Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ǹjẹ́ Ò Ń Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library?

Ǹjẹ́ Ò Ń Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library?

Gbogbo èèyàn ni ètò ìṣiṣẹ́ JW Library wà fún. Ó máa jẹ́ kó o lè wa Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde, àwọn fídíò àtàwọn ohùn àtẹ́tísí jáde sórí fóònù, tablet tàbí kọ̀ǹpútà rẹ.

BÓ O ṢE LÈ NÍ JW Library: Lọ síbi tí wọ́n ń kó àwọn ètò ìṣiṣẹ́ sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn app store, kó o wá ètò ìṣiṣẹ́ JW Library níbẹ̀, kó o sì gbé e sórí fóònù tàbí tablet rẹ. Wàá rí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library tó máa ṣiṣẹ́ lórí onírúurú ẹ̀rọ níbẹ̀. Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wàá ti ṣí ètò ìṣiṣẹ́ yìí, tí wàá sì yan èyí tó lè ṣiṣẹ́ lórí fóònù tàbí tablet rẹ. Tí o kò bá ní Íńtánẹ́ẹ̀tì nílé, o lè lo Íńtánẹ́ẹ̀tì ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yín tẹ́ ẹ bá ní tàbí láwọn ibòmíì tó o ti lè rí Íńtánẹ́ẹ̀tì lò. Tó o bá ti lè wa ìtẹ̀jáde kan jáde sórí JW Library tó wà lórí fóònù tàbí tablet rẹ, o kò nílò Íńtánẹ́ẹ̀tì mọ́ nígbàkigbà tó o bá fẹ́ kà á. Ó gba pé kó o máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì déédéé, kó o sì máa rí i dájú pé o ní ètò ìṣiṣẹ́ JW Library tó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ lórí rẹ̀ tá a bá ti gbé e sí app store.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O NÍ JW Library? Ó máa jẹ́ kó ò lè ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó rọrùn, wàá sì tún lè lò ó tó o bá wà nípàdé. Ó tún wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ní pàtàkì tó o bá ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà.