Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Là Ń Sọ Oúnjẹ Wa Dà?

Kí Là Ń Sọ Oúnjẹ Wa Dà?

Kí Là Ń Sọ Oúnjẹ Wa Dà?

KÁ MÁA yí oúnjẹ padà sí oríṣi mìíràn kì í ṣe nǹkan tuntun. Kódà, àtìrandíran làwọn èèyàn ti mọ ọ̀nà tí wọ́n fi ń yí oúnjẹ padà. Mímọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi ń mú nǹkan pọ̀ sí i ti yọrí sí níní oríṣiríṣi irè oko tuntun, màlúù àti àgùntàn tó pọ̀ sí i. Àní, ẹnì kan tó ń ṣojú Àjọ Tó Ń Bójú Tó Oúnjẹ àti Oògùn ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo oúnjẹ tó o bá rà ni wọ́n á ti fi nǹkan tó ń mú kí oúnjẹ pọ̀ yí padà.”

Mímú oúnjẹ pọ̀ sí i nìkan kọ́ lohun tó ń pa oúnjẹ dà. Àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣòwò oúnjẹ náà ti ṣàwárí oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n fi ń yí oúnjẹ padà sí oríṣi mìíràn tí wọ́n á sì lú àwọn nǹkan mìíràn mọ́ wọn, bóyá láti mú kó túbọ̀ dùn, kí ojú rẹ̀ lè wuni sí i tàbí kó lè bá ohun tó lòde mu kó má sì tètè bà jẹ́. Ó ti wá mọ́ àwọn èèyàn lára báyìí láti máa jẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti yí padà lọ́nà kan tàbí òmíràn.

Àmọ́ ńṣe ni iye àwọn òǹrajà tọ́kàn wọn kò balẹ̀ nítorí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí oúnjẹ wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Kí nìdí? Àwọn kan ń bẹ̀rù pé ńṣe ni àwọn ìlànà òde òní tí wọ́n ń lò báyìí ń sọ oúnjẹ wa di eléwu. Ṣé ìbẹ̀rù wọn tọ̀nà? Ẹ jẹ́ ká wo apá ibi mẹ́ta tọ́kàn àwọn èèyàn ò ti balẹ̀. a

Omi Ara Tí Ń Súnni Ṣe Nǹkan Àtàwọn Oògùn Agbóguntàrùn

Láwọn ibì kan, láti àwọn ọdún 1950 ni wọ́n ti ń lú oògùn agbóguntàrùn díẹ̀díẹ̀ mọ́ oúnjẹ adìyẹ, ẹlẹ́dẹ̀ àti màlúù. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe èyí ni láti dín àìsàn kù, pàápàá láwọn ibi tó jẹ́ pé ojú kan náà ni wọ́n ń kó àwọn ẹran ọ̀sìn sí. Láwọn ilẹ̀ kan, wọ́n tún máa ń lú àwọn omi ìsúnniṣe-nǹkan mọ́ oúnjẹ ẹran ọ̀sìn kí wọ́n lè dàgbà kíákíá. Àwọn omi ìsúnniṣe-nǹkan àtàwọn oògùn agbóguntàrùn yìí ni wọ́n sọ pé ó máa ń dáàbò bo àwọn ẹran ọ̀sìn lọ́wọ́ àrùn tó sì ń jẹ́ kí iṣẹ́ àgbẹ̀ aládàá-ńlá túbọ̀ lérè lórí. Wọ́n ní àwọn tó ń rà wọ́n náà á tún jàǹfààní nítorí pé àwọn ọjà náà kò ní gbówó lórí púpọ̀.

Ó jọ pé ọgbọ́n wà nínú àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe yìí. Ṣùgbọ́n ṣé àwọn ẹran tí wọ́n ti fi nǹkan lú oúnjẹ wọn yìí kò léwu fún àwọn èèyàn tó máa rà wọ́n jẹ? Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ètò Ọrọ̀ Ajé àti Ti Ọ̀ràn Àwùjọ Àwọn Ará Yúróòpù parí ọ̀rọ̀ pé, ó ṣeé ṣe káwọn oògùn náà má pa àwọn kòkòrò bakitéríà kí wọ́n sì kọjá sára àwọn tó máa ra àwọn ẹran náà jẹ. Ìròyìn náà sọ pé: “Lára àwọn kòkòrò yìí, irú bíi Salmonella àti Campylobacter, tó lè wà nínú ẹran tí kò jinná dáadáa tàbí ẹran alárùn lè jẹ́ ohun tó ń fa bí àwọn èèyàn ṣe ń kó àìsàn burúkú látinú oúnjẹ.” Yàtọ̀ síyẹn, tí kì í bá ṣe kòkòrò nìkan ni àwọn ẹran náà ní ńkọ́ àmọ́ tí àwọn oògùn apakòkòrò tún ṣẹ́ kù sí wọn lára? Ìbẹ̀rù tí èyí ti dá sílẹ̀ ni pé, àwọn kòkòrò tó ń fa àìsàn sí èèyàn lára lè di bóorán, tí oògùn kò ní lè kápá wọn mọ́.

Tàwọn ẹran tí wọ́n ń lo omi ìsúnniṣe-nǹkan fún ńkọ́? Dókítà Heinrich Karg tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní ìlú Munich, ní orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Gbogbo àwọn ògbógi ló fohùn ṣọ̀kan pé ẹran tó wá láti ara àwọn nǹkan ọ̀sìn tí wọ́n ti fi omi ìsúnniṣe-nǹkan yí láyé padà kò lè pààyàn lára tí wọ́n bá ṣáà ti lo oògùn náà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ṣe sọ.” Àmọ́ ṣá o, ohun tí ìwé ìròyìn Die Woche sọ nípa ọ̀rọ̀ bóyá ó léwu tàbí kò léwu láti máa jẹ àwọn ẹran tí wọ́n ń fi omi ìsúnniṣe-nǹkan sínú oúnjẹ wọn ni pé, “láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, àwọn olùwádìí kò tíì lè fohùn ṣọ̀kan.” Ní ilẹ̀ Faransé sì rèé, àsọtúnsọ ni wọ́n ń sọ ọ́ pé, ‘Rárá o! Wọn ò gbọ́dọ̀ lo omi ìsúnniṣe-nǹkan fún àwọn ẹran!’ Èyí fi hàn gbangba pé, àríyànjiyàn náà ṣì ń lọ ní rẹbutu.

Àwọn Oúnjẹ Tí Wọ́n Lo Ìtànṣán Fún

Látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ní ilẹ̀ Sweden ní 1916, ó kéré tán, orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógójì ló ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa gbé àwọn èròjà oúnjẹ bí ànàmọ́, àgbàdo, èso àti ẹran sábẹ́ ìtànṣán fúngbà díẹ̀. Kí ni iṣẹ́ tí wọ́n ní ìtànṣán ń ṣe? Wọ́n ní ó máa ń pa oríṣiríṣi kòkòrò tó ń fa àrùn, tí á sì tipa bẹ́ẹ̀ dín àìsàn táwọn èèyàn lè kó látinú oúnjẹ wọ̀nyẹn kù. Kì í tún jẹ́ kí oúnjẹ tètè bà jẹ́.

Àmọ́ o, àwọn ògbógi sọ pé ohun tó dára jù lọ ni pé kí àwọn ohun tẹ́nu ń jẹ wà ní mímọ́ tónítóní kó sì tutù yọ̀yọ̀. Àmọ́ ta ló ráyè àtimáa ṣe wàhálà tó wà nídìí àwọn oúnjẹ títutù yọ̀yọ̀ nígbà gbogbo? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Test ti sọ, àkókò tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń lò nídìí oúnjẹ báyìí kò ju “ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ fún oúnjẹ àárọ̀, ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún oúnjẹ ọ̀sán àti ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún oúnjẹ alẹ́.” Abájọ tí àwọn òǹrajà kúkú fi yàn láti máa ra àwọn nǹkan jíjẹ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ tí kì í sì í tètè bà jẹ́. Àmọ́ ṣe àwọn ohun tẹnu ń jẹ tí wọ́n ń gbé sábẹ́ ìtànṣán yìí kò léwu nínú?

Àjọ Ìlera Àgbáyé tẹ ìwádìí kan tí àwọn ògbógi jákèjádò àgbáyé ṣe jáde ní 1999. Wọ́n ní èròjà oúnjẹ tí wọ́n gbé sábẹ́ ìtànṣán “kò léwu kankan nínú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn èròjà aṣaralóore inú rẹ̀ pé pérépéré.” Àwọn tó fara mọ́ pé kí wọ́n máa lo ìtànṣán fún oúnjẹ fi wé bí wọ́n ṣe máa ń pa kòkòrò inú báńdéèjì ní ọsibítù, tó jẹ́ pé ìtànṣán náà ni wọ́n ń lò. Wọ́n tún fi wé bi ẹrù ṣe máa ń kọjá lábẹ́ ẹ̀rọ oníná tó ń yẹ ẹrù wò ní pápákọ̀ òfuurufú. Àmọ́, àwọn tó ń ṣe òfíntótó ẹ̀ kò yé é sọ pé, ńṣe ni títan ìtànṣán sórí àwọn nǹkan tẹ́nu ń jẹ máa ń dín àwọn ohun tó ń ṣara lóore nínú wọn kù ó sì lè ní àwọn ewu kan nínú èyí tí wọn ò tíì mọ̀ báyìí.

Àwọn Oúnjẹ Tí Wọ́n Yí Àbùdá Wọn Padà

Ó ṣe díẹ̀ báyìí tí ó ti ṣeé ṣe fún àwọn onímọ̀ nípa àbùdá láti mú àbùdá kan láti ara ìṣẹ̀dá kan kí wọ́n sì fi sínú òmíràn tí wọ́n jọ jẹ́ ara ọ̀wọ́ kan náà. Àmọ́ lọ́jọ́ òní, àwọn onímọ̀ nípa àbùdá ti lè ṣe ju ìyẹn lọ fíìfíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èso kan àtàwọn tòmátì kan wà tó jẹ́ pé wọ́n ti fi àbùdá kan tí wọ́n mú láti ara ẹja kan yí wọn padà, èyí tá á jẹ́ kí wọ́n lè dàgbà láwọn àgbègbè tí òtútù wà.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni wọ́n ti sọ láti fi ti fífi àbùdá yí oúnjẹ padà lẹ́yìn tàbí láti fi ta kò ó. b Àwọn tó ń ṣalágbàwí rẹ̀ sọ pé pípa ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ti ohun alààyè pọ̀ lọ́nà yìí ṣe é gbára lé àti pé ó ṣeé ṣàkóso ju àwọn ọ̀nà tí wọ́n ti fi ń mú oúnjẹ pọ̀ látayébáyé lọ, wọ́n tún sọ pé á jẹ́ kí àwọn irè oko pọ̀ sí i á sì jẹ́ kí ebi tó ń pa aráyé dín kù. Àmọ́ ṣé jíjẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti yí àbùdá wọn padà yìí kò lè ṣèèyàn léṣe?

Àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ń ṣojú fún àwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, títí kan ilẹ̀ Brazil, China, Íńdíà, Mẹ́síkò àtàwọn orílẹ̀-èdè míì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ṣe ìwé kan jáde lórí kókó yìí. Ìwé náà tí wọ́n tẹ̀ jáde ní oṣù July ọdún 2000 sọ pé: “Títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ti ju ọgbọ̀n mílíọ̀nù hẹ́kítà ilẹ̀ lọ tí wọ́n ti fi gbin àwọn irè oko tí wọ́n ti yí àbùdá wọn padà, kò sì tíì sí ìṣòro ìlera kankan tí wọ́n lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn irè oko yìí ló fà á.” Láwọn àgbègbè kan, wọ́n gbà gbọ́ pé bí àwọn oúnjẹ tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ kò ṣe léwu nínú náà làwọn tí wọ́n yí àbùdá wọn padà náà kò ṣe léwu nínú.

Àmọ́ o, láwọn apá ibòmíràn, wọn ò yéé ṣiyèméjì nípa rẹ̀. Ní orílẹ̀-èdè Austria, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Faransé, àwọn kan ṣì ń fura sí àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti yí àbùdá wọn padà yìí. Olóṣèlú kan ní ilẹ̀ Netherlands sọ nípa àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti yí àbùdá wọn padà pé: “Àwọn oúnjẹ kan wà tó jẹ́ pé a ò kàn tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí wọn.” Àwọn tó ń kọminú sí irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ tún béèrè àwọn ìbéèrè olórí pípé kan àtàwọn ewu tó lè ṣe fún àyíká.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ronú pé, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tí ọ̀rọ̀ yíyí àbùdá irè oko padà bẹ̀rẹ̀, ó yẹ kí àyẹ̀wò ṣì máa lọ lórí rẹ̀ nípa àwọn ewu tó lè ṣe fún àwọn tó ń jẹ ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbà pé lóòótọ́ ni lílo àbùdá lọ́nà yìí jọ pé ó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní tó pọ̀. Síbẹ̀, ó sọ pé àwọn ohun kan wà tó ṣì ń kọni lóminú, irú bí àwọn ìṣòro tí àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti yí àbùdá wọn padà yìí lè fà, ìyẹn sì túmọ̀ sí pé “ó pọn dandan láti túbọ̀ ṣe ìwádìí sí i.”

Bí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tí Kò Fì Síbì Kan

Àwọn ilẹ̀ kan wà tó jẹ́ pé ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ohun tí wọ́n ń jẹ ni wọ́n ti fi ìmọ̀ ẹ̀rọ yí padà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń lo àwọn èròjà kan láti gbé adùn oúnjẹ tàbí àwọ̀ wọn yọ, kí wọ́n má sì lè tètè bà jẹ́. Kódà ìwé ìwádìí kan sọ pé “kò sí bí àwọn oúnjẹ tó wọ́pọ̀ lóde òní, irú bí àwọn oúnjẹ tí kì í mára wúwo, ìpápánu, àtàwọn oúnjẹ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀, ṣe lè ṣeé ṣe láìsí àwọn èròjà wọ̀nyẹn.” Ó sì ṣeé ṣe kí irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ní àwọn èròjà tí wọ́n ti yí àbùdá wọn padà nínú.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, kárí ayé ni àwọn èèyàn ti ń lo àwọn ọ̀nà iṣẹ́ àgbẹ̀ kan táwọn èèyàn ń wò pé ó léwu. Àpẹẹrẹ kan ni ti lílo àwọn oògùn apakòkòrò tó ní májèlé nínú. Yàtọ̀ síyẹn, ó pẹ́ táwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe oúnjẹ jáde ti ń lo àwọn èròjà tó jẹ́ pé bóyá ni kò ní jẹ́ òun ló ń fa ìṣòro fún àwọn tó ń rà wọ́n jẹ. Ṣé àwọn ọ̀nà ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun tí wọ́n ń lò fún oúnjẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí kò burú ju àwọn ìyẹn lọ? Ẹnu àwọn ògbógi gan-an kò kò lórí ìyẹn. Kódà, kò sí èyí tí àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tì lẹ́yìn nínú wọn ó sì dà bí ẹni pé ńṣe lèyí túbọ̀ ń dá kún bí èrò àwọn èèyàn ṣe ń yàtọ̀ síra.

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ti wá pinnu pé àwọn ò ní jẹ́ kí ọ̀ràn yìí kó ìdààmú bá àwọn, nítorí kò kúkú sí bí àwọn ṣe lè yẹra pátápátá fún àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti fi ìmọ̀ ẹ̀rọ yí padà àti pé àwọn ní nǹkan mìíràn tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ láti gbájú mọ́. Àmọ́ o, àwọn kan wà tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ń kó láyà sókè gan-an. Bí kò bá dá ìwọ àti ìdílé rẹ lójú bóyá kẹ́ ẹ máa jẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti fi ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní yí padà, kí lo lè ṣe? Àwọn ohun bíbọ́gbọ́nmu kan wà tó o lè yàn láti ṣe, a sì jíròrò díẹ̀ lára wọn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí. Àmọ́ o, yóò dára ká kọ́kọ́ ní èrò tó tọ́ nípa ọ̀ràn náà.

Bí ọ̀ràn ìlera lọ̀ràn kóúnjẹ má ṣèèyàn ní jàǹbá rí. Kò sí bí ọwọ́ wa ṣe lè tẹ̀ ẹ́ lọ́nà tó pé pérépéré lásìkò tá a wà yìí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì tó ń jẹ́ natur & kosmos ti sọ, kódà láàárín àwọn tó máa ń ṣọ́ ohun tí wọ́n ń jẹ gidigidi àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sè é, àwọn ohun tí ń ṣara lóore kì í fìgbà gbogbo tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Ohun tó ṣara ẹnì kan lóore lè ṣe ẹlòmíràn ní jàǹbá. Ṣé kò wá bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé ká wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ká sì yẹra fún títi àṣejù bọ ọ̀rọ̀ náà?

Òótọ́ ni pé, Bíbélì kò sọ ìpinnu wo ló yẹ ká ṣe nípa àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń lo ọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ gíga òde òní fún. Àmọ́, ó kọ́ wa ní ànímọ́ kan tó yẹ ká ní èyí tá á ràn wá lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn yìí. Fílípì 4:5 sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” Fífi òye mọ nǹkan yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó wà déédéé ká sì yẹra fún títi àṣejù bọ̀ ọ́. Ó lè jẹ́ ká yẹra fún bíbẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn ẹlòmíràn pé ohun báyìí ló yẹ kí wọ́n ṣe tàbí ni kò yẹ kí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà. Ó sì tún lè jẹ́ ká yàgò fún àríyànjiyàn tó lè dá ìpínyà sílẹ̀ láàárín àwa àtàwọn tí ohun tí wọ́n rò lórí kókó náà lè yàtọ̀ sí tiwa.

Síbẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìpalára tí oúnjẹ máa ń fà kì í fi bẹ́ẹ̀ fa iyàn jíjà. Kí ni díẹ̀ lára wọn, àwọn ìṣọ́ra wo lo sì lè lò láti dáàbò ara rẹ àti ìdílé rẹ?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Olúkúlùkù ló ni ìpinnu lórí irú oúnjẹ yòówù tó bá yàn láti máa jẹ. Jí! kò dámọ̀ràn pé oríṣiríṣi àwọn oúnjẹ tá a jíròrò níbí ni kéèyàn máa jẹ tàbí ni kó má jẹ, láìka irú ìmọ̀ ẹ̀rọ yòówù tí wọ́n fi ṣe wọ́n sí. Ohun tí àwọn àpilẹ̀kọ yìí wà fún ni láti jẹ́ kí àwọn òǹkàwé wa mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

b Jọ̀wọ́ wo Jí! April 22, 2000. (Gẹ̀ẹ́sì)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ṣé ìpalára kan wà tí àwọn ẹran tí wọ́n ń fún ní omi ìsúnniṣe-nǹkan àti oògùn agbóguntàrùn ń ṣe fáwọn tó ń jẹ wọ́n?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ó bọ́gbọ́n mu pé kó o máa ka àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára oúnjẹ tí ò ń rà dáadáa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ríra àwọn irè oko òòjọ́ látìgbàdégbà ní àwọn àǹfààní tó ń ṣe