ṣe di ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ mọ́ nìyẹn, nígbà tó sì di ọdún 1917 wọ́n tú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìwé Index ká. Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1966, ìwé Index “kò ní agbára òfin ṣọ́ọ̀ṣì láti gbógun ti àwọn ìwé mìíràn mọ́.”

Bíbélì ní Èdè Ìbílẹ̀

Ìtàn ìwé Index fi hàn pé nínú gbogbo àwọn ìwé tí àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì kà sí ìwékíwèé, ẹyọ kan wà ní pàtàkì tó ń kọ wọ́n lóminú, ìyẹn ni Bíbélì tó wà ní èdè tí tọmọdé tàgbà lè kà. Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, “nǹkan bí ẹẹ́wàálénígba [210] ẹ̀dà Bíbélì lódindi tàbí Májẹ̀mú Tuntun,” ló wà lára àwọn ìwé tí àwọn ìwé Index náà fòfin dè, gẹ́gẹ́ bí àlàyé ògbógi Jesús Martinez de Bujanda. Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ẹni tó ń fi ìtara ọkàn ka Bíbélì làwọn èèyàn mọ àwọn ará Ítálì sí. Síbẹ̀, nítorí bí ìwé Index náà ṣe ka Ìwé Mímọ́ lédè ìbílẹ̀ léèwọ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ó ṣàkóbá gidigidi fún àjọṣe orílẹ̀-èdè yìí pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Olùkọ́ Fragnito sọ pé: “Níwọ̀n bí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́ léèwọ̀, tí wọ́n sì mú kí àwọn ará Ítálì máa wò ó gẹ́gẹ́ bí ìwé tó jẹ́ orísun àdámọ̀, ohun tó fà á nìyí tí àwọn èèyàn fi máa ń fi àṣìṣe kà á sí ìwé àwọn aládàámọ̀.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìwé katikísìmù ni ọ̀nà ìgbàlà fún àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tó wà ní gúúsù Yúróòpù,” àti pé “àwọn tí kò lóye ọ̀ràn ẹ̀sìn jinlẹ̀ làwọn àlùfáà fẹ́ràn ju àwọn tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí lọ.”

Ìgbà tó di ọdún 1757 ni Póòpù Benedict Kẹrìnlá tó fàṣẹ sí kíka ‘àwọn Bíbélì tó wà lédè ìbílẹ̀, èyí tí Ọ́fíìsì Póòpù bá ti fọwọ́ sí.’ Nípa báyìí, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n wá lè ṣe ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn lédè Ítálì, èyí tí wọ́n gbé ka ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì Latin Vulgate. Àní sẹ́, àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tó jẹ́ ará Ítálì ní láti dúró títí di ọdún 1958 kí wọ́n tó ní odindi ìtumọ̀ Bíbélì àkọ́kọ́ tí a gbé ka àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Olùkọ́ Fragnito sọ pé lónìí, àwọn tí kì í ṣe Kátólíìkì gan-an ni wọ́n ń fi aápọn “pín Ìwé Mímọ́ káàkiri.” Kò sí àní-àní pé, lára àwọn tí ọwọ́ wọn dí jù lọ nínú ìgbòkègbodò yìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ti pín ohun tó ju mílíọ̀nù mẹ́rin ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Ítálì. Wọ́n ti tipa báyìí ta ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jí lọ́kàn ẹgbàágbèje èèyàn. (Sáàmù 119:97) O ò ṣe túbọ̀ mọ ìwé aláìlẹ́gbẹ́ yìí dunjú?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Àwọn ojú ìwé kan látinú ìwé “Index of Forbidden Books”

[Credit Line]

Su concessione del Ministero per i Beni e le Attività Culturali

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Bíbélì lédè Ítálì ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún tí ṣọ́ọ̀ṣì kà léèwọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Bíbélì ní “Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” ti ta ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jí lọ́kàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn