Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́

Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́

Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́

“Nínú ayé kan tí ìkọ̀sílẹ̀ ti pọ̀ jaburata yìí, àfèèṣì ni kò fi ní jẹ́ pé ohun tó máa gbẹ̀yìn púpọ̀ àwọn ìgbéyàwó tí kò láyọ̀ nìyẹn. Ó sì tún ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tún di aláìláyọ̀.”—ẸGBẸ́ TÓ Ń ṢÈWÁDÌÍ NÍPA Ọ̀RÀN ÌDÍLÉ NÍ AMẸ́RÍKÀ.

ÀWỌN alákìíyèsí ti sọ pé inú ìgbéyàwó ni púpọ̀ nínú ayọ̀ téèyàn ń ní láyé àti wàhálà téèyàn ń kó sí láyé ti ń wá. Lóòótọ́, nínú ìgbésí ayé, ìwọ̀nba ni ohun tó lè fúnni ní ayọ̀ púpọ̀ jọjọ—tàbí kí ó kó làásìgbò báni lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ìgbéyàwó. Bí àpótí tó wà nínu àpilẹ̀kọ yìí ti fi hàn, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni ìdààmú tó pọ̀ ju agbára wọn lọ ń bá.

Ṣùgbọ́n apá kan ìṣòro náà ni àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìkọ̀sílẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ fi hàn. Bí ìgbéyàwó kan péré bá forí ṣánpọ́n, àìmọye àwọn mìíràn ni kò tíì forí ṣánpọ́n ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé wàhálà kò tán rí nínú ìgbéyàwó náà. Obìnrin kan tó ti lé ní ọgbọ̀n ọdún tó ti wọnú ìdè ìgbéyàwó sọ láṣìírí pé: “Ìdílé aláyọ̀ ni ìdílé wa tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ọdún méjìlá tó kọjá kò rọgbọ fún wa rárá. Ọkọ mi kò tiẹ̀ fẹ́ mọ nǹkan kan nípa mi mọ́. Kí n sọ tòótọ́, òun ni ọ̀tá mi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bà mí lọ́kàn jẹ́ jù lọ.” Bákan náà, ọkọ kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó ti gbéyàwó kédàárò pé: “Ìyàwó mi ti sọ fún mi pé òun kò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́. Ó sọ pé, ó tẹ́ òun lọ́rùn ká kàn jọ máa gbélé, kí olúkúlùkù sì máa ṣe tiẹ̀.”

Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn kan tí wọ́n ní irú ìṣòro lílekoko yẹn máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì wà tí wọn kì í ronú nípa kíkọ ara wọn sílẹ̀. Èé ṣe? Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé Karen Kayser ti sọ, àwọn ìdí tó ń fà á ni ọmọ tí wọ́n ti bí, orúkọ burúkú tó lè fà fún wọn láwùjọ, ìṣúnná owó, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn ẹbí, àti ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn lè mú kí tọkọtaya kan ṣì wà papọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní sí ìfẹ́ láàárín wọn. Ó sọ pé: “Nítorí pé ó lè má ṣeé ṣe fún àwọn tọkọtaya yìí láti kọ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n á kúkú yàn láti máa gbé papọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n á ti kọ ara wọn sílẹ̀ nínú ọkàn wọn.”

Ṣé ọ̀ranyàn ni kí tọkọtaya tí àárín wọn kò gún régé mọ́ máa gbé pọ̀ láìsí ìtẹ́lọ́rùn ni? Ṣé ọ̀nà kan ṣoṣo táa lè fi yẹra fún ìkọ̀sílẹ̀ ni ká wà nínú ìdè ìgbéyàwó àmọ́ ká máà nífẹ̀ẹ́ ara ẹni? Ìrírí fi hàn pé a lè yọ ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó nínú làásìgbò tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀—a lè yọ wọ́n nínú àìfararọ tí ìkọ̀sílẹ̀ ń fà àti nínú ẹ̀dùn ọkàn tí àìnífẹ̀ẹ́ ara ẹni ń fà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

BÍ ÌKỌ̀SÍLẸ̀ ṢE PỌ̀ TÓ LÁWỌN IBÌ KAN LÁGBÀÁYÉ

Ọsirélíà: Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1960 ni iye àwọn tọkọtaya tí ń kọ ara wọn sílẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́rin.

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì: Gẹ́gẹ́ bí àwítẹ́lẹ̀, mẹ́rin lára ìgbéyàwó mẹ́wàá ni yóò yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀.

Kánádà àti Japan: Ìkọ̀sílẹ̀ ń fòpin sí nǹkan bí ìlàta gbogbo ìgbéyàwó.

Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà: Láti ọdún 1970, kò sí ìdánilójú pé àwọn tọkọtaya tó ń ṣègbéyàwó yóò gbé pọ̀ tàbí pé wọn kò ní gbé pọ̀.

Zimbabwe: Ìkọ̀sílẹ̀ ló ń gbẹ̀yìn nǹkan bí méjì lára ìgbéyàwó márùn-ún.