Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

‘Kò Sí Ọ̀rọ̀ Kan Tí Ó Kùnà’

Gbogbo ìrìn-àjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù ti wá sópin. Ilẹ̀ Ìlérí tí wọ́n ti ń wọ̀nà fún látọjọ́ yìí ni wọ́n ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí. Lábẹ́ ìdarí Jóṣúà, ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, kí wọ́n lè rí ìmúṣẹ gbogbo àwọn ìlérí Rẹ̀? Wo bí ìtàn yìí á ṣe jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣẹ lọ́jọ́ wa yìí!