Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Táwọn Ìlànà Fi Ń Yí Padà

Ìdí Táwọn Ìlànà Fi Ń Yí Padà

Ìdí Táwọn Ìlànà Fi Ń Yí Padà

“Kí ló ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé?”

Ìbéèrè yìí ni wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ní ọgọ́ta orílẹ̀-èdè. Àjọ Aṣèwádìí tó ń jẹ́ Gallup sọ pé, èsì tó wọ́pọ̀ ní ibi púpọ̀ jù lọ lágbàáyé ni “kéèyàn ní ìdílé aláyọ̀” àti “kéèyàn ní ìlera tó jíire.”

BÉÈYÀN bá kọ́kọ́ gbọ́ ìdáhùn àwọn èèyàn yìí, á dà bí ẹni pé irú àwọn ìlànà dáradára kan náà ni gbogbo ayé lápapọ̀ ń tẹ̀ lé. Àmọ́, kì í ṣe bí wọ́n kúkú ṣe sọ ọ́ lẹ́nu yẹn náà ni nǹkan rí. Láyé àtijọ́, àwọn ìlànà ẹ̀sìn àtàwọn ìlànà ìwà rere tó ti wà látayébáyé làwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé. Àmọ́, kíákíá ni nǹkan ń yí padà báyìí. Nígbà tí olùwádìí nì, Marisa Ferrari Occhionero ń sọ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ ní orílẹ̀-èdè Ítálì, ó sọ pé: “Ìṣesí àwọn èwe ìwòyí fi hàn pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ka àwọn ìlànà táwọn òbí wọn ń tẹ̀ lé sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ka àwọn ìlànà tó ti wà látayébáyé àtàwọn ìlànà ẹ̀sìn sí pàtàkì mọ́.” Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn yíká ayé, àtọmọdé àtàgbàlagbà.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ronald Inglehart, tó jẹ́ olùṣekòkárí ètò kan tí wọ́n pè ní Wíwádìí Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Hùwà Rere Sí Lágbàáyé, sọ pé: “Ẹ̀rí tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń fi hàn pé àwọn ìyípadà kíkàmàmà ń wáyé nínú ojú táwọn èèyàn fi ń wo nǹkan kárí ayé.” Kí ló ń fa àwọn ìyípadà yìí? Inglehart sọ pé: “Àwọn ìyípadà wọ̀nyí ń fi hàn pé ìyípadà ti ń wáyé nínú ètò ọrọ̀ ajé àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ.”

Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí tí Àjọ Aṣèwádìí tó ń jẹ́ Gallup ṣe fi hàn pé, láwọn orílẹ̀-èdè tó ti rọ́wọ́ mú, “ọwọ́ ẹ̀yìn” làwọn èèyàn to iṣẹ́ sí nínú àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé. Ṣùgbọ́n láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, kéèyàn níṣẹ́ lọ́wọ́ ló jẹ wọ́n lógún jù lọ! Òótọ́ ni, nígbà táwọn èèyàn ò bá rọ́wọ́ họrí, bí wọ́n á ṣe máa rí ohun tí wọ́n nílò lójúmọ́ ló máa ń ṣe pàtàkì sí wọn jù. Àmọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè bá ṣe wá ń lówó sí i, àwọn èèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí gbájú mọ́ àwọn nǹkan bíi níní ìlera tó dára, níní ìdílé aláyọ̀, àti ṣíṣe ohunkóhun tó bá sáà ti wà lọ́kàn ẹni.

Pẹ̀lú bí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó dájú pé àwọn ìlànà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dóde yìí máa nípa lórí àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ The Futurist sọ pé: “Àwọn ohun tí à ń rí àtàwọn ohun tí à ń gbọ́ sétí ló ń pinnu ohun tá a gbà gbọ́ àti ìlànà tí à ń tẹ̀ lé.” Nípa bẹ́ẹ̀, ipa kékeré kọ́ làwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ti ní lórí àwọn ìlànà táwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń tẹ̀ lé. Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Gbogbo ayé pátá làwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn wọ̀nyí ti ń nípa lórí àwọn èèyàn.”

Irú àwọn ìyípadà wo là ń rí nínú ìwà àti ìṣesí àwọn èèyàn? Ọ̀nà wo làwọn ìlànà tó ń yí padà yìí ń gbà nípa lórí rẹ àti lórí ìdílé rẹ?